Tag Archives: London

ẸGBẸ́́ YORÙBÁ NÍ ÌLÚỌBA: Finding Yoruba Food in the UK (Dalston Kingsland)

Yorùbá ní “Bí ewé bá pẹ́ lára ọṣẹ, á dọṣẹ”,ọ̀rọ̀ yí bá ẹgbẹ́ Yorùbá ni Ìlúọba mu pàtàkì àwọn ti o ngbe ni Olú Ìlúọba.  Títí di bi ọgbọ̀n ọdún sẹhin, àti rí oúnjẹ Yorùbá rà ṣọ̀wọ́n.  Ní àpẹrẹ, àti ri adìẹ tó gbó rà lásìkò yi, à fi tí irú ẹni bẹ̃ bá lọ si òpópó Liverpool,  ṣùgbọ́n ní ayé òde òni, kòsí agbègbè ti ènìà kò ti lè rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Yorùbá ra.

Lati bi ogún ọdún sẹ́hin, Yorùbá ti pọ̀si nidi àtẹ oúnjẹ títà ni Olú Ìlúọba.  Nitõtọ, oúnjẹ Yorùbá bi iṣu, epo pupa, èlùbọ́, gãri, ẹ̀wà pupa, sèmó, iyán, ẹran, adìẹ tógbó, ẹja àti bẹ̃bẹ wa ni àrọ́wọ́to lãdugbo.  Ṣùgbọ́n, bí ènìà bá fẹ́ àwọn nkan bí ìgbín, panla, oriṣiriṣi ẹ̀fọ́ ìbílẹ̀, bọkọtọ̃, edé gbígbẹ àti bẹ̃bẹ lọ tí kòsí lãdugbo, á rí àwọn nkan wọnyi ra ni ọjà Dalston àti Kingsland fún àwọn ti o ngbe agbègbè Àríwá àti ọja Pekham fún àwọn ti o ngbe ni agbègbè Gũsu ni Olú Ìlúọba.

Àwòrán àwọn ọjà wọnyi a bẹrẹ pẹ̀lú, Ọja Dalston àti Kingsland.  Ẹ fojú sọ́nà fún àwọn ọja yókù.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2013-04-05 21:06:49. Republished by Blog Post Promoter

Àjọ̀dún Iṣẹ́-Ọnà Yorùbá ni London: Yoruba Art Festival London

Ni ọjọ Àbámẹ́ta àti ọjọ Àìkú oṣù keje, ọjọ́ kẹtadinlọgbọn àti ọjọ kejidinlọgbọn ọdun ẹgbã̃-le-mẹtala, wọn ṣe àjọ̀dún kẹrin Iṣẹ́-ọnà ilẹ Yorùbá, ni pápá Clissod, ni ìlú London.

Gẹgẹbi òwe Yorùbá “Ẹni ti ó ni ki ará ilé ohun má là, ará ìta ni o ya láṣọ”.  Òwe yi là le fi ba awọn èyaǹ wa wi, nitori bi Òyìnbó bá bẹ̀rẹ̀ si ṣe irú àjọ̀dún yi, awọn enia wa a tò pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ lati gba àyè lati fi iṣẹ́ ọnà àti àṣà Yorùbá ni irú ibi bẹ̃.  Bi èrò ìwòran ti ó fẹ́ mọ nipa iṣẹ́ ọ̀na Yorùbá ti pọ̀ tó, kòsí oníṣẹ́ ọnà bi: onilù, olórin ìbìlẹ́, oníṣòwò ọjà ìbílẹ̀ àti bẹ̃bẹ̃ lọ lati polówó iṣẹ́ ọnà àti àṣà Yorùbá ni àjọ̀dún yi.

Awọn ẹ̀ka Yorùbá ti ó wà ni Brazil ló kó onílù àti oníjò “Batala” ti ó dá awọn èrò lára ya.́  Awon olonje Yoruba ri oja ta.   Awọn onilù, oníṣòwò ibile, olórin ibile, oniṣẹ ọna ati eléré ìbílẹ̀ Yorùbá ni ìlú-ọba pàdánù àti jẹ ọrọ̀ àti polongo iṣẹ ọwọ́ wọn.

Ó ṣe pàtàkì lati parapọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ lati gbé àṣà, iṣẹ́ ọnà àti èdè Yorùbá lárugẹ.

ENGLISH LANGUAGE

On Saturday and Sunday July 27 and 28, 2013 Yoruba Art Festival was held in Clissold Park in London.

According to Yoruba adage literally translates to “Anyone that says his kinsman should not be rich would rely on outsider to borrow clothes”.  This adage can be applied to the low patronage by the Yoruba budding artists and cultural groups in the United Kingdom.  It is observed that if this event had been organized by foreigners, our people would have queued to beg for a spot to display their culture.  Many of the audience/crowd were disappointed at not seeing Yoruba Artist and other Cultural display at the event.

However, the branch of Yoruba at Brazil “Batala Dance and Drum Group” gave a good performance to entertain the crowd.  The Yoruba food Vendors made brisk business.  The Yoruba indigenous Drummers, Artists, Entertainment Group, Dancers etc. lost the opportunity to show case and advertise their skills.

It is important to join hand with love to promote Yoruba Culture, Art and Language.

Share Button

Ọmọ tóda ni ti Bàbá ṣùgbọ́n burúkú ni ti Ìyá”: A Good Child is the Father’s but a Bad One is the Mother’s #Woolwich #Adebolajo

Ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tó ṣẹ́lẹ̀ ni ọ̀sán gangan, Ọjọ Kẹta Oṣù Karun ọdún Ẹgbẹrunmejilemẹtala ni Woolwich, Olú Ìlúọba jẹ apẹrẹ fún òwe Yorùbá tó wípé “Ọmọ tóda ni ti Bàbá ṣùgbọ́n burúkú ni ti Ìyá”.  Ẹ̀kọ́ ti a le ri lo ninu òwe yi nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ yi ni ka kìlọ̀ fún onínú fùfù kó ṣọ́ra, ìbínú burúkú ni ìdí ti àwọn ọ̀dọ́mọ̀kunrin meji fi pa Jagunjagun ni Woolwich.

Gẹ́gẹ́bí ẹniti o ti gbé Peckham fún ọdún melo kan sẹhin, a ṣe àkíyèsí pe àwọn ọ̀dọmọ̀kunrin tó ni ìdíwọ́ ma jáde pẹ̀lú ọ̀be lati ya ẹni tó nlọ ni ìgboro Gũsu, Olú Ìlúọba, lọbẹ laiṣẹ.  Ibã jẹ nípa àwáwí lati digun jalè tàbí gba ẹ̀sìn sódì, kò si àwáwí tó tọ̀nà lati pa ẹnìkejì.  Ohun tó dára lati ṣe ni ki a pa ẹnu pọ̀ lati sọ wípé “ohun ti kó da, ko da’’.

Michael Adebọlajọ ti di ọmọ ìyá̀ rẹ – Nigeria, kò yani lẹ́nu wípé Bàbá rẹ̀ London kọ silẹ̀.  Ó pani lẹrin wípé ọmọkùnrin yi ti ka ara rẹ kun ẹbi Palestine, Iraq ati Afghansistan nigbàti a o le da ẹ̀bi fún Ìjọba Ìlúọba fún ikú obinrin ati ọmọ wẹ́wẹ́ to nṣẹlẹ ni Nigeria.

English Translation: Continue reading

Share Button

NÍNÍ OWÓ BABA ÀFOJÚDI, ÀÌNÍ OWÓ BABA ÌJAYÀ: Abundance of Money is the Father of Insolence and Lack of Money the Father of Panic

Welfare System Reforms -- BBC

BBC article on benefit cuts, aini owo baba ijaya.

Ọ̀rọ̀ Yorùbá yi ba ìjọba Ìlúọba àti àwọn ará ìlú wi. Ìjọba njaya nítorí owó ti o nwọle kò kárí owó lati ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀tọ́ ti àwọn ará ìlú nri gbà.  Àwọn ti o si ngba ẹ̀tọ́ lọ́dọ̀ ìjọba njaya nítorí, ẹ̀tọ́ ti Ìjọba ndiku yio mu ìnira bá wọn nítorí ẹ̀dín owó yi bọ́sí àsìkò ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ àti ohun ìtura míràn.

Gẹ́gẹ́bí ilé iṣẹ́ amóhùn máwòran Ìlúọba ti ròyìn, lati Oṣù kẹrin, ọjọ́ kini, ọdún ẹgbẹ̀rúnmẽjilemẹtala, Ìjọba Ìlúọba bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtúnṣe lati dín gbèsè ti ìlú jẹ ku; gbígba àwọn òṣìṣẹ́ ni ìyànjú ki wọn tẹra mọ́ṣẹ àti ki àwọn ti ko ṣiṣẹ́ le padà si ẹnu iṣẹ́.  Díẹ̀ nínú àwọn àtúnṣe yi ni: ìdérí owó ìrànlọ́wọ́ si poun mẹrindinlọgbọn lọ́dún fún ìdílé; yíyọ owó fún yàrá tó ṣófo; àtúnṣe fún Ilé Ìwòsàn lapapọ àti bẹ̃bẹ lọ.

Yorùbá ni “Kòsọ́gbọ́n tí o lèda, kòsíwà tí o lèhù  tí o lè  fi tẹ ayé lórùn”,  bí ọ̀pọ̀ ti nyin ìjọba bẹ̃ni ọ̀pọ̀ mbu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu àtúnṣe wọnyi wípé Ìjọba ngba lọ́wọ́ aláìní fún àwọn tóní.

ENGLISH TRANSLATION >>> Continue reading

Share Button