Tag Archives: Refuse disposal

“Ìmọ́tótó borí àrùn mọ́lẹ̀, bi ọyẹ́ ti ḿborí ooru” – “Cleanliness conquers disease as cold (harmattan) overcomes the heat”

Ìmọ́tótó borí àrùn mọlẹ̀, bọ́yẹ́ ti ḿborí ooru
Àrùn ìwọ̀sí tinú ẹ̀gbin là wá
Iná ni ḿborí aṣọ ẹlẹ́gbin

Ni ayé àtijọ́ tàbi, lati bi agogo marun idaji ni ìmọ́tótó ti bẹ̀rẹ̀, nipa gbigbá inú àti àyiká ilé.  Lẹhin eyi, àwọn àgbàlagbà á ṣe itọ́jú ara, wọn o si bójú tó bi àwọn ọmọ ilé-iwé yio ti ji, wẹ̀, múra, jẹun àti palẹ̀mọ́ àti kúrò ni ilé lọ si ilé-iwé àti ki àwọn àgbàlagbà lọ si ibi iṣẹ́ òòjọ́.

Mọ́inmọ́in/Ọ̀lẹ̀lẹ̀ Eléwé – Leaf wrapped steamed beans cake. Courtesy: @theyorubblog

Mọ́inmọ́in/Ọ̀lẹ̀lẹ̀ Eléwé – Leaf wrapped steamed beans cake. Courtesy: @theyorubblog

Pàǹtí ni àtijọ́ wúlò fún ajílẹ̀ nitori ara oúnjẹ ni. Ewé ni wọn fi ńpọ́n oúnjẹ tàbi ki wọn bu oúnjẹ sinú abọ́ àlò-tún-lò, omi wa ninú àmù (ikòkò amọ̀), ṣùgbọ́n láyé òde òni, ike aláyọ́ ni wọn fi ńbu oúnjẹ, wọn a si mu omi ninú àpò ọ̀rá.  Ike àti ọ̀rá ki kẹ̀, ó si léwu fún ẹja odòàti ẹranko lati gbé mi, ó tún léwu fún àyìká.  Àwọn ọ̀rá àti ike wọnyi pẹ̀lú nkan ti ó dá kún pàǹtí.

Ìmọ́tótó jinà si àwọn ara ilú ńlá, pàtàki, ilú Èkó nibiti ọpọ òṣiṣẹ́ ti ji jade lọ si ibi iṣẹ́ ki agogo marun idaji tó lù, bẹni wọn kò ni wọlé titi di agogo mẹwa alẹ́ nitori sún-kẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ̀.  Eyi kò lè jẹ ki wọn ri àyè tọ́jú inú ilé, àyiká tàbi ara.   Ìjọba tún dá kún ẹ̀gbin ti ó gba ilú kan nitori ai pèsè àyè àti itọ́jú fún pàǹtí.  Eleyi ńjẹ́ ki ará ilú kó ohun ẹ́gbin si ibikibi, bi oju-àgbàrá, ẹ̀bá-ọ̀nà, ori titi, inú odò àti bẹ̃bẹ̃ lọ.  Kikó ohun ẹ̀gbin di ojú-àgbàrá ńfa adágún omi ti ó ńfa ẹ̀fọn, ikún omi àti àrùn lati ara kòkòrò ti pàǹtí fa.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Ìmọ́tótó borí àrùn mọ́lẹ̀, bi ọyẹ́ ti ḿborí ooru” àti orin Ìmọ́tótó ti wọn fi ńkọ́ àwon ọmọ ilé-iwé alakọbẹrẹ ṣe iranti à ti wá nkan ṣe si pàǹtí ti ó gba ilú kan.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-10-21 09:25:00. Republished by Blog Post Promoter