Idibò lati yan Olóri àti àwọn Òṣèlú wáyé ni ọjọ́ keje, oṣù karun, ọdún Ẹgbãlemẹ̃dógún lẹhin ọdún
marun ti wọn ṣe ikan kọja. Àsikò idibò kò dá iṣẹ́ dúró, kò si ijà tàbi ji àpóti ibò àti iwà burúkú miran ti ó nṣẹlẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú
Gbogbo Olóri ẹgbẹ́ Òṣèlú meje ti ó jade, polongo pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ fún ibò ará ilú. Wọn kan ilẹ̀kùn, wọn pin iwé lati ṣe àlàyé ohun ti wọn yio ṣe fún ilú. Ẹni ti ó wà lori oyè, David Cameron ti ó ndu ipò rẹ padà, lọ lati ibẹ̀rẹ̀ dé òpin Ìlú-Ọba lati ṣe àlàyé ohun ti ẹgbẹ́ rẹ ṣe fún ilú àti eyi ti ó kù ti àwọn yio ṣe. Àwọn Òṣèlú Ìlú-Ọba kò pin ìrẹsì àti owó lati ra ibò bi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdu pàtàki ni orilẹ̀ èdè Nigeria.
Gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá igbàlódé, “Ṣàdúrà, ki nṣe Àmin, ijà ò si ni Ṣọ́ọ̀ṣì”, àwọn Òṣèlú Ilu-Oba kò sọ idibò di ijà, ẹgbẹ́ kan kò rán jàndùkú si ọmọ ẹgbẹ́ keji, wọn ò ji àpóti ibò, wọn ò sọ ipò Òṣèlú di oyè idilè bi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdu ti ó nlo ipò wọn lati mú àwọn èniyàn wọn lẹ́rú. Bi ó bá di àsikò idibò, wọn a lo ẹ̀sin àti ẹ̀yà lati pin ará ilú dipò ki wọn sọ ohun ti wọn ṣe tàbi ohun ti wọn yio ṣe lati tú ilú ṣe pàtàki lati gba ilú lọwọ òkùnkùn àti àwọn olè ti ó nṣe Ìjọba. Ó yẹ ki àwọn Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdu fi eyi kọ́gbọ́n.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading