Tag Archives: marriage

“Àpọ́nlé kò si fún Ọba ti kò ni Olorì” – “There is no respect for a King that has no Queen”

Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Bi ọmọdé bá tó ni ọkọ́, à fún lọ́kọ́”.  Ọkọ́ jẹ irinṣẹ́ pàtàki fún Àgbẹ̀.  Iṣẹ́-àgbẹ̀ ni ó wọ́pọ̀ ni ayé àtijọ́. Nitori eyi, bi bàbá ti nkọ́ ọmọ rẹ ọkùnrin ni iṣẹ-àgbẹ̀, ni ìyá nkọ́ ọmọ obinrin rẹ ni ìtọ́jú-ile lati kọ fún ilé-ọkọ.  Iṣẹ́ la fi nmọ ọmọ ọkùnrin, nitori eyi, bi ọkùnrin bá dàgbà, bàbá rẹ á fun ni ọkọ́ nitori ki ó lè dá dúró lati lè ṣe iṣẹ́ ti yio fi bọ́ ẹbi rẹ ni ọjọ́ iwájú.

Bi ọkùnrin bá ni iṣẹ́, ó ku kó gbéyàwó ti yio jẹ “Olorì” ni ilé rẹ.  Ìyàwó fi fẹ́ bu iyi kún ọkùnrin, nitori, ó fi hàn pé ó ni igbẹ́kẹ̀lé.  Àṣà Yorùbá gbà fún ọkùnrin lati fẹ́ iye ìyàwó ti agbára rẹ bá gbé lati tọ́jú.  Nitori eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọba, Baálẹ̀, Ìjòyè àti àwọn enia pàtàki láwùjọ ma nfẹ ìyàwó púpọ̀.  Ìṣòro ni ki wọn fi ọkùnrin ti kò ni ìyàwó jẹ Ọba.  Kò wọ́pọ̀ ki Ọba ni ìyàwó kan ṣoṣo.

Ìwúyè Ọba Àkúrẹ́, Olóògbé Ọba Adebiyi Adeṣida - Coronation of the Late Deji of Akure.

Ìwúyè Ọba Àkúrẹ́, Olóògbé Ọba Adebiyi Adeṣida – Coronation of the Late Deji of Akure.

Ohun ti a ṣe akiyesi ni ayé òde òni, ni Ọba ti ó fẹ ìyàwó kan ṣoṣo nitori ẹ̀sìn, pàtàki ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n ti ó ni àlè rẹpẹtẹ.  Ọba ayé òde òni ndá nikan lọ si òde lai mú Olorì dáni.  Gẹgẹbi ọ̀rọ̀ Yorùbá, “Àpọ́nlé kò si fún Ọba ti kò ni Olorì”, nitori eyi, kò bu iyi kún Ọba, ki ó lọ àwùjó tàbi rin irin àjò pàtàki lai mú Olorì dáni.  Ohun ti ó yẹ Ọba ni ki a ri Ọba àti Olorì rẹ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ.

ENGLISH TRANSLATION

Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-11-11 19:13:42. Republished by Blog Post Promoter

Ìfẹ́ kò fọ́jú, ẹni ti ó wọnú ìfẹ́ ló fọ́jú: ‘Igbéyàwó ki ṣe ọjà òkùnkùn’ – Love is not blind, it is the person falling in love that is blind”: Marriage is not ‘Black Market’

Ni ayé àtijọ́, ki òbí tó gbà lati fi ọmọ fún ọkọ, wọn yio ṣe iwadi irú iwà àti àìsàn ti ó wọ́pọ̀ ni irú idile bẹ́ ẹ̀.  Nitori eyi, igbéyàwó ibilẹ̀ ayé  àtijọ́ ma npẹ́ ju ti ayé òde òni.  Bi ọmọ obinrin bá nlọ si ilé ọkọ, ikan ninu ẹrù tó ṣe pàtàki ni ki wọn gbé “ẹni” fún dáni lati fi han pé kò si àyè fun ni ilé òbi rẹ mọ nitori ó  ti di ara kan pẹ̀lú ẹbi ọkọ rẹ.

Ọkùnrin fi ìfẹ́ han obinrin - Couple in love

Ọkùnrin fi ìfẹ́ han obinrin – Couple in love

Ni idà keji, obinrin ayé òde òni, kò dúró ki òbí ṣe iwadi rara, pàtàki bi wọn bá pàdé ni ilú nla ti èrò lati oriṣiriṣi ẹ̀yà pọ̀ si tàbi ni ilé-iwé.  Ọkùnrin ri obinrin, wọn fi ìfẹ́ han si ara wọn, ó pari, ọ̀pọ̀ ki ṣe iwadi lati wo ohun ti àgbà tàbi òbí nwò ki wọn tó ṣe igbéyàwó.  Obinrin ti lè lóyún ki òbí tó gbọ́ tàbi ki wọn tó lọ si ilé Ìjọ́sìn lati ṣe ètò igbéyàwó.  Àwọn miran nkánjú, wọn kò lè dúró gba imọ̀ràn.  Irú imọ̀ràn wo ni òbí tàbi Alufa fẹ́ fún ọkùnrin àti obinrin bẹ́ ẹ̀?

 

Ki ṣe “ìfẹ́ ló fọ́jú”, ṣùgbọ́n “àwọn ti ó wọnú ìfẹ́ ló fọ́jú” nitori, bi obinrin tàbi ọkùnrin miran bá ti ri owó, ẹwà, ipò agbára, wọn á dijú si àlébù miran ti ó wà lára ẹni ti wọn fẹ́ fẹ́.   Igbéyàwó ki ṣe ọjà̀ òkùnkùn, ṣùgbọ́n àwọn ti ó nwọ̀ ọ́ ni ó dijú, nitori nigbati àlébù ti wọn dijú si bá bẹ̀rẹ̀ si jade lẹhin igbéyàwó, igbéyàwó á túká.

Ki ṣe “ìfẹ́ ló fọ́jú”, ṣùgbọ́n “àwọn ti ó wọnú ìfẹ́ ló fọ́jú” nitori, bi obinrin tàbi ọkùnrin miran bá ti ri owó, ẹwà, ipò agbára, wọn á dijú si àlébù miran ti ó wà lára ẹni ti wọn fẹ́ fẹ́.   Igbéyàwó ki ṣe ọjà̀ òkùnkùn, ṣùgbọ́n àwọn ti ó nwọ̀ ọ́ ni ó dijú, nitori nigbati àlébù ti wọn dijú si bá bẹ̀rẹ̀ si jade lẹhin igbéyàwó, igbéyàwó á túká.

Ìmọ̀ràn fún ọkùnrin àti obinrin ti ó nronú lati ṣe igbéyàwó ni ki wọn lajú, ki wọn si farabalẹ̀ ṣe iwadi irú iwa ti wọn lè gbà lati fi bára gbé lai wo ohun ayé bi ẹwà, owó àti ipò nitori ìwà ló ṣe kókó jù fún igbéyàwó ti yio di alẹ́.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-01-06 09:00:19. Republished by Blog Post Promoter

Ẹ bá wa gbé ọ̀rọ̀ yi yẹ̀wò. Àwọn Ilé Ìdájọ́ Àgbà ni ìlú Amerika ṣe ìdájọ wípé “ìgbéyàwó ko di dandan kó jẹ́ laarin ọkùnrin àti obinrin” : US Supreme Court Decides Marriage Does not Have to be Man & Woman

Two men rejoicing

A gay couple rejoicing over the repeal of the Defense of Marriage Act — June 26, 2013. Image is from AP/BBC

Ẹ bá wa gbé ọ̀rọ̀ yi yẹ̀wò. Àwọn Ilé Ìdájọ́ Àgbà ni ìlú Amerika ṣe ìdájọ wípé “ìgbéyàwó ko di dandan kó jẹ́ laarin ọkùnrin àti obinrin”. Bi wọn ti s’alaiye oro na si, wọn ni kò dára ki àwọn Aṣòfin ti a mọ si “Congress”, sọ wípé “ìgbéyàwó lati jẹ́ laarin ọkùnrin àti obìnrin ni kan ṣoṣo”. Àkíyèsí ti wọn ṣe ni wípé, ìdí ti àwọn Aṣòfin ṣe sọ bẹ̃, ni pé wọn o fẹ́ràn àwọn ti o nṣe igbeyawo ọkùnrin si ọkùnrin tabi obìnrin si obìnrin.

Ẹ jẹ́ ki a yẹ ọ̀rọ̀ yi wo bó yá a fẹ́ràn ẹ, tàbi a o fẹ́ràn ẹ, ṣe àṣà àdáyébá Yorùbá kankan wa, bi òwe tàbí nkan bẹ̃, ti ó sọ ìdí ti a ṣe n fun àwọn ti ó bá ṣe ìgbéyàwó ni ọpọlọpọ ẹ̀tọ́ ti a n fun wọn?

Ẹ jọ̀wọ́, ẹyin ará Yoruba blog, ẹ bá wa da si. Ẹ sọ ìdí ti aṣe n fun àwọn ti ó bá ṣe ìgbéyàwó ni oriṣiriṣi ẹ̀tọ́, ẹ̀bùn lọ́jọ́, ìgbéyàwó àti àyẹ́sí fún àwọn tó bá wà ni ilé ọkọ.

Ìdájọ́ yi ṣe pàtàkì, bi o ti ẹ jẹ wípé Amerika lo yi òfin padà pe ìgbéyàwó ki ṣe laarin ọkùnrin àti obìnrin mọ́ lọ́jọ́ òní, ni ọjọ́ kan, Yorùbá, orílẹ̀ èdè Nigeria àti gbogbo ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú yio ṣe ipinu ọ̀rọ̀ yi.

 

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-06-28 15:27:02. Republished by Blog Post Promoter