Ki ìjọba alágbádá ìgbàlódé tó dé, Yorùbá ni bi wọ́n ṣe nṣe ètò ìlú. Ètò ìlú ayé ìgbà àtijọ́ kò bẹ̀rẹ̀ tàbi pin si ọ̀dọ̀ Ọba àti Ìjòyè ìlú nìkan. Ètò ìlú bẹ̀rẹ̀ lati ìdílé, nitori kò si ẹni ti kò ni olórí ẹbí tàbi àgbà ìdílé, lẹhin eyi, àdúgbò ni àgbà àdúgbò, bẹni abúlé-oko ni Baálẹ, ọjà ni olórí.
Ètò òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá bàjẹ́ lati igbà ti àwọn ológun ti bẹ̀rẹ̀ si fi ibọn gba ipò òṣèlú, nitori wọn kò náání Ọba tàbi Ìjòyè bẹni wọn kò kọ́ ológun ni iṣẹ́-òṣèlú bi kò ṣe ki wọn gbèjà ìlú tàbi orílẹ̀-èdè. Ẹ̀yà mẹta ni Nigeria pin si tele – Yorùbá, Haúsá, Ìgbò, nṣe ètò agbègbè wọn, wọn ńsan owó-ori fún ìjọba àpapọ̀. Ni ọ̀kànlélàádọ́ta ọdún sẹhin, ìjọba ológun da gbogbo ẹ̀yà mẹtẹta yi papọ̀ ki wọ́n tó pin si ẹ̀yà méjìlá si abẹ́ ìjọba àpapọ̀. Lati igbà yi ni nkan kò ti rọgbọ.
Ètò ti ìjọba-òṣèlú lọ́wọ́lọ́wọ́ – Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwájú, fẹ́ gbé kalẹ̀ lati yan àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti yio gbé àpótí ìbò fún ipò òṣèlú nipa ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ lè dìbò yan ẹni ti ó bá wù wọ́n, dára gidigidi. Tẹ́lẹ̀, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ ni o ma ńdìbò fún àwọn ti wọn yio yàn lati gbe àpóti ìbò. Eleyi ki i jẹ ki àwọn òṣèlú mọ ará ìlú tàbi ki ará ìlú mọ àwọn ti ó wà ni ipò òṣèlú nitori wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ìbò nitori wọn ni “Bàbá Ìsàlẹ̀” lẹhin.
Nigbati wọn lo ètò titun yi ni ipinlẹ̀ Ọ̀ṣun, lati yan ẹni yio gbe àpótí ìbò fún ipò Gómìnà Ọ̀ṣun, inú gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ dùn wi pé àwọn ni ipin àti yan àwọn òṣèlú. Eleyi yi o jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ ará ìlú lè mọ àwọn ti ó wà ni ipò òṣèlú olóri àjọ ìgbìmọ̀ kékeré, Gómìnà, aṣojú ni ipinlẹ̀ àti ni ìjọba àpapọ̀.
Gómìnà ipinlẹ̀ Èkó tẹ́lẹ̀, Bọ́lá Ahmed Tinubu – ògúná gbòngbò Ẹgbẹ́ Àjọ Ìtẹ̀síwáju,́ ti polongo ètò ki àwọn ọmọ ẹgbẹ́ bẹ̀rẹ̀ si dìbò yan ẹni ti wọn bá fẹ́ ni ipò.
ENGLISH TRANSLATION
Prior to the modern democratic dispensation, Yoruba ethnic group had their system of governance. Governance in the olden days did not begin or end with the King and his Chiefs. Governance begins with the family as everyone has a family head or elder, then each neighbourhood has a leader, farm settlements is led by their leader and markets have their leader too. Continue reading