Ìbẹ̀rù tó gbòde ayé òde òni ni pé “Ayé Móoru”, nitori iṣẹ̀lẹ̀ ti o nṣẹlẹ̀ ni àgbáyé bi òjò àrọ̀ irọ̀ dá ni ilú kan, ilẹ̀-riru ni òmìràn, ọ̀gbẹlẹ̀, omíyalé, ijà iná àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ. Eleyi dá ìbẹ̀rù silẹ̀ ni àgbáyé pàtàki ni àwọn ilú Òkè-Òkun bi Àmẹ́ríkà ti ó ka àwọn iṣẹ̀lẹ̀ wọnyi si àfọwọ́fà ọmọ ẹda. Wọn kilọ̀ pé bi wọn kò bá wá nkan ṣe si Ayé Móoru yi, ayé yio parẹ́.
Àpẹrẹ miran ti a lè fi ṣe àlàyé pé “Ọ̀run nyabọ̀, ki ṣé ọ̀rọ̀ ẹnìkan”, ni ẹni ti ó sọ pé ohun ri amin pé ayé ti fẹ parẹ́, àwọn kan gbàgbọ́, wọn bẹ̀rẹ̀ si ta ohun ìní wọn. Àti ẹni ti ó ta ohun ìní àti ẹni ti ó ra, kò si ninú wọn ti ó ma mú nkankan lọ ti ayé bá parẹ ni tootọ. Elòmíràn, kò ni ṣe iwadi ohun ti àwọn èniyàn fi ńsáré, ki ó tó bẹ̀rẹ̀ si sáré. Ọpọlọpọ ti sa wọ inú ewu ti wọn rò wí pé àwọn sá fún. Fún àpẹrẹ, nigbati iná ajónirun balẹ̀ ni àgọ́ Ológun ni Ikẹja ni ìlú Èkó ni bi ọdún mẹwa sẹhin. Bi àwọn kan ti gbọ́ ìró iná ajónirun yi, wọn sáré titi ọpọ fi parun si inú irà ni Ejigbo ni ọ̀nà jínjìn si ibi ti ìṣẹ̀lẹ̀ ti ṣẹlẹ̀.
Òwe Yorùbá yi ṣe gba àwọn ti o nbẹ̀rù nigba gbogbo níyànjú wí pé ó yẹ ki èniyàn fara balẹ̀ lati ṣe iwadi ohun ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀ ki ó tó “kú sílẹ̀ de ikú”. Bi èniyàn bẹ̀rù á kú, bi kò bẹ̀rù á kú, nitori gẹ́gẹ́ bi itàn àdáyébá, gbogbo ohun ti ó nṣẹlẹ̀ láyé òde òni ló ti ṣẹlẹ̀ ri.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2016-04-19 08:30:59. Republished by Blog Post Promoter