Tag Archives: yoruba

ÌGBÉYÀWÓ ÌBÍLẸ̀ – TRADITIONAL MARRIAGE

Traditional Wedding Picture

Gifts at a modern Yoruba Traditional wedding — courtesy of @theYorubablog

Ìgbéyàwó ìbíle ní Ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ àsìkò ti ẹbí ọkọ àti ì̀yàwó ma nparapọ.  Ìyàwó ṣíṣe ni ilẹ̀ Yorùbá kò pin sí ãrin ọkọ àti ìyàwó nikan, ohun ti ẹbí nparapọ ṣe pẹ̀lú ìdùnnú nípàtàkì lati gbà wọ́n níyànjú àti lati gba àdúrà fún wọn.

A lè ṣe gbogbo ètò ìgb́eyàwó ìbílẹ̀ ni ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ púpọ̀ fún àpẹrẹ: mọ̀mí-nmọ̀ẹ lọjọkan ati idana lọ́jọ́ keji tàbi ọjọ miran.  Ní ayé àtijọ́, nígbàtí Yorùbá ma nṣe ayẹyẹ níwọ̀ntúnwọ̀sín, ilé ẹbí tàbi ọgbà bàbá àti ìyá iyawo ni wọn ti nṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n láyé òde òní, àyè ọ̀tọ̀ bi ilé ìlú, pápá ìṣeré, ilé àlejò àti bẹ̃bẹ lọ ni wọ́n nlo.  Àṣà gbígba àyè ọ̀tọ tógbòde bẹ̀rẹ̀ nítorí àwọn adigun jalè àti àwọn ènìyàn burúkú míràn ti o ma ndarapọ pẹ̀lú àwọn àlejò tí a pè sí ibi ìyàwó lati ṣe iṣẹ́ ibi.  Owó púpọ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ma nfi gba à̀yè ibi ṣíṣe ìyàwó.

Bí òbí ba ti lọ́lá tó ni wọn ma náwó tó, nitori ìdùnnú ni fún òbí pé a tọ́mọ, wọ́n gbẹ̀kọ́, wọn fẹ di òmìnira lati bẹ̀rẹ̀ ẹbí tíwọn, ṣùgbọ́n àṣejù ati àṣehàn ti wa wọ́pọ̀ jù. Nítorí ìnáwó ìgbéyàwó, ilé ayẹyẹ pọ̀ju ilé ìkàwé lọ láyé òde òní. Kí ṣe bi a ti náwó tó níbi ìgbéyàwó lo nmu àṣeyorí ba ọkọ àti ìyàwo, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ntuka láìpẹ́ lẹ́hin ariwo rẹpẹtẹ yi.    Yorùbá ni “A ki fọlá jẹ iyọ̀”, nínú ìṣẹ layika ni ilẹ̀ Aláwọdúdú, ó yẹ ki a ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó níwọ̀ntúnwọ̀nsìn.  Ẹ fojú sọ́nà fún ètò ìgbéyàwó ibilè.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-04-12 21:00:05. Republished by Blog Post Promoter

ORÚKỌ ỌJỌ́: Days of the Week in Yoruba

Below are the Yoruba days of the week. Of course it is worth noting that very few native Yoruba speakers use these words in conversation.

 

SUNDAY                               ÀÌKÚ

MONDAY                             AJÉ

TUESDAY                             ÌṢẸ́GUN

WEDNESDAY                      ỌJỌ́RÚ

THURSDAY                          ỌJỌ́BỌ̀

FRIDAY                                 ẸTÌ

SATURDAY                          ÀBÁMẸ́TA

Share Button

Originally posted 2013-03-19 22:33:05. Republished by Blog Post Promoter

“BÍ A TI NṢE NI ILÉ WA…”: MICHELLE OBAMA’S DRESSING AT OSCAR 2013

Michelle Obama Academy Award Edgy Dress

Image is from MSNBC (http://tv.msnbc.com/2013/02/25/a-cover-up-by-the-iranian-press-michelle-obama-has-no-right-to-bare-arms/) They covered the story on the Iranian Press Agency that found Michelle Obama’s dress a little too over the edge.

“Bí a ti nṣe ní ilé wa, ewọ ibòmíì”: “Our ways at  home, a taboo for others” — one man’s meat is another man’s poison.

Òwe yi fihàn wípé bí ọpọlọpọ ti sọ wípé imura Obìnrin Akọkọ ni ìlú America Michelle Obama (ni OSCAR 2013) ti dara tó, ewọ ni ki obinrin Iran mura bẹ.  Awọn obinrin Iran nilati bo gbogbo ara pẹlu “Hijab” nitori wọn o gbọdọ rí irun, apá tàbí ẹsẹ obìnrin ni gbangba.

ENGLISH TRANSLATION

This Yoruba proverb: “Our ways at  home, a taboo for others”, shows that even though many people thought the First Lady Michelle Obama’s dressing for the Oscar was stunning, it might be a taboo for an Iranian woman to dress like that. Iranian women must cover all their bodies with “Hijab” because women’s hair, arms or legs must not be exposed in the public.

Share Button

Originally posted 2013-02-26 18:17:08. Republished by Blog Post Promoter

Ounjẹ Yorùbá: Yoruba Food

Ẹ GBA OUNJẸ YORÙBÁ LÀ: SAVE YORÙBÁ: SAVE YORUBA FOOD

Ọpọlọpọ oriṣiriṣi ounjẹ Yorùbá nparẹ lọ, nípàtàkì larin awọn to ngbe ìlú nla.  Òwe Yorùbá ni “Ki àgbàdo to de ilẹ aye, adíyẹ njẹ, adíyẹ nmu”.  Itumo eyi nipe ki a to bẹrẹ si ra ounjẹ latokere, a nri ounjẹ ilẹ wa jẹ. Awọn to ngbe ilu nla bi ti Eko ko ri aye lati se ọpọlọpọ ounjẹ ilẹ wa, èyí ko jẹki àlejò mọ wipe Yorùbá ni oriṣiriṣi ọbẹ, ounjẹ ati ìpanu. Ni ọpọ ọdun sẹhin, irẹsi ki ṣe ounjẹ ojojumọ ṣugbọn fun awọn ọmọ igbalode, Irẹsi “Burẹdi” ati “Indomie” ti di ounjẹ.  Ọpọlọpọ ko ti ẹ fẹ jẹ ounjẹ ibilẹ bi awọn ounjẹ òkèlè: Iyán, Ẹba, Láfún ati bệbệ lọ.  Ti a ba ṣakiyesi, ọpọ ọmọ to dagba si Eko, ko mọ wipe Yorùbá ni ju ọbẹ ata ati ẹfọ/ila lọ.  Ọbẹ ata lo yá lati fi jẹ irẹsi, nitori ọpọ ninu awọn ọmọ wọnyi le jẹ irẹsi lojojumọ, larọ, lọsan ati lalẹ.  Ni ìlú Èkó, sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ko jẹ ki obi tètè délé lẹhin iṣẹ ojọ wọn, ẹlo miran ti ji kuro nílé lati bi agogo mẹrinabọ lai pada sílé titi di agogo mẹwa alẹ nigbati awọn ọmọ tisùn.  Nitori èyí ọpọ òbí ko ri aye lati se ounjẹ Yorùbá.   Àìsí ina manamana dédé tun da kun ifẹ si ounjẹ pápàpá.

Ìyàlẹnu ni wipe ọpọ awọn ti ówà l’Okeokun ngbe ounjẹ Yorùbá larugẹ ju awọn ti ówà ni ilé lọ pàtàkì ni ilu nla. Oṣeṣe pe bi iná manamana ba ṣe dédé ounje Yoruba yio gbayi si, nitori awọn òbì ma le se oriṣiriṣi ounjẹ pamọ.   Ẹjọwọ ẹ maṣe jẹ ki a fi ounjẹ òkèrè dipo ounjẹ ilẹ wa, okùnfà gbèsè ni.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-02-19 21:47:33. Republished by Blog Post Promoter

“Ã Ò PÉ KÁMÁ JỌ BABA ẸNI…”: It is not enough to have a striking resemblance to one’s Father

Yorùbá ní “Ã ò pé kámá jọ Baba ẹni timútimú, ìwà lọmọ àlè”.   Òwe yi bá ọpọlọpọ Yorùbá tí o nyi orúkọ ìdílé wọn padà nítorí ẹ̀sìn lai yi ìwà padà̀ lati bá orúkọ titun áti ẹ̀sìn mu.  Yorùbá ni “ilé lanwo ki a tó sọmọ lórúkọ” nítorí èyí, ọpọlọpọ orúkọ ìdílé ma nbere pẹ̀lú orúkọ òrìṣà ìdílé bi: Ògún, Ṣàngó, Ọya, Èṣù, Ọ̀sun, Ifá, Oṣó àti bẹ̃bẹ lọ.  Fún àpẹrẹ: Ògúnlànà, Fálànà, Ṣólànà ti yi padà sí Olúlànà.  Ìgbà míràn ti wọn bá lò lára orúkọ àwọn òrìṣa yi wọn a ṣe àyípadà si, fún àpẹrẹ: “Eṣubiyi” di “Èṣúpòfo”.

Esupofo, image is courtesy of Microsoft office images

“Esupofo”? Njẹ Èṣù pòfo bí, nígbàtí ẹni ti o yi orúkọ padà sí “Èṣúpòfo” njale. . .

Njẹ Èṣù pòfo bí, nígbàtí ẹni ti o yi orúkọ padà sí “Èṣúpòfo” njale, ṣiṣẹ́ gbọ́mọgbọ́mọ, purọ́, kówó ìlú jẹ, àti bẹ̃bẹ lọ? Ótì o, Èṣù o pòfo, ìwà lọmọ àlè.  Ọmọ àlè ti pọ si nítorí ìwà Èṣu ti pọ si ni ilẹ̀ Yorùbá. Kò sí nkan tí óburú ninú orúkọ yíyí padà, èyí ti o burú ni kí a yí orúkọ padà lai yi ìwà padà.  Ẹ fi ìwà rere dípò ìporúkodà.

ENGLISH TRANSLATION

The Yoruba people have a saying that “It is not enough to have a striking resemblance to one’s father, character distinguishes a bastard”.  This proverb refers to Yoruba people that replace their family names without matching change of character to go with the name or religion.  Another Yoruba saying goes that: “home is observed before naming a child” as a result of this, and so family names are derived with a prefix of the name of the gods and goddesses worshiped in the family such as Ò̀̀̀̀̀̀gun – god of iron/war, Ṣango – god of thunder, Oya – Sango’s wife, Eṣu – Satan, Osun – river goddess, Ifa – Divination, Oso – Wizard etc.  For example names like: Ogunlana, Falana, Solana have mostly been changed to “Olulana”.  Sometimes, when part of these gods/goddess names are used it is often changed, for example: “Esubiyi – delivered by Satan” is turned “Esupofo – satan has lost”. Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-01-23 10:15:54. Republished by Blog Post Promoter

Ọ̀tún wẹ Òsì, Òsì wẹ Ọ̀tún, Lọwọ́ fi Nmọ: Right Washing The Left & The Left Washing The Right Makes For Clean Hands

Washing hands

There is a Yoruba saying that, the right hand washes the left, and the left washes the right for clean hands. Image is courtesy of Microsoft Free Images.

Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, ọwọ́ ni a fi njẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Yorùbá, nítorí kò si ṣíbí tó dára tó ọwọ́ lati fi jẹ oúnjẹ òkèlè bi iyán, èyí jẹ kó ṣe pàtàkì lati fọ ọwọ́ mejeji lẹ́hìn oúnjẹ.  Fífọ ọwọ́ kan kòlè mọ́ bi ka fọ ọwọ́ mejeji.

Ọ̀rọ̀, “ọ̀tún wẹ òsì, òsì wẹ ọ̀tún, lọwọ́ fi nmọ” wúlò lati gba àwọn ènìà níyànjú wípé àgbájọwọ́ lãrin ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ará ìlú lérè.

Yorùbá ni “Àgbájọ ọwọ́ la fi nsọya, ajẹjẹ ọwọ́ kan ko gbe ẹrú dórí”, ọmọ Yorùbá nílélóko, ẹ jẹ́kí a parapọ̀ tún ílú ṣe.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-04-10 02:30:45. Republished by Blog Post Promoter

IMULO ÒWE YORUBA: APPLYING YORUBA PROVERBS

“A NGBA ÒRÒMỌDÌYẸ LỌWỌ IKÚ O NI WỌN O JẸ KI OHUN LỌ ATAN LỌJẸ” 

A le lo òwe yi lati kilọ fun ẹni to fẹ lọ si Òkèokun (Ìlu Òyìnbó)  lọna kọna lai ni ase tabi iwe ìrìnà.  Bi ẹbi, ọrẹ tabi ojulumọ to mọ ewu to wa ninu igbesẹ bẹ ba ngba irú ẹni bẹ niyanju, a ma binu wipe wọn o fẹ ki ohun ṣoriire.   Bi ounjẹ ti pọ to l’atan fun oromọdiyẹ bẹni ewu pọ to.  Bi ọna ati ṣoriire ti pọ to ni Òkèokun bẹni ewu ati ibanujẹ pọ to fun ẹniti koni aṣẹ/iwe ìrìnà.  Ọpọlọpọ nku sọna, ọpọ si nde ọhun lai ri iṣẹ, lai ri ibi gbe tabi lai ribi pamọ si fun Òfin. Lati pada si ile a di isoro nitori ọpọ ninu wọn ti ta ile ati gbogbo ohun ìní lati lọ oke okun. Bi iru ẹni bẹ ṣe npe si l’Òkèokun bẹni ìtìjú ati pada sile se npọ si.

Òwe yi kọwa wipe ka ma kọ eti ikun si ikilọ, ka gbe ọrọ iyanju yẹwo ki a ba le se nkan lọna totọ.

ENGLISH TRANSLATION

“WE ARE TRYING TO SAVE THE CHICK FROM DEATH, ITS COMPLAINING OF NOT BEING ALLOWED TO GO TO THE DUMPSITE” — “A NGBA ÒRÒMỌDÌYẸ LỌWỌ IKÚ O NI WỌN O JẸ KI OHUN LỌ ATAN LỌJẸ”

Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-02-19 22:08:02. Republished by Blog Post Promoter

Bi ará ilé ẹni ba njẹ kòkòrò búburú ti a ò sọ fun, hẹ̀rẹ̀-huru rẹ kò ní jẹ ki a sùn – If you fail to warn your neighbor of danger, his cries at night might prevent you from sleeping

Ó ti lé ni ọgbọ̀n ọdún ti ìyà iná monomono ti ńfi ìyà jẹ ará ilú orílẹ̀ èdè Nigeria.  Nitori dáku-́dájí iná  mọ̀nàmọ́na ti Ìjọba àpapọ̀ pèsè, ẹ̀rọ iná mọ̀nàmọ́na kékèké ti a lè fi wé kòkòrò búburú gbòde.

Generators

Power generators: ẹ̀rọ iná mọ̀nàmọ́na. The image is from http://lowhangingfruits.blogspot.com

Òwe Yorùbá ti ó ni “Bi ará ilé ẹni ba njẹ kòkòrò búburú ti a ò sọ fun, hẹ̀rẹ̀huru rẹ kò ni jẹ ki a sùn” bá iṣẹlẹ ọ̀rọ̀ àti pèsè ina monamona yi mu.  Pẹlu gbogbo owó ti ó ti wọlẹ̀ lóri àti pèsè ina mona-mona, ará ilé ẹni ti o ńjẹ kòkòrò búburú ti jẹ́run.  Ai sọ̀rọ̀ ará ìlú lati igbà ti aiṣe dẽde iná ti bẹrẹ lo fa hẹ̀rẹ̀huru ariwo ti ọ̀pọ̀ ẹ̀rọ-iná kékèké ma ńfà.  Ariwo yi pọ to bẹ gẹ, ti àtisùn di ogun.  Àti ọ̀sán àti òru ni ariwo ẹ̀rọ-iná kékèké yi ma ńdá sílẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tó burú jù ni herehuru ti òru.

Ki ṣe omi, epo-rọ̀bi, èédú nikan ni a fi lè ṣe ètò ina mona-mona.  A lè fi õrun,  atẹ́gùn àti pàntí ti ó pọ̀ ni orílẹ̀ èdè wa ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ pèsè iná mona-. Ìlú ti kò ni õrun tó ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú ńfi õrun pèsè iná mona-mona.

Ohun ìtìjú ni pé fún bi ọgbọ̀n ọdún ó lé díẹ̀, àwọn Òṣèlú àti ará ìlu, kò ri ará ilé ti ó ńjẹ kòkòrò búburú báwí.

English translation: Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-10-22 03:51:57. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ bá wa gbé ọ̀rọ̀ yi yẹ̀wò. Àwọn Ilé Ìdájọ́ Àgbà ni ìlú Amerika ṣe ìdájọ wípé “ìgbéyàwó ko di dandan kó jẹ́ laarin ọkùnrin àti obinrin” : US Supreme Court Decides Marriage Does not Have to be Man & Woman

Two men rejoicing

A gay couple rejoicing over the repeal of the Defense of Marriage Act — June 26, 2013. Image is from AP/BBC

Ẹ bá wa gbé ọ̀rọ̀ yi yẹ̀wò. Àwọn Ilé Ìdájọ́ Àgbà ni ìlú Amerika ṣe ìdájọ wípé “ìgbéyàwó ko di dandan kó jẹ́ laarin ọkùnrin àti obinrin”. Bi wọn ti s’alaiye oro na si, wọn ni kò dára ki àwọn Aṣòfin ti a mọ si “Congress”, sọ wípé “ìgbéyàwó lati jẹ́ laarin ọkùnrin àti obìnrin ni kan ṣoṣo”. Àkíyèsí ti wọn ṣe ni wípé, ìdí ti àwọn Aṣòfin ṣe sọ bẹ̃, ni pé wọn o fẹ́ràn àwọn ti o nṣe igbeyawo ọkùnrin si ọkùnrin tabi obìnrin si obìnrin.

Ẹ jẹ́ ki a yẹ ọ̀rọ̀ yi wo bó yá a fẹ́ràn ẹ, tàbi a o fẹ́ràn ẹ, ṣe àṣà àdáyébá Yorùbá kankan wa, bi òwe tàbí nkan bẹ̃, ti ó sọ ìdí ti a ṣe n fun àwọn ti ó bá ṣe ìgbéyàwó ni ọpọlọpọ ẹ̀tọ́ ti a n fun wọn?

Ẹ jọ̀wọ́, ẹyin ará Yoruba blog, ẹ bá wa da si. Ẹ sọ ìdí ti aṣe n fun àwọn ti ó bá ṣe ìgbéyàwó ni oriṣiriṣi ẹ̀tọ́, ẹ̀bùn lọ́jọ́, ìgbéyàwó àti àyẹ́sí fún àwọn tó bá wà ni ilé ọkọ.

Ìdájọ́ yi ṣe pàtàkì, bi o ti ẹ jẹ wípé Amerika lo yi òfin padà pe ìgbéyàwó ki ṣe laarin ọkùnrin àti obìnrin mọ́ lọ́jọ́ òní, ni ọjọ́ kan, Yorùbá, orílẹ̀ èdè Nigeria àti gbogbo ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú yio ṣe ipinu ọ̀rọ̀ yi.

 

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-06-28 15:27:02. Republished by Blog Post Promoter

Ìbà Àkọ́dá – Reverence to the First Being

Obinrin ti ó́ nṣe Ì̀bà Aṣẹ̀dá - A woman paying reverence to the Creator. Courtesy: @theyorubablog

Obinrin ti ó́ nṣe Ì̀bà Aṣẹ̀dá – A woman paying reverence to the Creator. Courtesy: @theyorubablog

Ìbà Àkọ́dá, ìbà Aṣẹ̀dá
Ìbà ni n ó f’òní jú, mo r’íbà, k’íbà ṣẹ
Nínú ríríjẹ, nínú àìríjẹ
Mo wá gbégbá ọpẹ́, mo r’íbà k’íbà ṣẹ
Alápáńlá tó so’lé ayé ró
Ṣe àtúntò ayé mi
Ní gbogbo ọ̀nà tí mo ti k’etí ikún sí Ọ
Baba d’áríjì, mo bẹ̀bẹ̀
Odò Orisun Rẹ ni mí, máṣe jẹ́ n gbẹ

Ìbà! ìbà!!

Ọmọ ìkà ń d’àgbà, ọmọ ìkà ń gbèrú
Ọmọ ẹni ire a má a tọrọ jẹ
Ọmọ onínúure a má a pọ́njú
Bó ti wù Ọ ́lo ń ṣ’ọlá Rẹ
Ìṣe Rẹ, Ìwọ ló yé o; Ògo Rẹ, é dibàjẹ́
Àpáta ayérayé, mo sá di Ọ ́o
Yọ́yọ́ l’ẹnu ayé
Aráyé ń sọ Ọ ́sí láburú, aráyé ń sọ Ọ ́sí rere
Ọlọ́jọ́ ń ka’jọ́
Bó pẹ́, bó yá, ohun ayé á b’áyé lọ

Ìbà! ìbà!!

Ẹni iná ọ̀rẹ́ bá jó rí, bó bá ní’hun nínú kò ní lè rò
ọ̀rẹ́ gidi ń bẹ bíi ká f’ẹ́ni dé’nú
ọ̀rẹ́ ló ṣe’ni l’ọ́ṣẹ́ tó ku s’ára bí iṣu
Ìrètí nínú ènìyàn, irọ́ funfun gbáláhú!
ọ̀rẹ́ kan tí mo ní
Elédùmarè, Alágbára, ìbà Rẹ o Baba, Atóbijù!

Ìbà! ìbà!!

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-02 19:50:39. Republished by Blog Post Promoter