Orúkọ ẹni ni ìfihàn ẹni, orúkọ Yorùbá fi àṣà, iṣẹ́ àti Òriṣà idile hàn tàbi àtẹsẹ̀bi ọmọ. Yorùbá gbàgbọ́ ninú Ọlọrun/Eledumare ki ẹ̀sin igbàgbọ́ àti imọ̀le tó dé. Ifá jẹ́ ẹ̀sin Yorùbá, nitori Ifá ni wọn fi ńṣe iwadi lọ́dọ̀ Ọlọrun ki Yorùbá tó dá wọ́ lé ohunkohun. Yorùbá gbàgbọ́ ninú àwọn iránṣẹ́ Ọlọrun ti a mọ̀ si “Òriṣà”. Àwọn Òriṣà Yorùbá pọ̀ ṣùgbọ́n pàtàki lára àwọn Òriṣà ni: Ògún, Ṣàngó, Ọya, Yemọja, Oṣó, Ọ̀ṣun, Olokun, Ṣọ̀pọ̀ná, Èṣù àti bẹ̃bẹ̃ lọ. Àwọn orúkọ ti ó fi ẹ̀sin àwọn Òriṣà wọnyi hàn ti ńparẹ́ nitori àwọn ẹlẹsin igbàlódé ti fi “Oluwa/Ọlọrun” dipò orúkọ ti ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ifá, Ògún, Èṣù àti bẹ̃bẹ̃ lọ. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ wọnyi:
ENGLISH TRANSLATION
One’s name is one’s identity, Yoruba names reflect the culture, trade, gods being worshipped in the family as well as the situation in which a child was born. Yoruba had faith in the Almighty God of Heaven ever before the advent of Christianity and Islam. Ifa was then the religion of the Yoruba people, because “Ifa” was the medium of consulting God before embarking on any venture. Yoruba believed in the messengers of God known as mini gods called “Orisa”. There many mini gods but prominent among them are: Ogun – god or Iron; Sango – god of thunder and lightning; Oya – river Niger goddess, wife of Sango; Yemoja – goddess of all rivers; Oso – wizard deity, Osun – river goddess; Olokun – Ocean goddess; Sopona – deity associated with chicken pox; Esu – god of protector as well as trickster deity that generates confusion; etc. The names that were associated with all these Yoruba gods are disappearing because they are being replaced with “Olu, Oluwa, Olorun”, to reflect the modern beliefs. Check below names that associated with the traditional and modern faith:
IFÁ – Yoruba belief of Divination
Orúkọ idile Yorùbá | Orúkọ igbàlódé ti ó dipò orúkọ ibilẹ̀ | English/Literal meaning – IFA –Yoruba Religion |
Fábùnmi | Olúbùnmi | Ifa/God gave me |
Fádádunsi | Dáhùnsi | Ifa responded to this |
Fadaisi/Fadairo | Oludaisi | Ifa/God spared this one |
Fadójú/Fadójútimi | Ifa did not disgrace me | |
Fádùlú | Ifa became town | |
Fáfúnwá | Olúfúnwá | Ifa/God gave me to search |
Fágbàmigbé | Ifa did not forget me | |
Fágbàmilà/Fagbamiye | Ifa saved me | |
Fágbèmi | Olúgbèmi | Ifa/God supported me |
Fagbemileke | Oluwagbemileke | Ifa/God made me prevail |
Fágbénró | Olúgbénró | Ifa/God sustained me |
Fágúnwà | Ifa straightened character | |
Fájánà/Fatona | Ifa led the way | |
Fájọbi | Ifa joined at delivery | |
Fájuyi | Ifa is greater than honour | |
Fakẹyẹ | Ifa gathered honour | |
Fálànà | Olúlànà | Ifa/God opened the way |
Fálayé | Ifa is the way of the world | |
Fáléti | Ifa has hearing | |
Fálọlá | Ifa is wealth | |
Fálolú | Ọláolú | Ifa is god |
Fámùkòmi/Fáfúnmi | Olúwafúnmi | Ifa/God gave to me |
Fámúrewá | Ifa brought goodness | |
Farinre | Ọlarinre | Ifa/Wealth came in goodness |
Fáṣeun | Olúwaṣeun | Thanks to Ifa |
Faséùn/Fápohùndà | Ifa kept his words | |
Fáṣọlá | Olúṣọlá | Ifa/God created wealth |
Fatimilẹhin | Oluwatimilẹhin | Ifa/God supported me |
Fátúnàṣe | Ifa repaired morals | |
Faturoti | Ifa is worth waiting on | |
Fáyẹmi | Olúyẹmi | Ifa/God suits me |
Fayoṣe | Ifa will perform it | |
Ọláifá | Ọláolú | Ifa’s wealth |
Originally posted 2014-07-11 20:39:12. Republished by Blog Post Promoter