Oriṣiriṣi wèrè ló wà, nitori pé ki ṣe wèrè ti ó wọ àkísà ni ìgboro tàbi já sita nikan ni wèrè. Ẹnikẹni ti o nhu ìwà burúkú tàbi ṣe ìpinnu burúkú ni Yorùbá npè ni “wèrè”.
Ìpinnu ṣi ṣe, ṣe pàtàki ni ayé àtijọ́ àti òde òní. Òwe Yorùbá sọ wi pé “Bi ará ilé ẹni bá njẹ kòkòrò búburú, hẹ̀rẹ̀-huru rẹ̀ kò ni jẹ́ ki a sùn ni òru”. Àbáyọrí ìpinnu tàbi èrò burúkú kò pin si ọ̀dọ̀ ẹbi àwọn ti ó wà ni àyíká elérò burúkú, ó lè kan gbogbo àgbáyé. Fún àpẹrẹ, kò si ìyàtọ̀ laarin wèrè tó já sita nitori wèrè ni Yorùbá npe ọkọ tàbi ìyàwó ti ó ni ìwà burúkú, ẹbi burúkú, ọba ti ó nlo ipò rẹ lati rẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àti òṣèlu ti ó nja ilú ni olè lati kó owó ti wọn ji lọ si òkè òkun nibiti ohun amáyédẹrùn ti ilú wọn kò ni wà.
Gẹ́gẹ́ bi òwe Yoruba ti ó sọ wi pé “A ki sọ pé ki Wèrè ṣe òkú ìyá rẹ̀ bi ó bá ṣe ri, bi ó bá ni òhun fẹ́ sún jẹ nkọ́?” Ìtumọ̀ òwe yi ni wi pé ìpinnu pàtàki bi ìyè àti ikú kò ṣe é gbé lé wèrè lọ́wọ́. Ó yẹ ki àwọn ènìyàn gidi ti ori rẹ pé dásí ọkọ tàbi ìyàwó, ọba tàbi àwọn ti ó wà ni ipò agbára, òṣèlu ti o nfi ipò wọn jalè àti àwọn ti ó nhu ìwà burúkú yi lati din àbáyọrí ìwà burúkú lóri ẹbí, alá-dúgbò àti àgbáyé kù.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2017-11-03 22:47:56. Republished by Blog Post Promoter