Òwe Yorùbá sọ pé “Ẹni a lè mú, là nlèdí mọ́”. Òwe yi fi iwà burúkú nipa ìwà/ìjà-agbára ti ó nṣẹlè ni inú ilé, pàtàki laarin ọkùnrin àti obinrin tàbi ọkọ àti ìyàwó. Ki ṣe ọkùnrin nikan ló nhu ìwà/ìjà-agbára si obinrin, obinrin oníjà miran ma nhu ìwà/ìjà-agbára si ọkùnrin tàbi si ọkọ, ṣùgbọ́n, eyi ti ó wọ́pọ̀ jù ni ọkùnrin si obinrin.
Bawo ni ènìyaìn ṣe lè sọ pé, ohun ni ìfẹ́ nigbati ó bá hu ìwà-agbára si ẹni ti ó fẹ́ràn? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé yi, ẹni tó nhu ìwà/ìjà-agbára ìwà burúkú ma nṣe si ẹni ti wọn bá rò pé àwọn lè mú tàbi ti wọn ni agbára ni ori rẹ. Àwọn ti wọn hu iwa-agbara si yi, ki le fi ẹjọ́ sùn, nitori ìbẹ̀rù ẹni ti ó ni agbára jù wọn lọ, pàtàki laarin ọkọ àti aya. Obinrin ti ó njẹ iya ìwà/ìjà-agbára ki lé tètè kúrò tàbi ki wọn fi ẹjọ́ sùn nitori àwọn idi pàtàki bi: ìfẹ́ si ẹni ti ó nhu ìwà/ìjà-agbára; àyípadà; itiju ki èrò ma gbọ́; ai fẹ ki ìgbéyàwó túká; ai lè dá dúró nitori owó tàbi àwọn ọmọ ti wọn bi si irú ilé bẹ-ẹ; ìyà ti mọ́ra; àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìbínú burúkú ló nfa iwa/ija-agbara. Igbẹhin ìwà/ìjà-agbára ki já si ire, nitori irú ìwà burúkú yi lè fa ikú ojiji; àrùn ọpọlọ; ìrẹ̀wẹ̀sì; li lọ si ẹ̀wọ̀n; ìbànújẹ́ fún àwọn ọmọ; àbùkù fún ẹni ti ó hu irú ìwà yi àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Irú àbùkù yi ló kan “Ray Rice” nigbati ìjà-agbára ti ó bá Àfẹ́sọ́nà rẹ̀ jà ninú ẹ̀rọ-àkàbà ti ó lu jade si gbogbo àgbáyé ninú ìròyìn àti ori ayélujára. Gẹgẹbi òwe Yorùbá ti ó sọ pé “Aṣeni ṣe ara rẹ, asánbàǹtẹ́ so ara rẹ lókùn”, lati ìgbà ti àṣiri ìwà/ìjà-agbára ti “Ray Rice” hu ti tú, aṣeni ti ṣe ara rẹ nitori iṣẹ rẹ ti bọ́.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading