Tag Archives: Power failure

“Ohun to yẹni lo yẹni, òkùnkùn ò yẹ ọmọ eniyan” – Ilé-iṣẹ́ mọ̀nà-mọ́ná: “What befits is what befit, darkness does not befit human being” – NEPA/PHCN

Ọ̀gá ninu Olórin Fela Anikulapo-Kuti kọrin pé “Ọjọ́ wo la ma bọ o, lóko ẹrú”, orin yi fa ìbèrè wípé “ọjọ́ wo la ma bọ ninu òkùnkùn ni orílẹ̀ èdè Nigeria?”

Bi eré bi àwàdà, dákú-dájí iná mọ̀nà-mọ́ná bẹrẹ ni àsikò Ìjọba Sagari, ni bi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n sẹhin.  Ni àsikò yi, ki ṣe pe iná ti ilú pèsè kò tó, ṣùgbọ́n a ṣe akiyesi pé awọn òṣìṣẹ́ ni àsikò na lọ ńyọ nkan lára àpóti iná, nitori eyi, ki ṣe gbogbo àdúgbò ni ki ni iná. Fún akiyesi, iná ilé-iwé giga àti agbègbè rẹ, awọn ilé iṣẹ́ bi ìlèṣẹ ọkọ̀ òfúrufú, ilé ìwòsàn àti bẹbẹ lọ ki lọ.  “Bi eniyan ba yọ́ ilẹ̀ dà, ohun burúkú a ma yọ́ni ṣe”, nigbati awọn òṣìṣẹ́ oníṣẹ́ ibi kò ri ẹni ba wọn wi, ọ̀rọ̀ iná lilọ bẹrẹ si gbòrò si.  Pẹlu gbogbo owó ti wọn ti na lati tú ọ̀rọ̀ iná mọ̀nà-mọ́ná ṣe, ó burú si lai ya ilé-iṣẹ́ àti ibi kankan sílẹ̀ ninu òkùnkùn.

Yorùbá ni “ohun tó yẹ ni, lo yẹ ni, òkùnkùn o yẹ ọmọ eniyan”, nitori òkùnkùn ti ilé-iṣẹ́ mọ̀nà-mọ́ná fa fún ará ilú, ọpọlọpọ ilé-iṣẹ́ ti kò kúrò ni Nigeria eleyi din ìpèsè iṣẹ́ kù, kò si iná lati tọ́jú ounjẹ eleyi jẹ ki ounjẹ wọn si, ìnáwó lori ẹ̀rọ iná mọ̀nà-mọ́ná pẹ̀lú ariwo ki jẹ ki eniyan sùn bẹni kò jẹ́ ki eniyan tabi ilé-iṣẹ́ fi owó pamọ́.

Á lérò wípé awọn ilé-iṣẹ́ ti wọn pin iná pi pèsè fún a yọ ilú kúrò ninu òkùnkùn nitori òkùnkùn kò yẹ ọmọ eniyan.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button