Ó ti lé ni ọgbọ̀n ọdún ti ìyà iná monomono ti ńfi ìyà jẹ ará ilú orílẹ̀ èdè Nigeria. Nitori dáku-́dájí iná mọ̀nàmọ́na ti Ìjọba àpapọ̀ pèsè, ẹ̀rọ iná mọ̀nàmọ́na kékèké ti a lè fi wé kòkòrò búburú gbòde.
Òwe Yorùbá ti ó ni “Bi ará ilé ẹni ba njẹ kòkòrò búburú ti a ò sọ fun, hẹ̀rẹ̀huru rẹ kò ni jẹ ki a sùn” bá iṣẹlẹ ọ̀rọ̀ àti pèsè ina monamona yi mu. Pẹlu gbogbo owó ti ó ti wọlẹ̀ lóri àti pèsè ina mona-mona, ará ilé ẹni ti o ńjẹ kòkòrò búburú ti jẹ́run. Ai sọ̀rọ̀ ará ìlú lati igbà ti aiṣe dẽde iná ti bẹrẹ lo fa hẹ̀rẹ̀huru ariwo ti ọ̀pọ̀ ẹ̀rọ-iná kékèké ma ńfà. Ariwo yi pọ to bẹ gẹ, ti àtisùn di ogun. Àti ọ̀sán àti òru ni ariwo ẹ̀rọ-iná kékèké yi ma ńdá sílẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tó burú jù ni herehuru ti òru.
Ki ṣe omi, epo-rọ̀bi, èédú nikan ni a fi lè ṣe ètò ina mona-mona. A lè fi õrun, atẹ́gùn àti pàntí ti ó pọ̀ ni orílẹ̀ èdè wa ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ pèsè iná mona-. Ìlú ti kò ni õrun tó ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú ńfi õrun pèsè iná mona-mona.
Ohun ìtìjú ni pé fún bi ọgbọ̀n ọdún ó lé díẹ̀, àwọn Òṣèlú àti ará ìlu, kò ri ará ilé ti ó ńjẹ kòkòrò búburú báwí.
English translation: Continue reading
Originally posted 2013-10-22 03:51:57. Republished by Blog Post Promoter