Tag Archives: New Democratic Dispensation

“A ki i fi ọjọ́ kan bọ́ ọmọ tó rù”: Ìmọ̀ràn fún Òṣèlú tuntun àti àwọn ará ilú Nigeria – It takes more than One Day to Nourish a Malnourished child”: Advice for the Newly Elected Politicians and the Nigerian People

Ọmọ ki dédé rù lai ni idi.  Lára àwọn idi ti ọmọ lè fi rù ni: àìsàn, ebi, òùngbẹ, ìṣẹ́, ai ni alabojuto, òbí olójú kòkòrò, ai ni òbí àti bẹ ẹ bẹ lọ.

Orilẹ̀ èdè Nigeria ti jẹ gbogbo ìyà àwọn ohun ti ó lè mú ki ọmọ rù yi, lọ́wọ́ Ìjọba Ológun àti Òsèlú fún ọ̀pọ̀ ọdún.  Nigbati àwọn òbí ti ó fẹ́ràn ọmọ bi Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àti àwọn àgbà ti ó bèrè fún Ominira lọwọ Ilú-Ọba, ṣe Òsèlú, ilú kò rù, pàtàki ọmọ Yorùbá.  Wọn fi ọrọ̀ ajé àti iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ipinlẹ̀, pèsè ohun amáyédẹrùn fún ilú, ilé-ìwòsàn ọ̀fẹ́, ilé-iwé ọ̀fẹ́, àwọn tó jade ni ilé-iwé giga ri iṣẹ́ gidi àti pé àwọn ará ilú tẹ̀ lé òfin.  Eyi mú ìlọsíwájú bá ilẹ̀ Yorùbá ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú.

Ilú bẹ̀rẹ̀ si rù lati igbà ti Ìjọba Ológun àkọ́kọ́ ti fi ipá kó gbogbo ipinlẹ̀ Nigeria si abẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ni  ọdún mọ́kàndinlãdọta sẹhin .  Lati igbà ti wọn ti kó ọrọ̀ ajé gbogbo ipinlẹ̀ si abẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ti a lè pè ni “Òbí” ti jinà si ará ilú ti a lè pè ni “Ọmọ” ti rù.  Ojúkòkòrò àti olè ji jà Ìjọba Ológun àti Òṣèlú lábẹ́ Ìjọba-àpapọ̀ ti fa ebi, òùngbẹ àti àìsàn fún ará ilú.

Ni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n sẹhin, Olóri Òsèlu tuntun Muhammadu Buhari àti àtẹ̀lé rẹ Túndé Ìdíàgbọn ṣe Ìjọba fún ogún oṣù gẹgẹ bi Ìjọba Ológun.  Nigbati wọn gba Ìjọba lọ́wọ́ àwọn Òṣèlú ti ó ba ilú jẹ́ pẹ̀lú iwà ìbàjẹ́ ti wọn fi kó ilú si igbèsè lábẹ́ Olóri Òṣèlú Shehu Shagari, wọn fi ìkánjú ṣe idájọ́ fún àwọn tó hu iwà ibàjẹ́, eleyi jẹ ki ilú ké pé Ìjọba wọn ti le jù.  Ká ni ilú farabalẹ̀ ni àsikò na a, ilú ki bá ti dára si.  Nigbati Olóri-ogun Badamasi Babangida gba Ìjọba, inú ilú dùn nitori àyè gba ará ilú lati ṣe bi wọn ti fẹ lati ri owó.  Eleyi jẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ olówó ojiji pọ̀ si lati igbà na a titi di oni.  Àyè àti ni owó ojiji nipa ifi owó epo-rọ̀bì ṣòfò, ki kó owó ìpèsè ohun amáyédẹrùn jẹ, gbi gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti iwà ìbàjẹ́, ló pa ilé-iwé giga, ilé-ìwòsàn, pàtàki ìpèsè iná-mọ̀nàmọ́ná, ìdájọ́ àti bẹ ẹ bẹ lọ.

A lè lo òwe “A ki i fi ọjọ́ kan bọ́ ọmọ tó rù” ṣe àlàyé pé iwà ìbàjẹ́ àti ohun tò bàjẹ́ fún ọdún pi pẹ́ kò ṣe tún ṣe ni ọjọ́ kan, nitori eyi, ki ará ilú ṣe sùúrù fún Ìjọba tuntun lati ṣe àtúnṣe lati ìbẹ̀rẹ̀.  Ki Ìjọba tuntun na a mọ̀ pé “Ori bi bẹ́, kọ́ ni oògùn ori fi fọ́”, nitori eyi ki wọn tẹ̀ lé òfin lati ṣe ìdájọ́ fún àwọn ti ó ba ilú jẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2016-01-12 10:09:45. Republished by Blog Post Promoter