Ìbá ṣe pọ̀ laarin Yorùbá àti Ìlú-Ọba ti lé ni igba ọdún nitori òwò Òkè-òkun, pàtàki òwò ẹrú àti fún ẹ̀kọ́ ni ilé iwé giga. Nitori eyi, àṣà àti èdè Yorùbá kò ṣe fi ọwọ́ rọ sẹhin.
Ni Ilú-Ọba, ẹ̀tọ́ ará ilú ni ki Ìjọba pèsè ohun amáyédẹrùn, pàtàki ibùgbé fún ọmọ ilú, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́ fún ọmọ àti ará ilú. Àwọn ẹ̀tọ́ wọnyi kò tọ́ si àlejò, ẹni ti ó fi èrú wọ ilú ti kò ni àṣẹ igbelu, tàbi ẹni tó ni iwé lati ṣe iṣẹ ṣùgbọ́n ko ti i di ará ilú. Ẹni ti ó ni iwé-igbelu lati ṣe iṣẹ́ ti ko ti di ará ilú kò ni ẹ̀tọ́ si ilé Ìjọba, ṣùgbọ́n wọn ni ẹ̀tọ́ si ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́. Iwé ìròyìn irọlẹ, gbe jade bi Trudy Alli-Balogun, ti lo ipò rẹ ni ilé iṣẹ́ ti ó nṣe ipèsè ibùgbé fún ọmọ ilú, lati gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Yorùbá ti kò ni ẹ̀tọ́ si irú ilé bẹ́ ẹ̀. Wọn ṣe ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún marun fún.
Ìròyìn ti ó gbòde ni inu iwé ìròyìn àti lori ayélujára fi han bi àwọn Olóri Òṣèlú, Aṣòfin àgbà nla àti kékeré, òṣiṣẹ́ Ìjọba àgbà àti àwọn ti ó wà ni ipó giga ni Nigeria ti lo ipò wọn lati fi ja ilu lólè. Àyipadà ni Ìjọba pẹ̀lú pe Olóri Òṣèlú Muhammadu Buhari/Yẹmi Osinbajo ti ó gbógun ti iwà ibàjẹ́, ló jẹ ki àṣiri iṣẹ́ ibi wọnyi jade si ará ilú bi àwọn ti ó wà ni ipò giga ti nlo ipò lati fi hu iwà ibàjẹ́ nitori àti kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà ẹ̀bùrú.
Yorùbá sọ wi pé “Ìṣe ilé ló mbá ni dode”. Ni àtijọ́, àṣà Yorùbá ni lati wá idi bi enia ti kó ọrọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ni ayé òde oni, olówó ni wọ́n mbọ, bi ó bá ti ẹ jalè tàbi ti ẹ̀wọ̀n de nitori iṣẹ́ ibi. Àyipadà burúkú yi ni obìnirin Trudy Alli-Balogun gbé dé ẹnu iṣẹ́ lati ja ilé iṣẹ́ rẹ ni olè ọ̀kẹ́ aimoye, ti ó si na owó bẹ́ ẹ̀ ni ìná àpà lai ronú orúkọ burúkú ti ó rà fún Yorùbá àti gbogbo orilẹ̀ èdè Nigeria ni Ilú-Ọba àti pé irú iwà ibàjẹ́ yi ló ba ohun amáyédẹrùn jẹ ni Nigeria. Iwà ibàjẹ́ kò ni orúkọ meji, ẹni ba jalè ba ọmọ jẹ́.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2016-05-06 23:39:56. Republished by Blog Post Promoter