Ni asiko ọdún, pataki, asiko ọdún iranti ọjọ ibi Jesu, bi oúnjẹ ti pọ̀ tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti o wa ni Òkè-okun àti àwọn díẹ̀ ni ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, bẹ̃ ni o ṣọ̀wọ́n tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àgbáyé.
Ò̀we Yorùbá ni, “Ọ̀kánjúwà-á bu òkèlè, ojú rẹ à lami”. Bi enia ò bá ni ọ̀kánjúwà, á mọ irú òkèlè ti ó lè gba ọ̀nà ọ̀fun rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀kánjúwa á bu lai ronu pe òkèlè ti ó ju ọ̀nà ọ̀fun lọ á fa ẹkún. Òwe yi bá àwọn ti ó ṣe jura wọn lọ tàbi ki ó jẹ igbèsè lati ra ẹ̀bùn, oúnjẹ ti wọn ò ni jẹ tán, aṣọ, bàtà àti oriṣiriṣi ti wọn ri ni ìpolówó lai mọ̀ pé ọdún á ré kọjá. Lẹhin ọdún, ọ̀pọ̀ a fi igbèsè bẹ̀rẹ̀ ọdún titun, eyi a fa ìrora àti ọ̀rọ̀ ti ó ṣòro si ayé irú ẹni bẹ̃.
Yorùbá ni “Ájẹ ìwẹ̀hìn ló ba Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ”, nitori eyi ìkìlọ̀ fún ẹ̀yin ti ẹ ni ìfẹ́ àti gbé èdè àti àṣà̀̀ Yorùbá lárugẹ, pe ki ẹ ṣe ohun gbogbo ni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.
Ẹ kú ọdún o, ọdún titun ti o ḿbọ̀ lọ́nà á ya abo fún gbogbo wa.
ENGLISH TRANSLATION
During this yuletide, particularly during the remembrance of Jesus’ birth – Christmas celebration, as there is abundance of food for many people in the developed world and some in Africa so also is scarcity for many others all over the world. Continue reading
Originally posted 2013-12-24 23:01:10. Republished by Blog Post Promoter