Ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tó ṣẹ́lẹ̀ ni ọ̀sán gangan, Ọjọ Kẹta Oṣù Karun ọdún Ẹgbẹrunmejilemẹtala ni Woolwich, Olú Ìlúọba jẹ apẹrẹ fún òwe Yorùbá tó wípé “Ọmọ tóda ni ti Bàbá ṣùgbọ́n burúkú ni ti Ìyá”. Ẹ̀kọ́ ti a le ri lo ninu òwe yi nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ yi ni ka kìlọ̀ fún onínú fùfù kó ṣọ́ra, ìbínú burúkú ni ìdí ti àwọn ọ̀dọ́mọ̀kunrin meji fi pa Jagunjagun ni Woolwich.
Gẹ́gẹ́bí ẹniti o ti gbé Peckham fún ọdún melo kan sẹhin, a ṣe àkíyèsí pe àwọn ọ̀dọmọ̀kunrin tó ni ìdíwọ́ ma jáde pẹ̀lú ọ̀be lati ya ẹni tó nlọ ni ìgboro Gũsu, Olú Ìlúọba, lọbẹ laiṣẹ. Ibã jẹ nípa àwáwí lati digun jalè tàbí gba ẹ̀sìn sódì, kò si àwáwí tó tọ̀nà lati pa ẹnìkejì. Ohun tó dára lati ṣe ni ki a pa ẹnu pọ̀ lati sọ wípé “ohun ti kó da, ko da’’.
Michael Adebọlajọ ti di ọmọ ìyá̀ rẹ – Nigeria, kò yani lẹ́nu wípé Bàbá rẹ̀ London kọ silẹ̀. Ó pani lẹrin wípé ọmọkùnrin yi ti ka ara rẹ kun ẹbi Palestine, Iraq ati Afghansistan nigbàti a o le da ẹ̀bi fún Ìjọba Ìlúọba fún ikú obinrin ati ọmọ wẹ́wẹ́ to nṣẹlẹ ni Nigeria.
English Translation: Continue reading