Ohun jíjẹ pàtàki ti à ńfi Iṣu Ewùrà ṣe: Ìfọ́kọrẹ́ tàbi Ìkọ́kọrẹ́ àti Ọ̀jọ̀jọ̀.

Ẹ ṣe àyẹ̀wò bi a ti ńṣe Ìfọ́kọrẹ́/Ìkọ́kọrẹ́ lójú iwé yi.

Gbé epo kaná
Kó èlò bi ẹ̀jà tútù tàbi gbigbẹ, edé, pọ̀nmọ́ sinú ikòkò epo-pupa yi
Fi iyọ̀ àti iyọ̀ igbàlódé àti omi si inú ikòkò yi lati se omi ọbẹ ìkọ́kọrẹ́
Fọ Iṣu Ewùrà kan
Bẹ Ewùrà yi
Rin iṣu yi (pẹ̀lú pãnu ti a dálu lati fi rin gãri, ilá tàbi ewùrà)
Fi iyọ̀ bi ṣibi kékeré kan po ewùrà ri-rin yi
Ti ó bá ki, fi omi diẹ si lati põ
Lẹhin pi pò, dá ewùrà pi pò yi sinú omi ọbẹ̀ ti a ti sè fún bi iṣẹ́jú mẹdogun
Rẹ iná rẹ silẹ̀, se fún bi ogún iṣẹ́jú
Ro pọ
Lẹhin eyi bu fún jijẹ.

 

ENGLISH TRANSLATION

Water Yam pottage

Heat Palm Oil
Add dry or fresh fish, prawns or crayfish, cooked cow skin into a pot,
Add salt or other seasoning, palm oil and water into
the pot as the water yam pottage stock,
Wash the water yam,
Peel the water yam,
Grate the water yam (use the type of aluminium grater
used for cassava, okra or water yam)
Add a teaspoon of salt to mix the grated water yam
If it is too thick, add a little water to soften it
After mixing, begin to cut it either with spoon or hand to the
Boiling stock which has been cooked for about fifteen minutes,
Stir together,
Then serve.

Share Button

Originally posted 2014-03-28 20:26:48. Republished by Blog Post Promoter

2 thoughts on “Ohun jíjẹ pàtàki ti à ńfi Iṣu Ewùrà ṣe: Ìfọ́kọrẹ́ tàbi Ìkọ́kọrẹ́ àti Ọ̀jọ̀jọ̀.

    1. Bim A Post author

      Ẹ ṣé púpọ̀, bẹni Ijebu lo ni Ìfọ́kọrẹ́/Ìkọ́kọrẹ́ gbogbo Yoruba lo ni Ọ̀jọ̀jọ̀.

      From:
      The Yoruba Blog Team.

      Reply

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Time limit is exhausted. Please reload the CAPTCHA.