“Ọ̀rẹ́ dani kò tó pọ́n, abínibí/ẹbi a má dani” – “It is not worth dwelling on a friend’s disappointment or deceit, as such do occur from siblings/family members”.

Kò si ibi ti ẹ̀tàn  tàbi ká dani kò ti lè wá.  Ẹni ti ó bá ni iwà burúkú bi: ojúkòkòrò, ìlara àti ìmọ-tara-ẹni nikan, lè dani tàbi tan-nijẹ. Ọmọ lè tan bàbá tàbi ìyá, ìyá tàbi bàbá lè tan ọmọ, ọkọ lè da aya, ọmọ-ìyá tàbi ẹbi ẹni lè tan ni jẹ, tàbi dani, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìgbà, èniyàn ki reti irú iwà yi lati ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́.  Nitori ifi ọkàn tàn si ọ̀rẹ́, ìbànújẹ́ tàbi ẹ̀dùn ọkàn gidi ni fún èniyàn ti ọ̀rẹ́ bá da tàbi tàn jẹ.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ pé, “Ọ̀rẹ́ dani kò tó pọ́n, abínibí/ẹbi a má dani”.  Òwe yi fihàn pé kò si ẹni ti kò lè dani tàbi tan ni jẹ, nitori “Àgbẹ́kẹ̀lé enia, asán ló jẹ́”.  A lè fi òwe yi ṣe ìtùnú fún ẹni ti irònú bá nitori ọ̀rẹ́ da a, tàbi ti ó sọ ohun ribiribi nù nitori ẹ̀tàn ọ̀rẹ́.

ENGLISH TRANSLATION

Disappointment or deception can come from anyone or anywhere.  Anyone with bad character such as: Greed, envy and selfishness, can disappoint or deceive others.  Disappointment or deceit could come from children to parents, mother or father to children, husband to wife or vice versa, or from siblings or family members, but most times, people never expected such from friends.  As a result of placing great confidence in a friend, it often causes sorrow or depression for people that are disappointed or deceived.

According to the Yoruba adage that said “It is not worth dwelling on a friend’s disappointment or deceit, as such do occur from siblings/family members”. This proverb showed that anyone could disappoint or deceive because “Trust/confidence in people is vanity”.   The adage can be used to console or comfort those that are depressed as a result of friend’s disappointment or those who have incurred losses as a result of a friend’s deceit.

Share Button

Originally posted 2014-10-28 19:45:27. Republished by Blog Post Promoter

Ohun gbogbo ki i tó olè: Òṣèlú Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú – Nothing ever satisfies the thief: African Leaders/Politicians

Òṣèlú Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú African Union leaders

Òṣèlú Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú African Union leaders

Kò si oye ọdún ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú lè lò ni ipò ti wọn lè gbà lẹ́rọ̀ lati kúrò.  Bi àyè bá gbà wọn, wọn fẹ kú si ori oyè.  Bi a bá ṣe akiyesi ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú Òkè-Òkun, bi àwọn ará ilú bá ti dibò pé wọn kò fẹ́ wọn nipa yin yan ẹlòmíràn, wọn yio gbà lẹ́rọ̀, lati gbé Ìjọba fún ẹni tuntun ti ará ilú yan, ṣùgbọ́n kò ri bẹ ẹ ni Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú.

Ohun ti ó jẹ́ ki àwọn Òṣèlú Ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú fẹ́ kú si ipò pọ.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Olóri Òṣèlú Nigeria, ki ba jẹ ti Ìjọba Ológun tàbi Alágbádá, kò si ẹni tó mọ bàbá wọn ni ilú, ṣùgbọ́n wọn kò kọ́ ọgbọ́n pé ọ̀pọ̀ ọmọ ti wọn mọ bàbá wọn ni àwùjọ kò dé ipó nla ti àwọn dé.  Ó ṣe é ṣe ki ó jẹ́ wipé ìbẹ̀rù iṣẹ́ ti ó ṣẹ́ wọn ni kékeré ló jẹ́ ki wọn ni ojúkòkòrò lati fi ipò wọn ji owó ilú pamọ́ fún ara wọn, ọmọ àti aya wọn nitori ìbẹ̀rù iṣẹ́.  Kò si oye owó ti wọn ji pamọ́ ti ó lè tẹ́ wọn lọ́rùn, eyi ló fa ìbẹ̀rù à ti kúrò ni ipò agbára.  Ìbẹ̀rù ki ẹni ti ó bá má a gba ipò lọ́wọ́ wọn, ma ṣe ṣe iwadi wọn na a pẹ̀lú, nitori wọn ò mọ̀ bóyá yio bá wọn ṣe ẹjọ́ lati gba owó ilú ti wọn ji kó padà.

Kàkà ki ilú gbérí, ṣe ni ọlá ilú nrẹ̀hìn.  Bi Òsèlú bá ji owó, wọn a ko ọ̀pọ̀ owó bẹ́ ẹ̀ lọ si Òkè-Òkun tàbi ki wọn ri irú owó bẹ́ ẹ̀ mọ́lẹ̀ lóri ki kọ ilé ọ̀kẹ́ aimoye ti ẹni kan kò gbé.  Ọ̀pọ̀ owó epo-rọ̀bì ló wọlé, ṣùgbọ́n àwọn Òṣèlú àti àwọn olè bi ti wọn njẹ ìgbádùn nigbati ará ilú njìyà.   Lára ìpalára ti ji ja ilú ni olè fa, ni owó Nigeria (Naira) ti ó di yẹpẹrẹ, àwọn ọdọ kò ri iṣẹ́ ṣe, àwọn ohun amáyé-dẹrùn ti bàjẹ́ tán, oúnjẹ wọn gógó àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.

Òwe Yorùbá ti ó ni “Ohun gbogbo ki i tó olè” fi àlébù ojúkòkòrò, ifẹ́ owó, àti à ṣi lò agbára han ni ilú, pàtàki ni Nigeria.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-02-20 09:15:08. Republished by Blog Post Promoter

“A ki mọ́ ọkọ ọmọ, ki a tún mọ àlè rẹ” – “One does not acknowledge one’s child husband and also acknowledge her illicit affair”

Igbéyàwó ibilẹ̀ - Traditional marriage

Igbéyàwó ibilẹ̀ – Traditional marriage

Ni ayé àtijọ́, wọn ma ńfi obinrin fún ọkọ ni, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, obinrin á mú̀ àfẹ́sọ́nà lati fi hàn òbi, nitori Yorùbá gba ọmọ obinrin ni àyè lati lọ si ilé-iwé, tàbi kọ́ iṣẹ́-ọwọ́, àti lati ṣe òwò.  Èyi jẹ ki obinrin kúrò lọ́dọ̀ obi wọn.  Bi obinrin bá ti dàgbà tó bi ọdún meji-din-logun, ti ó tó wọ ilé-ọkọ, àwọn òbi yio ma ran léti pé, ó ti tó mú ọkọ wálé.

Ẹni ti obinrin mọ̀ pé òhun kò lè fẹ́, bi àfojúdi ni lati fi irú ọkùnrin bẹ̃ han òbi.  Bi obinrin ti ó ti dàgbà tó lati wọ ilé ọkọ bá mú àfẹ́sọ́nà wá han òbi, wọn yio fi òwe Yorùbá ti ó ni “A ki mọ́ ọkọ ọmọ, ki a tún mọ àlè rẹ” ṣe iwadi pé, ṣe ó da lójú pé òhun yio fẹ ọkùnrin ti ó mú wá?  Òwe yi tún wúlò lati fi ṣe ikilọ nigbà igbéyàwó ibilẹ̀ fún obinrin pé kò lè mú ọkùnrin miràn wá lẹhin igbéyàwó.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-07-08 23:02:45. Republished by Blog Post Promoter

“Ọba Aládélúsi Ògúnladé-Aládétóyìnbó gun Ori Oyè ilu Àkúrẹ́” – “New Deji of Akure ascends the Throne”

Déjì Àkúrẹ́ Ọba Aládélúsi Ògúnladé-Aládétóyìnbó pari gbogbo ètùtù ibilẹ ti Ọba Àkúrẹ́ ma nṣe lati gori oyè ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹjọ, oṣù keje, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún, lati di Ọba Kejidinlãdọta ilú Àkúrẹ́ ni ipinlẹ̀ Ondó ti ila-oorun orilẹ̀ èdè Nigeria.

img_20150708_221218-resized-800

Ọba Àkúrẹ́ gun Òkiti Ọmọlóre – The New King of Akure completed the traditional rites

 

 

 

 

 

 

 

 

Kí kí Ọba ni èdè Àkúrẹ́ – Congratulatory message to the new King in Akure Dialect

Kábiyèsi, Ọba Aláyélúà, wo kú ori ire o
Ẹbọ á fín o Àbá
Adé á pẹ́ lóri, bàtà á pẹ́ lọ́sẹ̀ o
Ùgbà rẹ á tu ùlú Àkúrẹ́ lára (Àṣẹ)

ENGLISH TRANSLATION

The Monarch of Akure, Deji Aladelusi Ogunlade-Aladetoyinbo has completed the all the traditional rites required to ascend the throne and was crowned on Wednesday, July eight, Two Thousand and Fifteen to become the forty eight Monarch of the Ancient City of Akure, Ondo State in Western Nigeria.

The Yoruba Blog Team sent Congratulatory Message in Akure dialect.

 

Share Button

Originally posted 2015-07-14 20:44:41. Republished by Blog Post Promoter

Iwé-àkọ-ránṣẹ́ ni èdè Yorùbá – Letter writing in Yoruba Language

Ni àtijọ́, àwọn ọmọ ilé-iwé ló ńran àgbàlagbà ti kò lọ ilé-iwé lọ́wọ́ lati kọ iwé, pataki ni èdè abínibí.  Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn iwé-àkọ-ránṣẹ́ wọnyi ni ojú iwé yi:

Ìwé ti Ìyá kọ sí ọmọ

Èsì iwé ti ọmọ kọ si iyá

Iwé ti ọkọ kọ si iyàwó

Èsi iwé ti aya kọ si ọkọ

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-03-11 01:14:25. Republished by Blog Post Promoter

Àwòrán ati Orúkọ àwọn Ẹiyẹ ni èdè Yorùbá – Pictures and names of Birds in Youruba

 

 

 

Share Button

Originally posted 2014-10-17 13:00:55. Republished by Blog Post Promoter

A Dúpẹ́ fún Ẹyin Àyànfẹ́ tó Bẹ̀rẹ̀ sí Tẹ̀léwa ní Twitter: Thank You to Our New Twitter Followers

Twitter followers

Twitter followers

Ẹfi ojú sọ́na lọ́sọ̀sẹ̀ fún kíkọ nípa àwọn nkan wọnyi lédè Yorùbá àti ìtum̀ọ lédè Gẹ̀ẹ́sì: Ìmúlò Òwe, Kíkọ Èdè, Ìtàn àti Ìròyìn tí a lè fi kọ́gbọ́n, Ẹgbẹ́ àti Oúnjẹ Yorùbá ni ìlú London, New York, Chicago, Orlando àti bẹ̃bẹ lọ.  Ẹ bá wa sowọ́pọ̀ láti ri pé èdè wa kò kú nípa kíkọ àti kíkà èdè Yorùbá lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Ẹ ṣé púpọ̀, ilé àti èdè Yorùbà kò ní parun o lágbára Èdùmàrè (Àṣẹ).

ENGLISH TRANSLATION

Watch out weekly for postings on: application of Yoruba Proverbs, posts to help you learn Yoruba, folklore, news that we can learn lessons from, stories about the Yoruba community and food in London, New York, Chicago, Orlando etc.  Join us to ensure that the Yoruba language is not extinct by writing and reading Yoruba on the Internet.

Thanks so much, The Yoruba language will not be destroyed by the power of God and our collective efforts (Amen).

 

Share Button

Originally posted 2013-05-17 02:06:24. Republished by Blog Post Promoter

Obinrin kò ṣe e jánípò si ìdí Àdìrò nikan, Obinrin ló ni gbogbo Ilé – Women cannot be relegated to the kitchen, women are in charge of the entire home

Ìtàn fi yé wa wi pé Yorùbá ka ọ̀rọ̀ obinrin si ni àṣà Yorùbá  bi ó ti ẹ jẹ wi pé obinrin ki jẹ Ọba nitori ni àṣà ilú, ọkunrin ló njẹ olóri.  Obinrin kò pọ̀ ni ipò agbára.  Àwọn ipò obinrin ni ‘Ìyáálé’, eyi jẹ́ iyàwó àgbà tàbi iyàwó àkọ́fẹ́ ninú ẹbí, pàtàki ni ilé o ni iyàwó púpọ̀ ṣùgbọ́n ọkùnrin ni ‘olóri ẹbí’.  Ipò obinrin kò pin si idi àdìrò àti inú ilé yókù gẹ́gẹ́ bi Olóri Òṣèlú Nigeria, Muhammadu Buhari ti sọ.

Obinrin Yorùbá ti ni àyè lati ṣe iṣẹ́ ti pẹ́, bi ó ti ẹ̀ jẹ́ wi pé àwọn iṣẹ́ obinrin bi oúnjẹ ṣí ṣe, ẹní hí hun, aṣọ hí hun, aró ṣi ṣe, òwú gbi gbọ̀n, ọjà ti tà (ẹ̀kọ́ ọrọ̀ ajé díẹ̀), oúnjẹ sí sè àti itọ́jú ẹbi ni obinrin nṣe.  Àwọn ọkùnrin nṣe iṣẹ́ agbára bi iṣẹ́ ọdẹ, alágbẹ̀dẹ, àgbẹ̀ tàbi iṣẹ́ oko (iṣẹ́ fún ji jẹ àti mimu ẹbí).  Obinrin ni ògúná gbongbo ni oníṣòwò òkèèrè, eyi jẹ ki obinrin lè ni ọrọ̀ àti lati lè gba oyè ‘Ìyálóde’.  Fún àpẹrẹ, àwọn Ìyálóde ni ó njẹ Olóri ọjà ni gbogo ilẹ̀ Yorùbá àti alá-bójútó fún ọ̀rọ̀ obinrin.

Gẹ́gẹ́ bi àṣà ibilẹ̀ Yorùbá, àwọn ọkùnrin gbà ki iyàwó  wọn ṣe iṣẹ́ lati ran ẹbí lọ́wọ́, eyi lè jẹ́ nitori àwọn ọkùnrin ni iyàwó púpọ̀, nitori èyi, kò nira bi iyàwó kan tàbi méji bá lọ ṣòwò ni òkèèrè, àwọn iyàwó yókù yio bójú tó ilé.   Àṣà òkè-òkun fi fẹ́ iyàwó  kan àti ẹ̀sìn òkèère ti Yorùbá gbà ló sọ àdìrò di ipò fún obinrin àti “Alá-bọ́dó, Ìyàwóilé tàbi Oníṣẹ́-ilé” ti ó di iṣẹ́ obinrin.  Obinrin ayé òde òní kàwé, ṣùgbọ́n bi wọn kò ti ẹ kàwé, gbogbo ẹni ti ó bá ni làákàyè fún àṣà, kò gbọdọ̀ já obinrin si ipò kankan ni ilé nitori obinrin ló ni gbogbo ilé.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-10-25 21:42:34. Republished by Blog Post Promoter

Welcome to the Yoruba Blog…

The home of all things Yoruba… news, commentary, proverbs, food. Keeping the Yoruba culture alive.

Share Button

Originally posted 2013-01-24 21:03:41. Republished by Blog Post Promoter

Àjàpá sọ Ẹlẹ́dẹ̀ di ọ̀bùn – “Alágbára má mèrò; baba ọ̀le; Ọgbọ́n ju agbára” – The Tortoise turned the Pig to the filthy one – One who has strength but is thoughtless is the father figure of laziness –wisdom is mightier than strength

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Àlébù ki ṣe ẹ̀gàn tàbi agọ̀; ṣùgbọ́n, ẹ̀gàn àti agọ̀ ni fún ẹni ti ojú rẹ fọ́ si àlébù ara rẹ”.  Irú ẹni bẹ̃, kò lè ri àtúnṣe tàbi sọ àlèbú yi di ohun ini.  Ninú ìtàn bi Àjàpá ti sọ Ẹlẹ́dẹ̀ di ọ̀bùn ti a mọ̀ si titi di oni, Àjàpá jẹ́ ẹranko ti kò lè yára rin tàbi ni agbára iṣẹ́ àti ṣe lówó, ṣùgbọ́n ó ni ọgbọ́n lati bo àlébù rẹ.

Yorùbá ni “Alágbára má mèrò; baba ọ̀le; Ọgbọ́n ju agbára”.  Àjàpá́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹwẹ, nigbati Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ alágbá̀ra ti kò mèrò.  Kò si ohun ti Àjàpá lè ṣe lai ni idi tàbi ọgbọ́n àrékérekè, nitori eyi, ó sọ ara rẹ di ọ̀rẹ́ Ẹlẹ́dẹ̀ nitori gbogbo ẹranko yoku ti já ọgbọ́n rẹ.  Ẹlẹ́dẹ̀ kò fi ọgbọ́n wá idi irú ọ̀rẹ́ ti Àjàpá jẹ́.  Laipẹ, Àjàpá lọ yá owó lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dẹ̀ pẹ̀lu àdéhùn pe ohun yio san owó na padà ni ọjọ́ ti ohun dá.  Ẹlẹ́dẹ̀ rò pé ọ̀rẹ́ ju owó lọ, ó gbà lati yá Àjàpá lówó nitori àdéhùn rẹ.

Nigbati ọjọ ti Àjàpá dá pé, Ẹlẹ́dẹ̀ reti titi ki ó wá san owó ti ó yá, ṣù̀gbọn Àjàpá kò kúrò ni ilé rẹ nitori ó mọ̀ pé ohun kò ni owó́ lati san.  Àjàpá fi ohun pẹ̀lẹ́ ṣe àlàyé pé bi ohun ti fẹ́ ma kó owó lọ fún Ẹlẹ́dẹ̀ ni olè dá ohun lọ́nà, ti wọn gba gbogbo owó lọ.  Inú Ẹlẹ́dẹ̀ kò dùn nitori kò gba iṣẹ̀lẹ̀ yi gbọ́, ṣùgbọ́n ó gba nigbati Àjàpá tún dá ọjọ́ miran lati san owó na.  Bi Ẹlẹ́dẹ̀ ti kúrò ló bá aya rẹ “Yáníbo” dìmọ̀pọ̀ bi ohun kò ti ni san owó padà.  Ó ni bi ọjọ́ bá pé, bi Yáníbo bá ti gbọ́ ìró Ẹlẹ́dẹ̀, kó yi ohun padà, ki ó bẹrẹ si lọ ẹ̀gúsí ni àyà ohun lai dúró bi Ẹlẹ́dẹ̀ bá wọlé bèrè ohun.

Àjàpa ninu ẹrọ̀fọ̀ ti Ẹlẹ́dẹ̀ ju si - The Tortoise thrown by the Pig into the swamp.  Courtesy: @theyorubablog

Àjàpa ninu ẹrọ̀fọ̀ ti Ẹlẹ́dẹ̀ ju si – The Tortoise thrown by the Pig into the swamp. Courtesy: @theyorubablog

Ni ọjọ́ ti Àjàpá dá pé, Ẹlẹ́dẹ̀ dé lati gba owó rẹ, Yáníbo ṣe bi ọkọ rẹ ti wi.  Ẹlẹ́dẹ̀ fi ibinu gbé ọlọ àti ẹ̀gúsí sọnù si ẹrọ̀fọ̀ ti ó wá ni ìtòsí lai mọ̀ pé Àjàpá ni ọlọ yi.  Yáníbo fi igbe ta titi ọkọ rẹ fi wọlé.  Àjàpá yọ ara rẹ̀ kúrò ninú ẹrọ̀fọ̀, ó nu ara rẹ̀, ó ṣe bi ẹni pé ohun kò ri Ẹlẹ́dẹ̀ nigbati ó délé.  Ó bèrè ohun ti ó fa igbe ti Yáníbo ńké.  Yáníbo ṣe àlàyé.

Ẹlẹ́dẹ̀i fi imú tú ẹrọ̀fọ̀ - The Tortoise prout in the swamp.  Courtesy: @theyorubablog

Ẹlẹ́dẹ̀i fi imú tú ẹrọ̀fọ̀ – The Tortoise prout in the swamp. Courtesy: @theyorubablog

 

 

Yorùbá ni “Ọ̀bùn ri ikú ọkọ tìrọ̀ mọ́, ó ni ọjọ́ ti ọkọ ohun ti kú ohun ò wẹ̀”.  Àjàpá ri ohun ṣe àwá-wi, ó sọ fún Ẹlẹ́dẹ̀ pé ọlọ ti ó gbé sọnù ṣe pataki fún idilé àwọn, nitori na ó ni lati wá ọlọ yi jade ki ohun tó lè san owó ti ohun yá.  Ẹlẹ́dẹ̀ wọnú ẹrọ̀fọ̀ lati wá ọlọ idile Àjàpá.  Lati igbà yi ni Ẹlẹ́dẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ si fi imú tú ẹrọ̀fọ̀ titi di ọjọ́ oni.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-02-18 23:03:39. Republished by Blog Post Promoter