Tag Archives: United Kingdom

“Ire kì í dé ká má gbọ́ ohun gudu-gudu” Kate ati William ẹ kú orí-ire: Good fortune must be greeted with rejoicing – Congratulations Kate & William

Duke and Duchess of Cambridge outside the Lindo Wing of St Mary's Hospital with their new baby boy on 23 July 2013

The Royal Baby

http://t.news.uk.msn.com/uk/gun-salutes-to-mark-princes-birth

Ìròyìn ìbí ọba lọla igbá kẹta ni agogo mẹrin kọja ìṣẹ́jú mẹ́rin-lè-lógún jáde ni bi agogo mẹjọ àbọ̀, ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejilelogun, oṣù keje ọdún ẹgbã-lémétàlá.

Òwe Yorù̀bá ni “Ire kì í dé ká má gbọ́ ohun gudugudu”, igbe ayọ̀ ti o ti jáde ni gbogbo àgbáyé kọjá gudugudu lati àná.  Gbogbo ìlú, ọba àti ìjòyè ló mbá Ìyá-Bàba-Bàbá-Ọmọ Queen Elizabeth II, Bàba-bàbá-ọmo, Bàbá àti Ìyá ọmọ – Ayaba Kate àti  Ọmọba William yọ lati ìgbà ti ìròyìn ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Oníròyìn ti fi etí sọ́nà fún jáde.   Àwọn Ológun ti yin ọ̀kàn-lé-lógún sókè lati ki ọmọ titun  káàbọ̀ si ayé.

A kí bàbá àti ìyá ọmọ àti gbogbo ẹbí pé wọ́n kú orí-ire.

ENGLISH TRANSLATION

The news of the birth of the baby boy born at 4.24 p.m., the third in line to the throne of the United Kingdom, was announced at about 8.30 on Monday, 22 July, 2013.

According to the “Yoruba Proverbs” as translated by Oyekan Owomoyela “Good fortune does not arrive without being trailed by the sound of the gudu-gudu drum” meaning (Good fortune must be greeted with rejoicing), the shout of joy that was herald by the entire world was surely more than the gudu-gudu drum.  The entire country, the prominent and the lowly have been rejoicing with the paternal Great-grandmother – Queen Elizabeth II, the paternal Grand-father, the father and Mother, Duchess Kate and Prince William since the news was broken to the teaming Journalists and the public that have been awaiting for this news.  The Military gave twenty-one gun salute to welcome the new baby to the world.

Congratulations to the new father and mother as well as the entire family.

Share Button

“Ká kú lọ́mọdé kó yẹni sàn ju ki á dàgbà ẹ̀sin” Ológun Onilù Lee Rigby relé: “To die honourable at a young age is better than aging in disgrace”

Lee Rigby: Military Funeral for killed Soldier

Lee Rigby: Military Funeral for killed Soldier

http://www.bbc.co.uk/news/uk-england-23263754

Òṣèlú, ìjọ, ẹbi àti ará ìlúoba ṣe ẹ̀yẹ ìkẹhìn fún Onílù Lee Rigby ti o jade láyé lojiji lati ọwọ́ Michael Adébọ̀lájọ́ àti Michael Adébọ̀wálé ni oṣu karun ọdun yi.  Ilu dakẹ rọrọ fún ẹ̀sin nipa tí tò si ọ̀nà ti wọ́n gbé òkú rẹ gba lọ si ilé ijọsin.

Yorùbá ni “Ká kú lọ́mọdé kó yẹni sàn ju ki á dàgbà ẹ̀sin” fi han wípé bi ó ti jẹ ọmọ ọdún marun-lélógún ni nigbati ìṣẹ̀lẹ̀ ibi yi sẹlẹ̀, wọn si òkú Lee Rigby bi ọba.  Awọn ti o ge ẹ̀mí rẹ kúrú wà ni ọgbà ẹwọn, lati dàgbà ẹsin ninu ẹwọn.

Ki Ọlọrun tu ẹbi àti ọmọ Olõgbé ninu.  Sùn re o Onílù Lee Rigby.

ENGLISH TRANSLATION

The Politicians, the Church, Family and the people of the United Kingdom came together to pay their last respect to the late Soldier, Drummer Lee Rigby that met his untimely death in the hands of duo Michael Adebolajo and Michael Adebowale.  The Town stood still by lining the Street while the burial procession to the Church.

Yoruba adage said “It is better to die honourably at young age than to age with disgrace”.  This adage showed that even though Lee Rigby was only 25 years at the time of the unfortunate death, he was given a burial befitting for the King.  Those who cut his live short are in prison to age with disgrace in prison.

May God console his family especially his young son.  Rest in peace Drummer Lee Rigby.

Share Button

ÒKÚ NSUKUN Ò̀KÚ, AKÁṢỌLÉRÍ NSUKUN ARA WỌN: The Dead Weeps for the Dead — Yoruba Obituary for Margret Thatcher

ÌSÌNKÚ IYÃFIN MARGARET THATCHER

Wọn ṣe ẹ̀sìn ìsìnkú fún Olõgbe Iyãfin Margaret Hilda Thatcher – Obìnrin àkọ́kọ́ Olórí Òṣèlú Ìlúọba ni Ọjọ́rú, oṣù kẹrin ọjọ́ kẹtàdìnlógún ọdún ẹgbẹrunmejiIemẹtala.  Ọmọ ọdún mẹtadinladọrun ni nigbati ó dágbére fún ayé ni oṣù kẹrin ọjọ kẹjọ, ọdún ẹgbẹrunmejilemẹtala.

The coffin is carried on a gun carriage drawn by the King"s Troop Royal Artillery

The coffin is carried on a gun carriage drawn by the King”s Troop Royal Artillery.

Yorùbá ni “Òkú nsukun òkú, akáṣolérí nsukun ara wọn” ìtumọ̀ èyí ni wípé kò sẹ́ni tí kò ní kú, olówó, aláìní, ọmọdé, arúgbó, Òṣèlú, Ọba àti Ìjòyè á kú tí àsìkò bá tó, nitorina, ẹni to sunkun, sunkun fún ara rẹ, ẹni tó mbinu, mbinu ara rẹ nitori, ẹni tó kú ti lọ.

Ojúọjọ́ dára, ètò ìsìnkú nã lọ dédé láìsí ìdíwọ́.

Sunre o, Olõgbe Iyãfin Margaret Hilda Thatcher, ó dìgbà.

ENGLISH TRANSLATION

The funeral service for Late Baroness Margaret Hilda Thatcher – the first female Prime Minister in the United Kingdom, was held on Wednesday, April 17, 2013, she bade the world farewell on April 8, 2013.  She passed on at the age of 87.

A Yoruba adage says: “The dead is weeping for the dead, while the mourners are weeping for themselves”, this means that there is no one who will not die: rich, poor, young, old, Politicians, King/Queen and Chiefs will die when it is time, as a result, those weeping are weeping for themselves, those angry are angry at themselves because the dead is gone.

The weather was good, the funeral service went well without any hitch.

Sleep on, Late Baroness Margaret Hilda Thatcher, farewell.

Read the article referred to by this post at at http://www.bbc.co.uk/news/uk-22151589

Share Button

NÍNÍ OWÓ BABA ÀFOJÚDI, ÀÌNÍ OWÓ BABA ÌJAYÀ: Abundance of Money is the Father of Insolence and Lack of Money the Father of Panic

Welfare System Reforms -- BBC

BBC article on benefit cuts, aini owo baba ijaya.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá yi ba ìjọba Ìlúọba àti àwọn ará ìlú wi. Ìjọba njaya nítorí owó ti o nwọle kò kárí owó lati ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀tọ́ ti àwọn ará ìlú nri gbà.  Àwọn ti o si ngba ẹ̀tọ́ lọ́dọ̀ ìjọba njaya nítorí, ẹ̀tọ́ ti Ìjọba ndiku yio mu ìnira bá wọn nítorí ẹ̀dín owó yi bọ́sí àsìkò ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ àti ohun ìtura míràn.

Gẹ́gẹ́bí ilé iṣẹ́ amóhùn máwòran Ìlúọba ti ròyìn, lati Oṣù kẹrin, ọjọ́ kini, ọdún ẹgbẹ̀rúnmẽjilemẹtala, Ìjọba Ìlúọba bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtúnṣe lati dín gbèsè ti ìlú jẹ ku; gbígba àwọn òṣìṣẹ́ ni ìyànjú ki wọn tẹra mọ́ṣẹ àti ki àwọn ti ko ṣiṣẹ́ le padà si ẹnu iṣẹ́.  Díẹ̀ nínú àwọn àtúnṣe yi ni: ìdérí owó ìrànlọ́wọ́ si poun mẹrindinlọgbọn lọ́dún fún ìdílé; yíyọ owó fún yàrá tó ṣófo; àtúnṣe fún Ilé Ìwòsàn lapapọ àti bẹ̃bẹ lọ.

Yorùbá ni “Kòsọ́gbọ́n tí o lèda, kòsíwà tí o lèhù  tí o lè  fi tẹ ayé lórùn”,  bí ọ̀pọ̀ ti nyin ìjọba bẹ̃ni ọ̀pọ̀ mbu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu àtúnṣe wọnyi wípé Ìjọba ngba lọ́wọ́ aláìní fún àwọn tóní.

ENGLISH TRANSLATION >>> Continue reading

Share Button