Tag Archives: Leopard

Ìtàn àròsọ bi obinrin ti sọ Àmọ̀tékùn di alábàwọ́n: The Folklore on how a woman turned the Leopard to a spotted animal.

Ni igba kan ri, Àmọ̀tékùn ni àwọ̀ dúdú ti ó jọ̀lọ̀, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ kan, Àmọ̀tékùn wá oúnjẹ õjọ́ rẹ lọ.  Ó dé ahéré kan, ó ṣe akiyesi pe obinrin kan ńwẹ̀, inú rẹ dùn púpọ̀ pé òhún ti ri oúnje.  O lúgọ de asiko ti yi o ri àyè pa obinrin yi fún oúnjẹ.

Yorùbá ni “Ọ̀pá tó wà lọ́wọ́ ẹni la fi npa ejò”.  Nigbati obinrin yi ri Àmọ̀tékùn, pẹ̀lú ìbẹ̀rù, ó fi igbe ta, ó ju kàrìnkàn ti ó fi ńwẹ̀ pẹ̀lú ọṣẹ híhó inú rẹ lù.  Àmọ̀tékùn fi eré si ṣùgbọ́n, gbogbo ọṣẹ ti ó wà ninu kànrìnkàn ti ta àbàwọ́n si ara rẹ lati ori dé ẹsẹ̀ rẹ, eleyi ló sọ Àmọ̀tékùn di alámì tó-tò-tó lára titi di ọjọ́ oni.  (Ẹ ka itàn àròsọ yi ninu iwé ti M.I. Ogumefu kọ ni èdè Gẹ̀ẹ́si).

Yorùbá ma nlo àwọn àròsọ itàn wọnyi lati kọ́ àwọn ọmọdé ni ẹ̀kọ́.  Yorùbá ni “Ẹni ti ó bá dákẹ́, ti ara rẹ á ba dákẹ́”, nitori eyi ẹ̀kọ́ pàtàki ti a ri ninu itàn àròsọ yi ni pé, kò yẹ ki enia fi ìbẹ̀rù dúró lai ṣe nkankan ti ewu bá dojú kọni ṣùgbọ́n ki á lo ohun kóhun ti ó bá wà ni àrọ́wótó lati fi gbèjà ara ẹni.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2014-01-31 18:08:54. Republished by Blog Post Promoter

“Ìtàn bi Ìjàpá ti fa Àkóbá fún Ọ̀bọ: Ẹ Ṣọ́ra fún Ọ̀rẹ́ Burúkú” – “The Story of how the Tortoise caused the Monkey an unprovoked trouble: Be careful with a bad Friend”

Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ itàn Yorùbá, Ìjàpá jẹ ọ̀lẹ, òbùrẹ́wà, kò tóbi tó àwọn ẹranko yoku, ṣùgbọ́n ó ni ọgbọ́n àrékérekè ti ó fi ngbé ilé ayé.

Ò̀we Yorùbá sọ wi pé, “Iwà jọ iwà, ni ọ̀rẹ́ jọ ọ̀rẹ́”, ṣùgbọ́n ninú itàn yi, iwà Ìjàpá àti Ọ̀bọ kò jọra.  Ìjàpá  pẹ̀lú Ọ̀bọ di ọ̀rẹ́ nitori wọn jọ ngbé àdúgbò.  Gbogbo ẹranko yoku mọ̀ wi pé iwà wọn kò jọra nitori eyi, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wọn irú ọ̀rẹ́ ti wọn bára ṣe.

Ọgbọ́n burúkú kó wọn Ìjàpá, ni ọjọ́ kan ó bẹ̀rẹ̀ si ṣe àdúrà lojiji pé “Àkóbá , àdábá, Ọlọrun ma jẹ ká ri”, Ọ̀bọ kò ṣe “Àmin àdúrà” nitori ó mọ̀ wi pé kò si ẹni ti ó lè ṣe àkóbá fún Ìjàpá, à fi ti ó bá ṣe àkóbá fún elòmiràn.  Inú bi Ìjàpá, ó ka iwà Ọ̀bọ yi si à ri fin, ó pinu lati kọ lọ́gbọ́n pé ọgbọ́n wa ninú ki enia mã ṣe “Àmin” si àdúrà àwọn àgbà.

Ìjàpá ṣe àkàrà ti ó fi oyin din, o di sinú ewé, ó gbe tọ Ẹkùn lọ.  Ki Ẹkùn tó bèrè ohun ti Ìjàpá nwa lo ti gbo oorun didun ohun ti Ìjàpá Ijapa gbe wa.  Ìjàpá jẹ́ ki Ẹkùn játọ́ titi kó tó fún ni àkàrà olóyin jẹ. Àkàrà olóyin dùn mọ́ Ẹkùn, ó ṣe iwadi bi òhun ti lè tún ri irú rẹ.  Ìjàpá ni àṣiri ni pé Ọ̀bọ ma nṣu di dùn, lára igbẹ́ rẹ ni òhun bù wá fún Ẹkùn.  Ó ni ki Ẹkùn fi ọgbọ́n tan Ọ̀bọ, ki ó si gba ni ikùn diẹ ki ó lè ṣu igbẹ́ aládùn fun.  Ẹkùn kò kọ́kọ́ gbàgbọ́, ó ni ọjọ́ ti òhun ti njẹ ẹran oriṣiriṣi, kò si ẹranko ti inú rẹ dùn bi eyi ti Ìjàpá gbé wá.  Ìjàpá ni ọ̀rẹ òhun kò fẹ́ ki ẹni kan mọ àṣiri yi.  Ẹkùn gbàgbọ́, nitori ó mọ̀ wi pé ọ̀rẹ́ gidi ni Ìjàpá àti Ọ̀bọ.

Ẹkùn gba ikùn Ọ̀bọ - Leopard dealt the Monkey blows.

Ẹkùn gba ikùn Ọ̀bọ – Leopard dealt the Monkey blows.

Ẹkùn lúgọ de Ọ̀bọ, ó fi ọgbọ́n tan ki ó lè sún mọ́ òhun.  Gẹ́rẹ́ ti Ọ̀bọ sún mọ́ Ẹkùn, o fã lati gba ikùn rẹ gẹ́gẹ́ bi Ìjàpá ti sọ, ki ó lè ṣu di dùn fún òhun.  Ó gbá ikun Ọ̀bọ titi ó fi ya igbẹ́ gbi gbóná ki ó tó tu silẹ̀.  Gẹ́rẹ́ ti Ẹkùn tu Ọ̀bọ silẹ̀, ó lo agbára diẹ ti ó kù lati sáré gun ori igi lọ lati gba ara lowo iku ojiji.  Ẹkùn tọ́ igbẹ́ Ọ̀bọ wò, inú rẹ bàjẹ́, ojú ti i pé òhun gba ọ̀rọ̀ Ìjàpá gbọ.  Lai pẹ, Ìjàpá ni Ọ̀bọ kọ́kọ́ ri, ó ṣe àlàyé fún ọ̀rẹ́ rẹ ohun ti ojú rẹ ri lọ́wọ́ Ẹkùn lai funra pé Ìjàpá ló fa àkóbá yi fún òhun.  Ìjàpá ṣe ojú àánú, ṣùgbọ́n ó padà ṣe àdúrà ti ó gbà ni ọjọ́ ti Obo kò ṣe “Amin”, pé ọgbọ́n wà ninú ki èniyàn mã ṣe “Àmin” si àdúrà àwọn àgbà.  Kia ni Ọ̀bọ bẹ̀rẹ̀ si ṣe “Àmin” lai dúró.  Idi ni yi ti Ọ̀bọ fi bẹ̀rẹ̀ si kólòlò ti ó ndún bi “Àmin” titi di ọjọ́ òni.

Ẹ̀kọ́ itàn yi ni pé, bi èniyàn bá mbá ọ̀rẹ́ ọlọ́gbọ́n burúkú rin, ki ó mã funra tàbi ki ó yẹra, ki o ma ba ri àkóbá.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-16 22:39:59. Republished by Blog Post Promoter