Oriṣiriṣi ọ̀nà ni enia lè gbà dé àjò, ṣùgbọ́n eyi ti ó wọ́pò jù láyé òde òni ni lati wọ ọkọ̀ òfũrufú, bóyá lati lọ kọ́ ẹ̀kọ si, lati ṣe ìbẹ̀wò, lati lọ ṣiṣẹ́ tàbi lati lọ bá ẹbi gbé (fún àpẹrẹ: ìyàwó lọ bá ọkọ, ọkọ lọ bá ìyàwó, ìyá/bàbá lọ bá ọmọ tàbi ọmọ lọ bá bàbá). Gbogbo ọ̀nà yi ni Yorùbá ti lọ lati dé Ìlú-Ọba.
Àṣepọ̀ laarin ará Ìlú-Ọba àti Yorùbá ti lè ni ọgọrun ọdún, nitori eyi, kò si ibi ti enia dé ni Ìlú-Ọba ni pataki àwọn Olú-Ìlú, ti kò ri ẹni ti ó ńsọ èdè Yorùbá tàbi gbé irú ilú bẹ. A ṣe akiyesi pé lati bi ọdún mẹwa sẹhin, àṣepọ̀ laarin ọmọ Yorùbá ni Ìlú-Ọba din kù. Ni ìgbà kan ri, bi ọmọ Yorùbá bá ri ara, wọn a ki ara wọn.
Òwe Yorùbá ni “Ibi ti a ngbe la nse; bi a bá dé ìlú adẹ́tẹ̀ a di ìkúùkù”, àwọn ọ̀nà ti a lè fi ṣe ibi ti a ngbe: Ki ka ìwé nipa àṣà àti iṣẹ ìlú ti a nlọ ninu ìwé tàbi ṣe iwadi lori ayélujára; wiwa ibùgbé; lọ si Ilé-Ìjọ́sìn; Ọjà; Ọkọ̀ wiwọ̀ àti bẹ̃bẹ lọ.
Ẹ fi ojú sọ́nà fún àlàyé lori àwọn ọ̀nà ti enia lè lò lati tètè fi idi kalẹ̀ ni àjò.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2014-01-03 23:45:42. Republished by Blog Post Promoter