Ilé-ìkàwé gẹ́gẹ́ bi orúkọ yi ti jẹ ni èdè Yorùbá, jẹ ibi ti wọn kó oriṣiriṣi iwé si, fún ọmọ ilé-iwé àti èrò lati wọlé yá iwé fún ki kà. Ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú ni Ilé-ìkàwé ti bẹ̀rẹ̀ ni Alexandria, Egypt. Ni ayé òde òni, ki ṣe iwé nikan ni wọn nkó si Ilé-ìkàwé, wọn a tún pèsè ẹ̀rọ ayélujára fún ẹni ti ó bá fẹ́ ka iwé lóri ayélujára àti lati wá idi ohun ti ó nlọ ni àgbáyé.
Ilé́-iwé kò pé lai si Ilé-ìkàwé. Ki ṣe ilé-iwé nikan ló ni Ilé-ìkàwé, nitori àdúgbò, agbègbè àti ilú na a ma nni Ilé-ìkàwé fún ọmọ ilé-iwé àti èrò ti ó ni ìfẹ́ lati ni ìmọ̀. Lati igbà ti Ìjọba-àpapọ̀ ti gba gbogbo ilé-iwé lọ́wọ́ àwọn Olùdásílẹ̀, ni ilé-iwé ti bàjẹ́ pàtàki àwọn ilé-iwé ti Ìjọba gba.
Yorùbá fẹ́ràn ẹni ti ó bá kàwé, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ìfẹ́ owó àti ìgbádùn ti dipò ìfẹ́ ẹ̀kọ́, nitori eyi Ilé-àpèjẹ pọ ni ilú ju Ilé-ìkàwé lọ. Eyi ti ó burú jù ni pé, kò si Ilé-ìkàwé tuntun, eyi ti ó wà kò ri àtúnṣe. Ìròyìn gbe jade pé, Ilé-iṣẹ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ti ṣe tán lati gbé Ilé-ìkàwé ti wọn kọ́ ni ọdún mẹwa sẹhin fún lilò ni ilé-iwé giga ti ó wà ni Àkokà, ilú Èkó, kúrò nitori wọn ti i pa lati ọdún marun lai lò. Eleyi yẹ kó ti ará ilú àti Òṣèlú lójú nitori, Ilé-ìkàwé ti wọn ti kọ́ ni ọgọrun ọdún sẹhin tàbi jù bẹ ẹ lọ ṣi wà ni Òkè-Òkun.
Ilú kò lè ni ìlọsíwájú lai si ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ nitori “Ìgbádùn tàbi Eré ṣi ṣe lai ṣi iṣẹ́, ló nfa Ìṣẹ́”.
ENGLISH TRANSLATION
Library as the name literarily suggested in Yoruba, is place where various kinds of books are kept, for Students and the public, where they can borrow books to read. The oldest Library started in Alexandria, Egypt in 300 BC. Nowadays, not only books are kept in the Library, Computers with internet are provided for those who want to read or carry out research on happenings around the world. Continue reading
Originally posted 2015-06-05 10:00:23. Republished by Blog Post Promoter