Ẹ̀sìn ti wa láyé, ki ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ àti Mùsùlùmi tó dé. Fún àpẹrẹ, Yorùbá gbàgbọ́ ninú “Ọlọrun” ti Yorùbá mọ̀ si “Òrìṣà-òkè” tàbi “Eledumare”. Bi Yorùbá ṣe ḿbá Ọlọrun sọ̀rọ̀ ni ayé àtijọ́ ni ó yàtọ̀ si ti àwọn ẹlẹ́sìn igbàlódé.
Yorùbá ńlo “Ifá” lati ṣe iwadi lọ́dọ̀ “Ọlọrun”, ohun ti ó bá rú wọn lójú. Yorùbá ma ńlo àwọn “Òrìṣà” bi “Ògún”, “Olókun”, “Yemọja”, “Ọya”, “Ṣàngó” àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bi “Onílàjà” larin èniyàn àti Eledumare.
Yorùbá ni “Ẹlẹkọ ò ni ki Alákàrà má tà”. Ẹ̀sìn ti fa ijà ri, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, àti ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀, Onigbàgbọ́ àti Mùsùlùmi ló ńṣe ẹ̀sìn wọn lai di ẹnikeji lọwọ. Ni òkè-òkun, ẹni ti ó ni ẹ̀sìn àti ẹni ti kò ṣe ẹ̀sìn kankan ló ńṣe ti wọn lai di ara wọn lọ́wọ́. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán yi: Mùsùlùmi àti Onígbàgbọ́ ńṣe ìwàásu lẹgbẹ ara wọn.
Ó ṣe pàtàki ki ẹ ma jẹ ki àwọn Òṣèlú tàbi alai-mọ̀kan lo ẹ̀sìn lati fa ijà tàbi ogun, nitori “Ojú ọ̀run tó ẹyẹ fò lai fi ara gbọ́n ra”.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2014-09-05 13:05:43. Republished by Blog Post Promoter