Òwe Yorùbá ni “Ọbẹ̀ tó dùn, owó ló pá”, ṣùgbọ́n kò ri bẹ̃ fún ẹni ti kò mọ ọbẹ̀ se. Elomiran lè lo ọ̀kẹ́ àimọye owó lati fi se ọbẹ̀ kó má dùn nitori, bi iyọ̀ ò ja, ata á pọ̀jù tàbi ki omi pọ̀jù.
Ni tõtọ, owó ni enia ma fi lọ ra èlò ọbẹ̀ lọ́jà, ṣùgbọ́n fún ẹni ti ó mọ ọbẹ̀ se, ìwọ̀nba owó ti ó bá mú lọ si ọjà, ó lè fi ra èlò ọbẹ̀ gẹ́gẹ́ bi owó rẹ ti mọ, ki ó si se ọbẹ̀ na kó dùn. Ẹ wo àwòrán àti pipè èlò ọbẹ ni abala ojú iwé yi.
Àwòrán àti pípè orúkọ Èlò Ọbẹ̀ Yorùbá
View more presentations or Upload your own.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2015-12-08 16:30:36. Republished by Blog Post Promoter