Jimmy Savile abused at least 500 victims
Ọ̀pọ̀ ti ó ni ipò ni àwùjọ ni ó fi iwà ikà ba ipò wọn jẹ. Ìròyìn bi Olóògbé Jimmy Savile ti fi iwà burúkú ba iṣẹ́ ribiribi ti ó ṣe nipa pi pa owó fún ọrẹ-àánú ni ó ńlọ lọ́wọ́-lọ́wọ́. Iṣẹ́ ibi ti ó ṣe ni igbà ayé rẹ fihan pé “O ni ikù ló mọ̀ ikà”. Gẹ́gẹ́ bi iwadi ti o jáde lẹhin ikú Olóògbé yi, ó lo ipò rẹ ni àwùjọ lati bá ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta obinrin ni àṣepọ̀ ni ọ̀nà ti kò tọ́.
Òwe Yorùbá ti ó ni “Ẹni ti o ni ori rere, ti kò ni iwà, iwà rẹ ni yio ba ori rẹ̀ jẹ́” fihàn pé Jimmy Savile fi iwà àbùkù ba iṣẹ́ rere ti ó ṣe jẹ. Ìṣẹ̀lẹ̀ Jimmy Savile kò ṣe àjòjì ni ilẹ̀ Yorùbá. Ni ayé àtijọ́, àwọn Ọba tàbi Olóyè miran ma ńlo ipò wọn lati ṣe iṣẹ ibi – bi ki wọn gbé ẹsẹ̀ lé iyàwó ará ilú; fi ipá gba oko tàbi ilẹ̀ ará ilú lai si ẹni ti ó lè mú wọn ṣùgbọ́n láyé òde òni, Ọba tàbi Olóyè ti ó bá hu iwà burúkú wọnyi, yio tẹ́.
Ọba/Olóyè yio ti ṣe iwà ibi yi pẹ́, ki ilú tó dide lati rọ̃ loye, ṣùgbọ́n láyé òde òni ki pẹ́, ki ẹni ti ó bá fi ipò bojú iwà burúkú yi tó tẹ́. Ọba/Olóyè/Ọlọ́rọ̀ Yorùbá ti ó bá fi ipò tàbi ọlá hu iwà ikà ni ayé igbàlódé yi, kò ri ibi pamọ́ si, nitori àṣiri á tú ninú iwé-ìròyìn, ẹ̀rọ-asọ̀rọ̀-mágbèsi, ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán àti lori ayélujára.
Ki ṣe ará ilú nikan ló lè ṣe ìdájọ́ fún Ọba ti ó bá hu iwà ikà nipa ri-rọ̀ lóyè, gbogbo àgbáyé ni yio ṣe idájọ́ fun, irú Ọba/Olóyè/Ọlọ́rọ̀ bẹ̃ yio tun fi ojú ba ilé-ẹjọ́. Fún àpẹrẹ: Ọba Adébùkọ́lá Alli – Alọ́wá ti Ìlọ́wá ti obinrin Agùnbánirọ̀ fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ipá ni àṣepọ̀ àti Déji Àkúrẹ́ ti wọn rọ̀ lóyè nitori iwa àbùkù – Oluwadare Adeṣina.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading