Tag Archives: New Year

“Ṣe bi o ti mọ ki i tẹ́ – Ọdún wọlé dé”: “One who acts moderately will not be disgraced – The Festive Period is here”

Ọdún Kérésì jẹ́ ọdún Onigbàgbọ́ lati ṣe iránti ọjọ́ ibi Jésù Olùgbàlà.  Ọjọ́ kẹjọ lẹhin ọdún Kérésìmesì ni ọdún  tuntun.  Fún ayẹyẹ ọdún, kò si iyàtọ̀ laarin Ìgbàgbọ́ àti Mùsùlùmi ni ilẹ̀ Yorùbá nitori Yorùbá gbà wi pé “Ẹni ọdún bá láyé, ó yẹ kó dúpẹ́”.  Ọpẹ́ ló yẹ ki èniyàn dá ju igbèsè ji jẹ lati ṣe àṣe hàn ni àsikò ọdún.

Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin, àwọn Àgbẹ̀ á dari wálé pẹ̀lú irè oko pàtàki iṣu.  Àwọn Oniṣòwò á ri ọjà tà nitori àsikò yi ni Bàbá àti Ìyá ma nrán aṣọ ọdún fún àwọn ọmọdé àti oúnjẹ rẹpẹtẹ fún ipalẹ̀mọ́ ọdún.  Inú ọmọdé ma ndùn nitori asiko yi ni wọn nse irẹsi àti pa adiẹ fún ọdún.  Àwọn ọmọdé á lọ lati ilé ẹbi kan si ekeji, ẹbi ti wọn lọ ki, á fún wọn ni oúnjẹ àti owó ọdún.  Àwọn àgbàlagbà naa ma ndá aṣọ ẹgbẹ́ fún idúpẹ́ ọdún, ṣùgbọ́n ki owó epo rọ̀bi tó gba igboro, ki ṣe aṣọ olówó nla bi ti ayé òde òni.

Àsikò ti olè npọ̀ si niyi pàtàki ni ilú Èkó, nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ fẹ na owó ti wọn kò ni lati ṣe ọdún.  Ìpolówó ọjà pọ̀ ni àsikò yi ni Òkè-Òkun, nitori eyi, ọ̀pọ̀ nlo ike-igbèsè tàbi ki wọn ya owó-èlè lati ra ọjà ti wọn kò ni owó rẹ.  Lẹhin ọdún, wọn a fi ọdún tuntun bẹ̀rẹ̀ si san igbèsè, nitori eyi Ìyá àti Bàbá a ma a ti ibi iṣẹ́ kan lọ si ekeji lai ni ìsimi tàbi ri àyè àti bójú tó àwọn ọmọ.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ wi pé “Ṣe bi o ti mọ ki i tẹ́ ”, nitori eyi gbogbo ọmọ Yorùbá ni ilé, ni oko, ẹ ṣe bi ẹ ti mọ, ẹ ma tori odun na ọwọ́ si nkan ti ọwọ́ yin kò tó, ki ẹ ma ba a tẹ́.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Onigbàgbọ́  ayé òde oni ki i fẹ fi èdè Yorùbá kọrin ṣùgbọ́n ẹ gbọ́ bi ọmọ Òyinbó ti kọ orin àwọn “Obinrin Rere” ni ojú iwé yi.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-12-18 23:18:09. Republished by Blog Post Promoter