Tag Archives: PROPHET OBADARE

WÕLI ỌBÁDÁRE SÙN NÍNÚ OLÚWA: PROPHET OBADARE SLEPT IN THE LORD

Ìròyìn wípé Wõli Timoteu Ọbádáre, Olùdásílẹ̀ Ìjọ “Olùjèrè Ẹ̀mí Oníhìnrere Iṣẹ́ Ìránsé” sùn nínú Olúwa jáde ni ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹta ọdún ẹgbẹ̀rúnméjì lémẹ́tàlá.

Wõli Ọbádáre jẹ ìkan nínú àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọrun àgbáyé nítorí ẹ̀ka Ìjọ ti wọn pè ni WOSEM wa kãkiri ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú àti ní Òkè-òkun/Ìlú-òyìnbó.  Ẹ̀ka Ìjọ Wõli Ọbádáre wà ni London, New York àti bẹ̃bẹ lọ. Nígbà ayé õlogbe yi, ó fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìhìnrere.

Sùnre lẹ́sẹ̀ Jésù, Wõli Timoteu Ọbádáre.

ENGLISH TRANSALATION

The news that Prophet Timothy Obadare, Church Founder “Soul Winning Evangelical Ministry” popularly known as “WOSEM” slept in the Lord on Friday, 22nd March, 2013.

Prophet Obadare was one of the Evangelists in the world because Soul Winning Evangelical Ministry (WOSEM) is spread in various countries of Africa and with branches Abroad/Europe such as in London, New York etc.  During his lifetime, he worked devotedly to spread the gospel.

Sleep well at the feet of Jesus Prophet Timothy Obadare.

Share Button