Tag Archives: Naming ceremony

“Ilé là ńwò ká tó sọmọ lórúkọ” – Orúkọ ẹni ni ìfihàn ẹni: One considers the circumstances of the home before naming a child – Your name is your identity

Ọpọlọpọ ọmọ Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ si tijú lati jẹ orúkọ ti òbí fi èdè Yorùbá sọ wọn.  Èyi tó bá tún gba lati jẹ orúkọ Yorùbá á tún bã jẹ ni kikọ tàbi ni pipè.  Èwo ni ká kọ “Bayọ ni Bayor, Fẹmi ni Phemmy, Tọlani ni Thorlani – kilo njẹ bẹ̃?  Nigbati ẹni to ni orúkọ bá nbajẹ bawo ni àjòji ṣe lè pe orúkọ na dada? Lẹhin ọdún pipẹ́ itumọ̀ orúkọ ti wọn ba jẹ yi a sọnù.

“Ẹni ti kò bámọ̀ itàn ara rẹ̀, wọn á pe lorúkọ ti ki ṣe tirẹ, á si dáhùn”.  Á gbọ́ ti igbà òwò burúkú “Òwò Ẹrú”, ti ilú tó lágbára ra àwọn enia bi ẹni ra ohun ini. Ni àsikò yi, bi wọn bà kó enia lẹ́rú, olówó rẹ á fun lórúkọ nitori ko ma ba ranti ibi ti ó ti ḿbọ̀.  Eleyi jẹ ki ó ṣòro fún ẹrú lati mọ ibi ti wọn ti wa lẹhin ti òwò ẹrú pari.  Ohun ribiribi ti ẹrú ṣe, kò hàn si àwọn ti ó kù ni ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú pé dúdú ti wọn kó lẹ́rú ló ṣẽ, nitori orúkọ ti ó yi padà.

Òwe Yorùbá ni “Ilé làńwò kátó sọmọ lórúkọ”. Ó ṣeni lãnu pé ọpọlọpọ ọmọ Yorùbá kò mọ iyi orúkọ wọn, nitori eyi fúnra wọn ni wọn pa orúkọ wọn da si orúkọ ti wọn kò mọ itumọ̀ rẹ.

Ẹ jọ̀wọ́, ẹ maṣe jẹ́ki ẹ̀yà àti èdè Yorùbá parẹ́. “Orúkọ ẹni ni ifihàn ẹni”, ao ni parẹ máyé o (Àṣẹ)

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-21 21:13:32. Republished by Blog Post Promoter

“Ilé làńwò ki a tó sọmọ lórúkọ – Orúkọ Yorùbá” – Home is examined before naming a child – Yoruba Names

Ni àṣà Yorùbá, ni ayé àtijọ́, ọjọ́ keje ni wọn ńsọmọ obinrin ni orúkọ, ọjọ́ kẹsan ni ti ọmọ ọkùnrin, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ọjọ kẹjọ ni wọn sọ gbogbo ọmọ lórú̀kọ.  Yorùbá ki sọmọ lórúkọ ni ọjọ́ ti wọn bi,ṣùgbọ́n Yorùbá ti ó bá bimọ si òkè-òkun lè fún ilé-igbẹbi lórúkọ ọmọ gẹgẹ bi àṣà òkè-òkun ki wọn tó sọmọ lórúkọ.

Òwe Yorùbá ni “Ilé làńwò, ki a tó sọmọ lórúkọ” nitori eyi, Bàbá àti Ìyá yio ronú orúkọ ti ó dara ti wọn yio sọ ọmọ ni ọjọ́ ikómọ.  Orúkọ Yorùbá lé ni ẹgbẹ-gbẹrun, àwọn orúkọ yi yio jade ni ipasẹ̀ akiyesi iṣẹ̀lẹ̀ ti o ṣẹlẹ̀ ni àsikò ti ọmọ wa ni ninú oyún; ọjọ́ ibi ọmọ; orúkọ ti ó bá idilé tabi ẹsin àtijọ́ àti ẹsin igbàlódé mu.

A o ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ igbalode àti àwọn orúkọ ibilẹ ti ó ti fẹ ma parẹ.  A o bẹrẹ pẹlu orukọ ti o wọpọ ni idile “Ọlá”, “Ọba”, “Olóyè” àti “Akinkanjú ni àwùjọ ni ayé òde òni.  “Ọlá” ninú orúkọ Yorùbá ki ṣe owó àti ohun ini nikan, Yorùbá ka “ilera” si  “Ọlà”. Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-07-01 20:03:09. Republished by Blog Post Promoter