Ọ̀rọ̀ àgbọ́sọ, pé wọn fẹ́ sún ọjọ́ idibò siwájú lu jade ni kété ti ọjọ́ idibò kù bi ọ̀sẹ̀ mẹta. Iroyin yi kọ́kọ́ lu jade lẹ́nu Ọ̀gágun Dasuki, Onimọ̀ràn Aabo fún Olóri-Òṣèlú Nigeria Jonathan Goodluck. Ó ni àwọn Ológun fẹ́ fi ọ̀sẹ̀ mẹfa dojú ijà kọ “Boko Haram”, ẹgbẹ́ burúkú ti ó ti gba àwọn ilú ni Òkè-Ọya, Nigeria lati bi ọdún marun. Nitori eyi, kò lè si àyè fún àwọn Ológun lati sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọpa lati pèsè àbò ni àsikò idibò ti wọn ti fi si oṣù keji ọdún, ọjọ́ kẹrinla.
Nigbati Olóri-Òṣèlú pe ipàdé àwọn àgbàgbà, ọ̀pọ̀ àwọn ará ilú tu jade lati tako si sún ọjọ́ idibò siwájú. Ọ̀gá ilé-iṣẹ́ Alabojuto ètò idibò, Ọ̀jọ̀gbọ́n Attahiru Jega, ṣe àlàyé fún àwọn Akọ̀wé-iroyin pé, Ìjọba sọ pé wọn kò lè dá aabo bo àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún ti àwọn yio gbà si iṣẹ́ àti ará ilú ti ó fẹ dibò ni àsikò idibò. Ó ni Ìjọba ni àwọn fẹ fi ọ̀sẹ̀ mẹfa fi taratara dojú ijà kọ “Boko Haram”, nitori eyi, Ọ̀jọ̀gbọ́n Attahiru Jega, sọ wipé àwọn kò lè fi ẹ̀min àwọn òṣìṣé àti ará ilú wewu, nitorina wọn gbà lati sún ọjọ́ idibò siwájú.
Ọjọ́ idibò tuntun lati yan Olóri-Òṣèlú yio wáyé ni ọjọ́ keji-din-lọgbọn, oṣù kẹta, idibò lati yan Gómìnà yio wáyé ni ọjọ́ kọ-kànlá oṣù kẹrin ọdún Ẹgbãlemẹdogun. Kiló ṣe ti Ìjọba kò fi taratara jà lati da aabo bo ilú lati bi ọdún marun? Owe Yoruba so wipe “Onígbèsè tó dá ogún ọdún, kò mọ̀ pé ogún ọdún nbọ̀ wá ku ọ̀la”, nitorina, ki àwọn ará ilú fi ọwọ́ wọ́nú, nitori ọjọ́ tuntun wọnyi súnmọ́ etíle. Continue reading