(Olóògbé Ọ̀jọ̀gbọ́n Olikoye Ransome Kuti – Oníṣègùn-Ọmọdé ti gbogbo àgbáyé mọ̀, Òjíṣẹ́-Òṣèlú Nigeria ni ọdún keji-din-lọ́gbọ̀n si ọdún keji-lé-lógún sẹhin, ṣe irànlọ́wọ́ gidigidi nipa di-din “Ikú ọmọdé kù” nipa ẹ̀kọ́-ìlàjú fún gbogbo ilú àti abúlé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ni, ìlàjú lóri ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán àti ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-mágbèsi gbàlà lọ́wọ́ ikú igbẹ́-gburu, nipa ìmọ̀ “Omi Oni-yọ lati dipò omi ara”.
Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ bi Àbíkú ti din-ku ni orilẹ̀ èdè Nigeria, nitori eyi orúkọ Àbíkú din-kù:
Ikú ọmọ ti kò ti pé ọdún marun ni ọdún mẹrin-lé-lógún sẹhin jẹ́ Igba-lé-mẹ́tàlá
Ikú ọmọ ti kò ti pé ọdún marun ni ọdún keji sẹhin ti din-kù si Mẹrin-lé-lọgọfa.
ENGLISH TRANSLATION
An Internationally acclaimed Paediatrician, Late Professor Olikoye Ransome-Kuti – Nigeria’s Minister of Health 1986 to 1992 contributed greatly to the reduction of Child Mortality in Nigeria through his Television/Radio Enlightenment Programme as well as promotion of Rural Health Education. Many children were saved from death through diarrhoea through his Television and Radio Enlightenment Programme on “Oral Dehydration Therapy – ORT”.
Check out example of how Child Mortality has reduced in Nigeria, hence names associated with Child Mortality has reduced. According to UNICEF statistics:
Under 5 Mortality Rate (U5MR) 1990 – 213
Under 5 Mortality Rate (U5MR) 2012 – 124
Orúkọ Yorùbá fú́n Àbíkú – Yoruba Name associated with child-mortality
|
Igé Kúrú Orúkọ Àbíkú – Short form of Name associated with child-mortality
|
Itumọ – Meaning in English |
Gbókọ̀yi | Kọyi | The forest rejected this |
Kòkúmọ́ | Kòkú | Not dying again |
Malọmọ | Malọ | Do not go again |
Igbẹkọyi | Kọyi | The dungeon rejected this |
Akisatan | No more rags (worn out clothes or rags were used as diapers) | |
Kòsọ́kọ́ | No hoe (e.g. hoe is synonymous with any instrument used in digging the grave i.e. Digger, Shovel, etc | |
Ọkọ́ya | The hoe is broken (i.e. hoe is synonymous with any digging instruments) | |
Ẹkúndayọ̀ | Dayọ̀ | Weeping has turned to joy |
Rẹ̀milẹ́kún | Rẹmi | Pacify me from weeping |
Ògúnrẹ̀milẹ́kún | Rẹ̀milẹ́kún | The god of iron (Ogun) has pacified me from weeping |
Olúwarẹ̀milẹ́kún | Rẹ̀mi/Rẹ̀milẹ́kún | God has pacified me from weeping |
Bámitálẹ́ | Tálẹ́ | Remain with me till the evening/end |
Fadaisi/Fadayisi | Daisi/Dayisi | “Ifa” has spared this |
Ogundaisi/Ogundayisi | Daisi/Dayisi | “Ogun” has spared this |
Mátànmijẹ | Mátànmi | Don’t deceive me |
Jokotimi | Joko | Seat with me |
Dúrójayé | Dúró/Jayé | Stay to enjoy the world |
Dúró́sinmi | Dúró/Sinmi | Stay to bury me (Me here means the plea from the child’s parent) |
Dúróorikẹ | Rikẹ | Stay to bury me (Me here means the plea from the child’s parent) |
Dúrótimi | Rotimi | Stay with me |
Bámidúró | Dúró | Stand with me |
Jokotọla | Joko/Tọla | Seat with wealth |
Adérọ́pò | Rọ́pò | He/she who came to replace |
Olúwafirọ́pò | Rọ́pò/Firọ́pò | God’s replacement |
Dúródọlá | Dúró/Dọlá | Wait for wealth |
Kilanko | Lanko | What are we naming |
Ajá | Dog | |
Ẹnilọlóbọ̀ | Ẹnilọ | He/she who left has returned |
Dúrójogún | Dúró/Jogún | Live/Stay to inherit. |
Originally posted 2014-09-23 09:01:44. Republished by Blog Post Promoter