Ni igbà ipalẹ̀mọ́ idibò, ẹ̀rù ba ará ilú nitori wọn kò mọ ohun ti ó lè sẹlẹ̀. Àwọn ti ó ndu ipò jade ni rẹpẹtẹ fún ètò-òṣèlú, eyi ti ó fa ki àwọn jàndùkú bẹ̀rẹ̀ ijà ti ó fa sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ pàtàki ni ilú Èkó, eleyi fa ibẹ̀rù pé ọjọ́ idibò yio burú.
Ẹgbẹ́ Onigbalẹ – APC Logo
Yorùbá ni “Ọ̀rọ̀ ki i mi ni ikùn àgbà” ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ mi ni ikùn Ọba Èkó, Ọba Rilwanu Akiolu nigbati ó ṣe ipàdé pẹ̀lú àwọn àgbà Ìgbò Èkó, pé ti wọn kò bá dibò fún ẹni ti ohun fẹ, wọn yio bá òkun lọ. Ọ̀rọ̀ Ọba Rilwanu Akiolu bi ará ilé àti oko ninú. Eleyi tún dá kún ibẹ̀rù pé ija yio bẹ́ ni ọjọ́ idibò, nitori eyi ọpọlọpọ ará ilú ko jade lati dibò.
Gbogbo àgbáyé ló mọ̀ wi pé àwọn Òṣèlú ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú ki i fẹ gbé Ìjọba silẹ. Ki ṣe pe wọn ni ifẹ́ ilu,́ bi kò ṣe pé, ó gbà wọn láyè lati lo ipò wọn lati ji owó ilú fún ara àti ẹbi wọn. Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ Yorùbá pe “Ikú tó fẹ́ pani, bó bá sini ni fìlà, ọpẹ́ ló yẹ ká dá”, ikú tó fẹ́ pa ará ilú ti re kọja nitori ọjọ́ idibò lati yan Gómìnà àti Aṣòfin-ipinlẹ̀ ti lọ lai mú ogun dáni bi ará ilú ti rò. Ẹ ṣe àyẹ̀wò èsi idibò:
ENGLISH TRANSLATION
-
-
Ìpínlẹ̀ Èkó – Ọ̀gbẹ́ni Akinwunmi Ambọde ti Ẹgbẹ́ Onigbalẹ ló wọlé.
Lagos State – Mr. Akinwunmi Ambode of the All Progressive Congress (APC) won the election
-
-
Ìpínlẹ̀ Ògùn – Aṣòfin-àgbà, Gómìnà Ibikunle Amósùn ti Ẹgbẹ́ Onigbalẹ ló wọlé ni igbà keji.
Ogun State – Governor (Senator) Ibikunle Amosun of the All Progressive Congress (APC) re-elected.
-
-
Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ – Gómìnà Abiọlá Ajimọbi ti Ẹgbẹ́ Onigbalẹ ló wọlé ni igbà keji.
Oyo State – Governor Abiola Ajimobi of the All Progressive Congress (APC) re-elected.
-
-
Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun – Kò si idibò yan Gómìnà nitori ọjọ́ kẹsan oṣ̀u kẹjọ ọdún Ẹgbãlemẹrinla ni Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹ́gbẹ́ṣọlá ti Ẹgbẹ́ Onigbalẹ ló wọlé ni igbà keji.
Osun State – No Governorship election because on tenth of August, twenty-fifteen, Mr. Rauf Aregbesola was re-elected under the All Progressive Congress (APC).
-
-
Ìpínlẹ̀ Èkìtì – Kò si idibò yan Gómìnà nitori ọjọ́ kọkanlélógún oṣù kẹfa ọdún Egbalemerinla ni wọn yan Ogbeni Ayọdele Fayoṣe ti Ẹgbẹ Alágboòrùn wọlé.
Ekiti State – No Governorship election because on the eleventh of June, Twenty-fourteen, Mr. Ayodele Fayose was re-elected under the People’s Democratic Party
-
-
Ìpínlẹ̀ Ondo – Kò si idibò yan Gómìnà nitori ọdún mẹrin Gómìnà Oniṣègùn Olúṣẹ́gun Mimiko ko ti pe. Wọn dibò gbe wọlé padà ni abẹ́ Ẹgbẹ́ Òṣiṣẹ́ ni ọjọ́ kọkanlelogun, oṣù kẹwa ọdún Ẹgbãlemejila.
Ondo State – No Governorship election because Governor (Dr) Olusegun Mimiko has not completed his second four year term. He was re-elected under the Labour Party on the eleventh of October, Twenty-twelve.
Continue reading →
Originally posted 2015-04-14 19:16:02. Republished by Blog Post Promoter