Nelson Mandela memorial: Obama lauds ‘giant of history’
Yorùbá ni “Òṣìkà kú, inú ilú dùn, ẹni rere kú inú ilú bàjẹ́”. Bi o ti le jẹ́ pé Nelson Mandela ti pé marun din-lọgọrun ọdun láyé (1918 – 2013), gbogbo àgbáyé ṣe dárò rẹ nitori ohun ti ó gbé ilé ayé ṣe. Ó fi ara da iyà lati gba àwọn enia rẹ sílẹ̀ ni oko ẹrú ni ilẹ̀ wọn. Ó fi ẹmi ìdáríjì han nigbati ó dé ipò Olórí Òṣèlú. Kò lo ipò rẹ lati kó ọrọ̀ jọ, ó gbé ipò sílẹ lẹhin ti ó ṣe ọdún marun àkọ́kọ́. Eleyi jẹ́ ki ọmọdé, àgbà, Òṣèlú, Ọlọ́rọ̀, Òtòṣì, funfun àti dúdú papọ̀ nibi ètò ìrántí rẹ ni Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọjọ́ Kẹwa, Oṣù Kejila, ọdún Ẹgba-̃le-mẹtala.
Ìgbà àti àsìkò Nelson Mandela jẹ àríkọ́gbọ́n fún gbogbo àgbáyé pataki àwọn ti ó wà ni ipò Òṣèlú. Ìjọba ilú South Africa ṣe àlàyé ètò ìsìnkú rẹ bayi:
Àìkú, Ọjọ́ kẹjọ, Oṣù Kejila, ọdún Ẹgbã-le-mẹtala: Ọjọ́ àdúrà àpa pọ̀
Ìṣégun, Ọjọ́ kẹwa, Oṣù Kejila, ọdún Ẹgbã-le-mẹtala: Ètò ìrántí
Ọjọ́rú, Ọjọ́bọ̀ àti Ẹti, Ọjọ́ kọkọnla si ikẹtala, Oṣù Kejila, ọdún Ẹgbã-le-mẹtala: Ìtẹ́ òkú
Abameta, Ọjọ́ kẹrinla, Osu kejila, odun Egbalemetala: Gbigbé òkú lọ si Qunu
Aiku, Ọjọ́ karun-din-lógún, Osu Kejila, odun Egbalemetala: Ìsìnkú
ENGLISH TRANSLATION