Ni ayé àtijọ́, ki òbí tó gbà lati fi ọmọ fún ọkọ, wọn yio ṣe iwadi irú iwà àti àìsàn ti ó wọ́pọ̀ ni irú idile bẹ́ ẹ̀. Nitori eyi, igbéyàwó ibilẹ̀ ayé àtijọ́ ma npẹ́ ju ti ayé òde òni. Bi ọmọ obinrin bá nlọ si ilé ọkọ, ikan ninu ẹrù tó ṣe pàtàki ni ki wọn gbé “ẹni” fún dáni lati fi han pé kò si àyè fun ni ilé òbi rẹ mọ nitori ó ti di ara kan pẹ̀lú ẹbi ọkọ rẹ.
Ni idà keji, obinrin ayé òde òni, kò dúró ki òbí ṣe iwadi rara, pàtàki bi wọn bá pàdé ni ilú nla ti èrò lati oriṣiriṣi ẹ̀yà pọ̀ si tàbi ni ilé-iwé. Ọkùnrin ri obinrin, wọn fi ìfẹ́ han si ara wọn, ó pari, ọ̀pọ̀ ki ṣe iwadi lati wo ohun ti àgbà tàbi òbí nwò ki wọn tó ṣe igbéyàwó. Obinrin ti lè lóyún ki òbí tó gbọ́ tàbi ki wọn tó lọ si ilé Ìjọ́sìn lati ṣe ètò igbéyàwó. Àwọn miran nkánjú, wọn kò lè dúró gba imọ̀ràn. Irú imọ̀ràn wo ni òbí tàbi Alufa fẹ́ fún ọkùnrin àti obinrin bẹ́ ẹ̀?
Ki ṣe “ìfẹ́ ló fọ́jú”, ṣùgbọ́n “àwọn ti ó wọnú ìfẹ́ ló fọ́jú” nitori, bi obinrin tàbi ọkùnrin miran bá ti ri owó, ẹwà, ipò agbára, wọn á dijú si àlébù miran ti ó wà lára ẹni ti wọn fẹ́ fẹ́. Igbéyàwó ki ṣe ọjà̀ òkùnkùn, ṣùgbọ́n àwọn ti ó nwọ̀ ọ́ ni ó dijú, nitori nigbati àlébù ti wọn dijú si bá bẹ̀rẹ̀ si jade lẹhin igbéyàwó, igbéyàwó á túká.

Ìmọ̀ràn fún ọkùnrin àti obinrin ti ó nronú lati ṣe igbéyàwó ni ki wọn lajú, ki wọn si farabalẹ̀ ṣe iwadi irú iwa ti wọn lè gbà lati fi bára gbé lai wo ohun ayé bi ẹwà, owó àti ipò nitori ìwà ló ṣe kókó jù fún igbéyàwó ti yio di alẹ́.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2015-01-06 09:00:19. Republished by Blog Post Promoter