Ọkùnrin kan pẹ̀lú iyàwó púpọ̀ wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn obinrin ti ó bá́ fẹ́ ọkọ kan naa ni à ńpè ni “Orogún”. Ìwà oriṣiriṣi ni ó ma ńhàn ni ilé olórogún, àrù̀n iyàwó ti ó ńjalè, purọ́, ṣe àgbèrè, aláisàn, ti ó ńṣe òfófó, àti bẹ̃bẹ lọ, lè má hàn bi ó bá jẹ́ obinrin kan pẹ̀lú ọkọ rẹ ni ó ńgbe gẹ́gẹ́ bi ti ayé ode oni. Bi iyàwó bá ti pé meji, mẹta, bi àrù́n yi bá hàn si iyàwó keji, èébú dé, pataki ni àsikò ijà.
Ni ẹ̀sin ibilẹ̀, oye iyàwó ti ọkùnrin lè fẹ́, ko niye, pàtàki Ọba, Olóyè, Ọlọ́rọ̀ àti akikanjú ni àwùjọ. Bi àwọn ti ó ni ipò giga tabi òkìkí ni àwùjọ kò fẹ́ fẹ́ iyàwó púpọ̀, ará ilú á fi obinrin ta wọn lọ́rẹ. Ẹ̀sin igbàlódé pàtàki, ẹ̀sin igbàgbọ́ ti din àṣà ikó-binrin-jọ kù. Òfin ẹlẹ́sin igbàgbọ́ ni “ọkọ kan àti aya kan”. Bi o ti jẹ́ pé ẹ̀sin Musulumi gbà ki “Ọkùnrin lè fẹ́ iyàwó titi dé mẹrin”, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin Musulumi igbàlódé ńsá fún kikó iyàwó jọ.
Yorùbá ni “Òriṣà òkè jẹ́ ki npé meji obinrin kò dé nú”. Inú obinrin ti wọn fẹ́ iyàwó tẹ̀lé kò lè dùn dé inú, nitori eyi, kò lè fi gbogbo ọkàn rẹ tán ọkọ rẹ mọ, owú jijẹ á bẹ̀rẹ̀. Iyàwó kékeré lè dé ilé ri àbùkù ọkọ ti iyálé mú mọ́ra. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé oló-rogún kiki ijà àti ariwo laarin àwọn iyàwó àti àwọn ọmọ naa. Diẹ̀ ninú ọkùnrin ti ó fẹ́ iyàwó púpọ̀ ló ni igbádùn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin ti ó kó obinrin jọ ni ó ńsọ ẹ̀mi wọn nù ni ọjọ́ ai pẹ́ nitori ai ni ifọ̀kànbalẹ̀ àti àisàn ti bi bá obinrin púpọ̀ lò pọ̀ lè fà. Nitori eyi, ọkùnrin ti ó bá fẹ́ kó iyàwó jọ nilati múra gidigidi fun ohun ti ó ma gbẹ̀hìn àṣà yi.
ENGLISH LANGUAGE Continue reading
Originally posted 2014-06-10 18:00:13. Republished by Blog Post Promoter