Ọmọ bibi ni ewu púpọ̀, nitori eyi ni Yorùbá fi ma nki “ìyá ọmọ kú ewu”. Ni ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ tàbi ìkómọ, Bàbá, Ìyá, ẹbi àti ọ̀rẹ́ òbí ọmọ tuntun á fi ìdùnnú hàn nipa ṣíṣe ọpẹ́ pataki fún Ọlọrun
Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ wọnyi ti òbí lò lati fi ẹmi imõre hàn.
ENGLISH TRANSLATION
Child birth is fraught with danger, as a result, Yoruba people often greet the mother of a new born, “well done for escaping the danger”. On the day of the naming ceremony or child dedication, both the father, mother, family and friends of the new baby’s parent would show their gratitude by giving thanks to God.
See below some of the names that parents give to show their gratitude: Continue reading →
Originally posted 2014-06-27 12:10:46. Republished by Blog Post Promoter
Orúkọ ẹni ni ìfihàn ẹni, orúkọ Yorùbá fi àṣà, iṣẹ́ àti Òriṣà idile hàn tàbi àtẹsẹ̀bi ọmọ. Yorùbá gbàgbọ́ ninú Ọlọrun/Eledumare ki ẹ̀sin igbàgbọ́ àti imọ̀le tó dé. Ifá jẹ́ ẹ̀sin Yorùbá, nitori Ifá ni wọn fi ńṣe iwadi lọ́dọ̀ Ọlọrun ki Yorùbá tó dá wọ́ lé ohunkohun. Yorùbá gbàgbọ́ ninú àwọn iránṣẹ́ Ọlọrun ti a mọ̀ si “Òriṣà”. Àwọn Òriṣà Yorùbá pọ̀ ṣùgbọ́n pàtàki lára àwọn Òriṣà ni: Ògún, Ṣàngó, Ọya, Yemọja, Oṣó, Ọ̀ṣun, Olokun, Ṣọ̀pọ̀ná, Èṣù àti bẹ̃bẹ̃ lọ. Àwọn orúkọ ti ó fi ẹ̀sin àwọn Òriṣà wọnyi hàn ti ńparẹ́ nitori àwọn ẹlẹsin igbàlódé ti fi “Oluwa/Ọlọrun” dipò orúkọ ti ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ifá, Ògún, Èṣù àti bẹ̃bẹ̃ lọ. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ wọnyi:
ENGLISH TRANSLATION
One’s name is one’s identity, Yoruba names reflect the culture, trade, gods being worshipped in the family as well as the situation in which a child was born. Yoruba had faith in the Almighty God of Heaven ever before the advent of Christianity and Islam. Ifa was then the religion of the Yoruba people, because “Ifa” was the medium of consulting God before embarking on any venture. Yoruba believed in the messengers of God known as mini gods called “Orisa”. There many mini gods but prominent among them are: Ogun – god or Iron; Sango – god of thunder and lightning; Oya – river Niger goddess, wife of Sango; Yemoja – goddess of all rivers; Oso – wizard deity, Osun – river goddess; Olokun – Ocean goddess; Sopona – deity associated with chicken pox; Esu – god of protector as well as trickster deity that generates confusion; etc. The names that were associated with all these Yoruba gods are disappearing because they are being replaced with “Olu, Oluwa, Olorun”, to reflect the modern beliefs. Check below names that associated with the traditional and modern faith:
IFÁ – Yoruba belief of Divination
Orúkọ idile Yorùbá
Orúkọ igbàlódé ti ó dipò orúkọ ibilẹ̀
English/Literal meaning – IFA –Yoruba Religion
Fábùnmi
Olúbùnmi
Ifa/God gave me
Fádádunsi
Dáhùnsi
Ifa responded to this
Fadaisi/Fadairo
Oludaisi
Ifa/God spared this one
Fadójú/Fadójútimi
Ifa did not disgrace me
Fádùlú
Ifa became town
Fáfúnwá
Olúfúnwá
Ifa/God gave me to search
Fágbàmigbé
Ifa did not forget me
Fágbàmilà/Fagbamiye
Ifa saved me
Fágbèmi
Olúgbèmi
Ifa/God supported me
Fagbemileke
Oluwagbemileke
Ifa/God made me prevail
Fágbénró
Olúgbénró
Ifa/God sustained me
Fágúnwà
Ifa straightened character
Fájánà/Fatona
Ifa led the way
Fájọbi
Ifa joined at delivery
Fájuyi
Ifa is greater than honour
Fakẹyẹ
Ifa gathered honour
Fálànà
Olúlànà
Ifa/God opened the way
Fálayé
Ifa is the way of the world
Fáléti
Ifa has hearing
Fálọlá
Ifa is wealth
Fálolú
Ọláolú
Ifa is god
Fámùkòmi/Fáfúnmi
Olúwafúnmi
Ifa/God gave to me
Fámúrewá
Ifa brought goodness
Farinre
Ọlarinre
Ifa/Wealth came in goodness
Fáṣeun
Olúwaṣeun
Thanks to Ifa
Faséùn/Fápohùndà
Ifa kept his words
Fáṣọlá
Olúṣọlá
Ifa/God created wealth
Fatimilẹhin
Oluwatimilẹhin
Ifa/God supported me
Fátúnàṣe
Ifa repaired morals
Faturoti
Ifa is worth waiting on
Fáyẹmi
Olúyẹmi
Ifa/God suits me
Fayoṣe
Ifa will perform it
Ọláifá
Ọláolú
Ifa’s wealth
Originally posted 2014-07-11 20:39:12. Republished by Blog Post Promoter
Orúkọ idile Yorùbá ti ó nparẹ́ nitori èsìn. Àwọn orúkọ ìdílé wọnyi kò di ẹlẹ́sìn lọ́wọ́ lati ṣe iṣẹ́ rere tàbi dé ọ̀run,
ENGLISH TRANSLATION
Yoruba family names that are disappearing. These traditional names should not be seen as obstacles by religious ones to doing good work or getting to heaven.
ÒGÚN – god of iron, war and justice
Orúkọ idile Yorùbá
Orúkọ igbàlódé ti ó dipò orúkọ ibilẹ̀
English/Literal meaning – IFA –Yoruba Religion
Adéògún
Ogun’s crown
Ògúnadé
Ogun in the crown
Ògúnbámbi
Olúbambi
Ògúnbiyi
Olubiyi/Biyi
Ogun/God gave birth to this
Ògúnbùnmi
Olúbùnmi/Bunmi
Ogun/God gave me
Ògúnbọ̀wálé
Adébọ̀wálé/Débọ̀
Ògúndàmọ́lá
Adédàmọ́lá/Dàmọ́lá
Ogun/Crown mixed with wealth
Ògúndiyimú/Ògúndimú
Ògúǹdé/Ògúnrindé
Ogun has arrived
Ògúndélé
Ọládélé/Délé
Ogun came home
Ògúndèyi
Ogun has become this
Ògúnfúnmi/Ògúnbùnfúnmi
Olúwáfúnmi/Fúnmi
Ogun gave me
Ògúngbadé
Olúgbadé/Gbadé
Ogun received the crown
Ògúngbèjà
Olúgbèjà
Ogun/God defends
Ògúnkọ̀yà
Olúkọ̀yà/Kọ̀yà
Ogun/God rejected suffering
Ogunlade
Olulade
Ògúnlàjà
Olulaja/Laja
Ogun/God separated a fight
Ògúnlànà
Olúlànà
Ogun/God paved the way
Ògúnlékè
Ọlálékè/Lékè
Ogun/God prevailed
Ògúnléndé
Ogun pursued me here
Ògúnlẹyẹ
Olulẹyẹ/Lẹyẹ
Ogun/God is honourable
Ògúnmọ́dẹdé
Olúmọ́dẹdé
Ogun/God made the hunter to arrive
Ògúnmọ́lá
Olumola
Ogun/God plus wealth
Ògúnmuyiwa
Olúmuyiwa/Muyiwa
Ogun/God brought this
Ògúnpọ́nlé/Ògúnpọ́nmilé
Olúpọ́nlé/Pọ́nlé
Ogun/God honoured me
Ògúnrẹ̀milẹ́kún
Oluwarẹmilẹkun/Rẹmi
Ogun/God consoled me
Ògúnrọ̀gbà
Adérọ̀gbà
Ogun/Crown has eased time
Ògúnsànyà
Olúsànyà/Sànyà
Ogun/God repay suffering
Ògúnṣẹ̀san
Olúṣẹsan/Ṣẹ̀san
Ogun/God compensate
Ògúnṣinà
Olúṣinà/Ṣina
Ogun/God opened the way
Ògúnṣọlá
Olúṣọlá/Ṣọlá
Ogun/God created wealth
Ògúnṣuyi
Ọláṣuyi/Ṣuyi
Ogun/God created honour
Ògúntóbi
Oluwatóbi
Ogun/God is great
Ògúntọ́ba
Olútọ̀ba
Ogun/God is equal to the King
Ògúntólú
Adétólú
Ogun/Crown is equal to the gods
Ògúntọ́lá
Olútọ́lá
Ogun/God is equal to wealth
Ògúntọ̀nà
Adétọ̀nà
Ogun/God leads the way
Ògúntoyinbo
Ogun is equal to the white man
Ogunye
Ogun survived
Ògúnyẹmi
Olúyẹmi/Yẹmi
Ogun suits me
Originally posted 2016-04-05 11:47:25. Republished by Blog Post Promoter
Yorùbá ka ọmọ si ọlá àti iyì ti yio tọ́jú ìyá àti bàbá lọ́jọ́ alẹ́. Eyi han ni orúkọ ti Yorùbá nsọ ọmọ bi: Ọmọlọlá, Ọmọniyi, Ọmọlẹ̀yẹ, Ọmọ́yẹmi, Ọlọ́mọ́là, Ọlọ́mọlólayé, Ọmọdunni, Ọmọwunmi, Ọmọgbemi, Ọmọ́dára àti bẹ̃bẹ̃ lọ. A o tun ṣe akiyesi ni àṣà Yorùbá pe bi obinrin ba wọ ilé ọkọ, wọn ki pe ni orúkọ ti ìyá ati bàbá sọ, wọn a fun ni orúkọ ni ilé ọkọ. Nigbati ó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé wọn a pe ni “Ìyàwó” ṣùgbọ́n bi ó bá ti bímọ a di “Ìyá orúkọ àkọ́bí”, bi ó bá bi ibeji tabi ibẹta a di “Ìyá Ibeji tàbi Ìyá Ibẹta”. Bàbá ọmọ a di “Bàbá orúkọ ọmọ àkọ̀bí, Bàbá Ibeji tàbi Bàbá Ìbẹta”. Nitori idi eyi, ìgbéyàwó ti kò bá si ọmọ ma nfa irònú púpọ̀.
Ni abúlé kan ni aye atijọ, ọkọ ati ìyàwó yi kò bímọ fún ọpọlọpọ ọdún lẹhin ìgbéyàwó. Nitori àti bímọ, wọn lọ si ilé Aláwo, wọn lọ si ilé oníṣègùn lati ṣe aajo, ṣùgbọ́n wọn o ri ọmọ bi. Aladugbo wọn gbà wọn niyanju ki wọn lọ si ọ̀dọ̀ Olóri-awo ni ìlú keji. Ọkọ àti ìyàwó tọ Olóri-awo yi lọ lati wa idi ohun ti wọn lè ṣe lati bímọ. Olóri-awo ṣe iwadi lọ́dọ̀ Ifa pẹ̀lú ọ̀pẹ̀lẹ̀ rẹ, o ṣe àlàyé pe ko si ọmọ mọ lọdọ Òrìṣà ṣùgbọ́n nigbati ẹ̀bẹ̀ pọ, o ni ọmọ kan lo ku lọdọ Òrìṣà-Omi, ṣùgbọ́n ti ohun bá gba ọmọ yi fún wọn kò ni bá wọn kalẹ́, nitori ti o ba lọ si odò ki ó tó bi ọmọ ni ilé ọkọ yio kú, Òrìṣà-Omi á gba ọmọ rẹ padà. Ọkọ àti Ìyàwó ni awọn a gbã bẹ.
Ààntére lọ fọ abọ́ lódò – Aantere went to the River to do dishes. Courtesy: @theyorubablog
Ìyàwó lóyún, ó bi obinrin, wọn sọ ni “Ààntéré” eyi ti ó tumọ si “Ọmọ Omi”. Gbogbo ẹbi àti ará bá wọn yọ̀ ni ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ. Ni ọjọ kan, Ààntéré bẹ awọn òbí rẹ pé ohun fẹ́ sáré lọ fọ abọ́, awọn òbí rẹ kọ. Nigbati ẹ̀bẹ̀ pọ wọn gbà nitori o ti dàgbà tó lati wọ ilé-ọkọ, wọn ti gbàgbé ewọ ti Olóri-awo sọ fún wọn pe, o ni lati wọ ile ọkọ ki o to bímọ. Ààntéré dé odò, Òrìṣà-omi, ri ọmọ rẹ, o fi iji nla fa Ààntéré wọ inú omi lai padà.
Ìyá àti Bàbá Ààntéré, reti ki ó padà lati odò ṣùgbọ́n kò dé, wọn ké dé ilé Ọba, Ọba pàṣẹ ki ọmọdé àti àgbà ìlú wa Ààntéré lọ. Nigba ti wọn dé idi odò, wọn bẹrẹ si gbọ orin ti Ààntéré nkọ, ṣùgbọ́n wọn ò ri.
UNILAG Senate Building – photo from http://www.unilag.edu.ng/
“A kì dàgbà jẹ Òjó”: “Natural birth names not appropriate at old age”
Òjó, Dàda, Àìná, Táíwò, Kẹhinde ati bebe lo je orúkọ amu tọrun wa. Pípa orúkọ Ilé-ìwé gíga ni Akoka, ilu Eko da lẹhin aadọta ọdún dàbí ìgbà ti a sọ arúgbó lorukọ àmú tọrun wa. Apẹrẹ: ẹni ti ki ṣe ibeji ko le pa orúkọ da si orúkọ àmú tọrun wa.
A dupẹ lọwọ Olórí Ìlú Goodluck Jonathan to gbọ igbe awọn ènìyàn lati da orúkọ Ilé-ìwé Gíga ti o wa ni Akoko ti Ilu Eko pada gẹgẹbi Olukọagba Jerry Gana, ti kọ si ìwé ìròyìn ni ọjọ Ẹti, oṣù keji ẹgbaa le mẹtala.
ENGLISH TRANSLATION
Òjó, Dàda, Àìná, Táíwò, Kẹhinde etc, all these names in Yoruba are given at birth as a result of natural circumstances observed at birth. Continue reading →
This website uses cookies to improve your experience. We'll assume you're ok with this, but you can opt-out if you wish. Cookie settingsACCEPT
Privacy & Cookies Policy
Privacy Overview
This website uses cookies to improve your experience while you navigate through the website. Out of these cookies, the cookies that are categorized as necessary are stored on your browser as they are essential for the working of basic functionalities of the website. We also use third-party cookies that help us analyze and understand how you use this website. These cookies will be stored in your browser only with your consent. You also have the option to opt-out of these cookies. But opting out of some of these cookies may have an effect on your browsing experience.
Necessary cookies are absolutely essential for the website to function properly. This category only includes cookies that ensures basic functionalities and security features of the website. These cookies do not store any personal information.
Any cookies that may not be particularly necessary for the website to function and is used specifically to collect user personal data via analytics, ads, other embedded contents are termed as non-necessary cookies. It is mandatory to procure user consent prior to running these cookies on your website.