A sọ wipe ọmọ kò gbọ́ èdè, tani kó kọ̃? Àwa òbí nii ṣe púpọ ni bi àwọn ọmọ wa ṣe mú èdè
abi-nibi wọn. Àwa òbí lati yi ìhà ti a kọ si èdè Yorùbá padá, ti a kò bá fẹ́ ki o pòórá.
Òwe Yorùbá kan tilẹ sọ wípé, “Onígbá Io npe igbá rẹ ni pankara, ti a fi nbaa fi kolẹ’.
Gẹ́gẹ́ bi òbí, ohun ti a bá fi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wa lati ìgbà èwe ni wọn yio gbọ́njú mọ,
ti wọn yio si dìmú.
Ṣugbọn kini a nfi lélẹ̀? ‘Ẹ̀kọ́ Àjòjì’! Eyi yi ni Èdè Gẹẹsi. Àwa òbí papa, ti a rò
pé a ti lajú ju pé kaa mã fi èdè abínibí wa maa ba àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ nílé lọ. Àti kàwé, a si
ti bọ́ si ipele tó ga ju èyi ti a bi wa si lọ, nitori na, èdè wa di ohun ìtìjú àti àbùkù, ti kò yẹ
ipò ti a wà.
Ẹ jẹ́ ki a kọ́ ọgbọ́n lára àwọn Ìgbò, Hausa, Oyinbo, China àti India,ki a si fi won ṣe àwòkọ́ṣe. Kò si ibi ti àwọn wọnyi wà, yálà nílé tabi lóko, èdè wọn, ni wọn maa ba awọn ọmọ sọ. Àwọn Oyinbo gbé èdè wọn ni arugẹ, ni ó mú ki idaji gbogbo enia ni àgbáyé ki ó maa lo èdè wọn. Àwọn ará ìlú China, ẹ̀wẹ̀, kò fi èdè wọn ṣeré rárá, tó bẹ̃ ti odindi ìlú America, àti àwọn kan ni ilẹ̀ adúláwọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ si kọ awọn ọmọ ilé-ìwé wọn ni Mandarin, ẹ̀yà èdè China. Continue reading
Originally posted 2013-10-08 18:36:55. Republished by Blog Post Promoter