Tag Archives: Reactions to Marriage Equality rulings

“Èèmọ̀ ni ki ọkùnrin fẹ́ ọkùnrin tàbi ki obinrin fẹ́ obinrin ni Àṣà Yorùbá ” – “Same Sex Marriage is a strage occurrence to Yoruba Traditional Marriage”

Ilé Ẹjọ́ Àgbà yi Àṣà Ìgbéyàwó Àdáyébá padà ni ilú Àmẹ́ríka.  Ni ọjọ́ Ẹti, Oṣù kẹfà, ọjọ́ Kẹrindinlọ́gbọ́n, ọdún Ẹgbãlemẹdógún, Ilé Ẹjọ́ Àgbà ti ilú Àmẹ́ríkà ṣe òfin pé “Kò si Ìpínlẹ̀ Àmẹ́ríkà ti ó ni ẹ̀tọ́ lati kọ igbéyàwó laarin ọkùnrin pẹ̀lú ọkùnrin tàbi obinrin pẹ̀lú obinrin”.  Ijà fún ẹ̀tọ́ lati ṣe irú igbeyawo yi ti wà lati bi ọdún mẹrindinlãdọta sẹhin, ṣùgbọ́n ni oṣù kẹfà, ọdún Ẹgbãlemẹ́tàlá, Ilé Ẹjọ́ Àgbà fi àṣẹ si pé ki Ìjọba Àpapọ̀ gba àṣà ki ọkùnrin fẹ́ ọkùnrin tàbi ki obinrin fẹ́ obinrin, lati jẹ ki àwọn ti ó bá ṣe irú igbéyàwó yi lè gba ẹ̀tọ́ ti ó tọ́ si igbéyàwó àdáyébá – ohun ti ó tọ́ si ọkùnrin ti o fẹ́ obinrin, nipa ogún pinpin, owó ori tàbi bi igbéyàwó ba túká.

Julia Tate, left, kisses her wife, Lisa McMillin, in Nashville, Tennessee, after the reading the results of the <a href="http://www.cnn.com/2013/06/26/politics/scotus-same-sex-main/index.html">Supreme Court rulings on same-sex marriage</a> on Wednesday, June 26. The high court struck down key parts of the <a href="http://www.cnn.com/interactive/2013/06/politics/scotus-ruling-windsor/index.html">Defense of Marriage Act</a> and cleared the way for same-sex marriages to resume in California by rejecting an appeal on the state's <a href="http://www.cnn.com/interactive/2013/06/politics/scotus-ruling-perry/index.html">Proposition 8</a>.

Obinrin fẹ́ obinrin – Lesbian Relationship reactions to the Supreme Court Ruling

Ìjọba-àpapọ̀ ti ilú Àmẹ́ríkà gba òfin yi wọlé nitori “Òfin-Òṣèlú ni wọn fi ndari ilú Àmẹ́ríkà”.  Lati igbà ti ìròyìn ìdájọ́ yi ti jade, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àgbáyé, pàtàki àwọn Ẹlẹ́sin Igbàgbọ́ ti nda ẹ̀bi fún Ìjọba Àmẹ́ríkà pé wọn rú òfin Ọlọrun nipa Igbéyàwó.

Ni àṣà igbéyàwó Yorùbá, èèmọ̀ ni ki ọkùnrin fẹ́ ọkùnrin tàbi ki obinrin fẹ́ obinrin.  Ki ẹbi ma ba parẹ́, ọmọ bibi jẹ ikan ninú ohun pàtàki ni igbéyàwó.  Bi ọkùnrin bá fẹ́ ọkùnrin, wọn ò lè bi ọmọ lai si pé wọn gba ọmọ tọ́ tàbi ki wọn wa obinrin ti yio bá wọn bi ọmọ tàbi bi ó bá jẹ laarin obinrin meji ti ó fẹ́ ara, ikan ninú obinrin yi ti lè bimọ tẹ́lẹ̀ tàbi ki ó wá ọkùnrin ti yio fún ohun lóyún ki wọn lè ni ọmọ ni irú igbéyàwó yi.

Yorùbá ni “Bi a ti nṣe ni ilé wa, èèwọ̀ ibòmíràn” òfin Àmẹ́ríkà yi jẹ́ èèmọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá nitori a kò gbọ tàbi ka a ninú itàn àṣà Yoruba  .  Ki ṣe gbogbo èèmọ̀ ni ó dára, fún àpẹrẹ, ni igbà kan ri èèmọ̀ ni ki èniyàn bi àfin, tàbi bi ibeji nitori eyi, wọn ma npa ikan ninú àwọn meji yi ni tàbi ki wọn jù wọn si igbó lati kú, ṣùgbọ́n láyé òde òni àṣà ji ju ibeji tàbi ibẹta si igbó ti dúró.  Kò yẹ ki ẹnikẹni pa ẹnikeji nitori àwọ̀ ara tàbi nitori ẹni ti èniyàn bá ni ìfẹ́ si.  Ni ilú Àmẹ́ríkà ni àwọn ti ó fi ẹsin Ìgbàgbọ́ bojú ti kó si abẹ́ àwọn Aṣòfin ilú Àmẹ́ríkà ni ayé àtijọ́ pé Aláwọ̀dúdú ki ṣe èniyàn, nitori eyi, ó lòdi si òfin ki Aláwọ̀dúdú fẹ́ Aláwọ̀funfun, bi wọn bá fẹ́ra, wọn kò kà wọn kún tàbi ka irú ọmọ bẹ ẹ si èniyàn gidi.  Bẹni wọn lo òfin burúkú yi naa lati pa Aláwọ̀dúdú lẹhin isin ni aarin igboro lai ya Aláwọ̀dúdú ti wọn kó lẹ́rú lati ilẹ Yorùbá sọtọ.  Ogun abẹ́lé àti ṣi ṣe Òfin Àpapọ̀ tuntun lẹhin ogun, ni wọn fi gba àwọn Aláwọ̀dúdú silẹ̀ ni ilú Àmẹ́ríkà.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-07-21 19:46:00. Republished by Blog Post Promoter