Tag Archives: Many wives

“Ni Ayé òde òni, njẹ́ ó yẹ ki a pọ́n Àṣà fi fẹ́ Iyàwó púpọ̀ lé ni Igbéyàwó Ìbílẹ̀ Yorùbá?” – “In Modern times, should Polygamy be encouraged in Yoruba Traditional Marriage?”

Ni igbà àtijọ́, oníyàwó kan kò wọ́pọ̀ nitori iṣẹ́ Àgbẹ̀.  Àṣà fi fẹ́ iyàwó púpọ̀ ṣe kókó nitori bibi ọmọ púpọ̀ pàtàki ọmọ ọkùnrin fún irànlọ́wọ́ iṣẹ́-oko.  Fi fẹ̀ iyàwó púpọ̀ kò pin si ilẹ̀ Yorùbá tàbi ilẹ̀ Aláwọ̀dúdú nikan, ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Aláwọ̀funfun ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹhin ṣùgbọ́n nitori òwò ẹrú àti ẹ̀sin igbàgbọ́ wọn bẹ̀rẹ̀ àṣà fi fẹ iyàwó kan.  Lẹhin òwò ẹrú, li lo ẹ̀rọ igbàlódé fún iṣẹ́ oko jẹ ki Aláwọ̀funfun lè dúró pẹ̀lú àṣà fi fẹ́ iyàwó kan.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ ayé òde òni ti kọ àṣà fi fẹ́ iyàwó púpọ̀ silẹ̀ nitori ẹ̀sìn, ìmọ̀ àti si sá fún rògbòdiyàn ti ó lọ pẹ̀lú iyàwó púpọ̀.  Iṣẹ́ Alákọ̀wé kò ṣe fi jogún fún ọmọ nitori iwé-ẹ̀ri àti ipò ti èniyàn dé ni iṣẹ́ Akọ̀wé tàbi iṣẹ́ Ìjọba kò ṣe fi jogún fún ọmọ bi oko.  Owó ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Oniṣẹ́-oṣ̀u ngba kò tó lati bọ́ iyàwó kan ki owó oṣù míràn tó wọlé, bẹni kò tó gba ilé nla ti ó lè gba iyàwó púpọ̀ pàtàki ni ilú nla bi Èkó.  Àṣà iyàwó púpọ̀ ṣi pọ̀, ni àwọn ilú kékeré tàbi Abúlé laarin àwọn àgbẹ̀ àti àwọn ti kò kàwé.

Ọmọ Oníyàwó púpọ̀ – Many children of a PolygamistYorùbá ni “Bàbá, bàbá gbogbo ayé”, bi iyàwó kò bá ni iṣẹ́ lati tọ́jú ọmọ wọn, ìṣẹ́ dé, nitori eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ obinrin Yorùbá ma ntẹpá mọ́ṣẹ́ lati lè tọ́jú ọmọ wọn lai dúró de ọkọ.  Ìyà àti ìṣẹ́ ni fún ọmọ púpọ̀ àti àwon iyàwó ọkùnrin ti kò ni iṣẹ́ tàbi eyi ti ó ni iṣẹ́ ti kò wúlò.

Ewu ti ó wà ni ilé oníyàwó  púpọ̀ ju ire ibẹ̀ lọ.  Yorùbá ni “Oníyàwó kan kò mọ ẹjọ́ oníyàwó  púpọ̀ da a”.  Lára ewu wọnyi ni, ki i si ifọ̀kànbalẹ̀ nitori ijà àti ariwo ti owú ji jẹ laarin àwọn iyàwó ma nfà pàtàki ni agbo ilé nlá tàbi ilé Ọlọ́rọ̀ àti Olóyè.  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé oníyàwó  púpọ̀ ma nda ahoro lẹhin ikú Olóri ilé nitori kò si ẹni ti ó ni ìfẹ́ tọ si Bàbá oníyàwó  púpọ̀.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-07-24 22:19:43. Republished by Blog Post Promoter