À ńlo ọ̀rọ̀ yi fún àwọn Ayáni-lówó: ki ba jẹ Ilé-owó tàbi àwọn Ayáni-lówó yókù. Ọ̀pọ̀ ìgbà, Ayáni-lówó ló ndá orin nipa oye èlé ti wọn lè fi lé owó ti Onígbèsè ya.
Ni ilẹ̀ Yorùbá ohun ti a lè fi ṣe àpèjúwe Ilé-iṣẹ́ Ayáni-lówó ni bi Ọba bá fún ni nilẹ̀ lati fi dá oko, Ọba lè ni ki irú ẹni bẹ kó idá-mẹrin, tàbi idá-marun irè oko nã wá ni igbà ìkórè. Àwọn miran tún ma ńyá owó lọwọ Olówó-èlé. Ẹ̀yà Yorùbá ti a mọ si Ìjẹ̀ṣà ma ńṣe òwò aṣọ àti wúrà tità lati ilú dé ilú àti agbègbè dé agbègbè. Bi wọn ba ti ta àwin fún onibara, bi ọjọ́ bá pé, Ìjẹ̀ṣà á ji lọ si ilé Onígbèsè lati gba owó ọjà, á ni “Òṣó mã ló gbowó mi loni” nitori eyi ni wọn fi npe Ìjẹ̀ṣà ni “Òṣó mã ló”.
Ike-ìyáwó kò wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n àwọn enia ma ńyá owó lọ́wọ́ ẹbi, ọ̀rẹ́, ẹgbẹ́ àti bẹ̃bẹ lọ, lati sin òkú, sán owó ilé iwé ọmọ, ṣòwò àti fún ọ̀pọ̀ idi miran. Èlé owó irú eyi kò pọ̀ tó ti èlé ori Ike-ìyáwó, nigbà miran kò ki ni èlé.
Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ ti ó ni:“Ẹni sanwó Onífèrè ló ndá orin”. Ayáni-lówó ló ńdá orin nipa di dari èlé ori owó Ike-ìyáwó. Ẹni ti o fi owó pamọ́ ki ri èlé gbà tó èlé ti ó wà lori owò Ike-ìyáwó. Nibiti èlé owó ipamọ́ bá jẹ́ idá-ọgọrun, èlé owó ori ike-iyawo lè tó idá-marun tàbi jù bẹ̃ lọ. Bi owó bá ti tó san, ọ̀pọ̀ Ayáni-lówó lè fi ipá gba owó irú bẹ̃. Bi wọn kò ti ẹ̀ fi ipá gba irú owó bẹ̃, èlé ori owó yi á sọ ẹni ti ó yá owó di Onigbèsè rẹpẹtẹ.
Ike-ìyáwó ni iwúlò fún ẹni ti ó bá lè kó ara rẹ ni ijánu lati dá owó padà nigbati ó bá yẹ. Ike-ìyáwó dùn lati nọ́ ju owó gidi lọ nitori eyi, fún ẹni ti kò bá mọ owó ṣirò tàbi ṣọ́ra, á sọ irú ẹni bẹ̃ di òtòṣi, nigbati èlé bá gun ori èlé. Onigbèsè pàdánù òmìnira.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading