Èkó jẹ́ Olú-Ilú Nigeria fún ọdún mẹ́tàdinlọ́gọrin, ṣùgbọ́n idikọ fún òwò àti ọrọ̀ ajé lati ẹgbẹgbẹ̀run ọdún sẹhin titi di ọjọ́ oni. “Ta ló lè mọ ori ọlọ́là lágbo?” Gbogbo àgbáyé ló nwá lati ṣe ọrọ̀ ajé ni ilú Èkó, òbí Gómìnà Jakande kò yàtọ̀ nitori wọ́n wá lati Òmù-Àrán, ti ó wà ni ìpínlẹ Kwara lati wá ṣe òwò ni Eko bi ti gbogbo èrò lai mọ wi pé ọmọ ọkùnrin ti Ọlọrun fi ta wọ́n lọ́rẹ ni ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù keje ọdún Ẹ̀ẹ́dẹ́gbàlémọ́kàndinlọ́gbọ̀n sẹ́hin ni agbègbè Ẹ̀pẹ́tẹ̀dó ni Ìsàlẹ̀-Èkó, yio di Gómìnà Alágbádá Àkọ́kọ́ ti Ìpínlẹ̀ Èkó ni ọjọ́ kan.
Ore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ni ki èniyàn dàgbà darúgbó di aadọrun ọdún láyé. Ki ṣe pi pẹ́ láyé lásán, ṣùgbọ́n ki a lo àsìkò, ẹ̀bùn àti ẹ̀kọ́ ti a bá ni lati sin ẹlòmíràn gẹ́gẹ́bi Alhaji Lateef Jakande ti fi ipò Òṣèlú tirẹ̀ sin Ìpínlẹ̀ Èkó. Kò si ẹni ti ó ńgbé ni Ìpínlẹ̀ Èkó ti kò jẹ ninú iṣẹ́ ribiribi, ti Alhaji Jakande ṣe si Ìpínlẹ̀ Èkó. Lára àwọn iṣẹ́ ná à ni:
Ìjọba Gómìnà Jakande ni igbà tirẹ̀ dá:
Ilé-iṣẹ́ asọ̀rọ̀mágbèsi àti ilé-iṣẹ́ amóhùn-máwòrán sile,
Ki kọ́ Ilé-ìwé ọ̀fẹ́ ti o sọ ilé-iwe li lọ lati iṣipo mẹta lójúmọ́ di ìgbà kan fún gbogbo ọmọ ilé-ìwé
Di dá Ilé-iwe giga Ipinle àkọ́kọ́ ni Orilẹ̀-èdè Nigeria sílẹ̀
Bi bẹ̀rẹ̀ Ọkọ̀ ojú-irin igbàlódé ti àwọn ijọba ológun dá dúro
Ki kọ́ Ile-iwòsàn àpapọ̀ si gbogbo agbègbè
Ki kọ́ ẹgbẹgbẹ̀rún ibùgbé àrọ́wọ́tó àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ
Gbogbo ẹgbẹ́ Olùkọ̀wé à̀ti Olùdarí gbígbé èdè àti àṣà Yorùbá lárugẹ lóri ayélujára bá ẹbi, ará àti gbogbo èrò Èkó dúpẹ́ lọ́wọ́ Èdùmàrè ti o dá ẹmi Alhaji Lateef Kayode Jakande si.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading