Tag Archives: Inheritance. Wealth

Ẹni tó ni Ẹrú ló ni Ẹrù – Ìtàn Bàbá tó kó gbogbo ogún fun Ẹrú – “One who owns the Slave owns the Slave’s property too” – The Story of a Father who bequeathed all to his Slave

Àwọn Alágbàṣe ni Oko -Labourers in the farm

Àwọn Alágbàṣe ni Oko -Labourers in the farm

Ni ayé igbà kan ri ki ṣe oye ọkọ, ilé gogoro, aṣọ àti owó ni ilé-ìfowó-pamọ́ ni a fi nmọ Ọlọ́rọ̀ bi kò ṣe pé oye Ẹrú, Ìyàwó, Ọmọ, Ẹran ọsin àti oko kòkó rẹpẹtẹ ni a fi n mọ Ọlọ́rọ̀.   Ni àsikò yi, Bàbá kan wa ti ó ni Iyawo púpọ̀, Oko rẹpẹtẹ, ogún-lọ́gọ̀ ohun ọsin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ẹrú tàbi Alágbàṣe, Ọmọ púpọ̀, ṣùgbọ́n ninú gbogbo ọmọ wọnyi, ikan ṣoṣo ni ọkùnrin.  Bàbá fi ikan ninú gbogbo Ẹrú ti ó ti pẹ́ pẹ̀lú rẹ, ṣe Olóri fún àwọn Ẹrú yoku.  Ẹrú yi fẹ́ràn Bàbá, ó si fi tọkàn-tọkàn ṣe iṣẹ́ fún.

Nigbati Bàbá ti dàgbà, ó pe àwọn àgbà ẹbí lati sọ àsọtẹ́lẹ̀ bi wọn ṣe ma a pín ogún ohun lẹhin ti ohun bá kú nitori kò si iwé-ìhágún bi ti ayé òde oni.  Ó ṣe àlàyé pé, ohun fẹ́ràn Olóri Ẹrú gidigidi nitori o fi tọkàn-tọkàn sin ohun, nitori na a, ki wọn kó gbogbo ohun ini ohun fún Ẹrú yi.  Ó ni ohun kan ṣoṣo ni ọmọ ọkùnrin ohun ni ẹ̀tọ́ si lati mu.

Lẹhin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, Bàbá re ibi àgbà nrè, ó ku.  Lẹhin ìsìnkú, àwọn ẹbí àti àwọn ọmọ Olóògbé pé jọ lati pín ogún.  Ni àsikò yi, ọmọ ọkùnrin ni ó n jogún Bàbá, pàtàki àkọ́bí ọkùnrin nitori ohun ni Àrólé.  Gẹgẹ bi àsọtẹ́lẹ̀, wọn pe Olóri Ẹrú jade, wọn si ko gbogbo ohun ini Bàbá ti o di Oloogbe fún.  Wọn tún pe ọmọ ọkùnrin kan ṣoṣo ti Bàbá bi jade pé ó ni ẹ̀tọ́ lati mu ohun kan ti ó bá wu u ninú gbogbo ohun ini Bàbá rẹ, nitori eyi wọn fún ni ọjọ́ meje lati ronú ohun ti ó bá wù ú jù.  Àwọn ẹbí sun ìpàdé si ọjọ́ keje.  Inú Ẹrú dùn púpọ̀ nigbati inú ọmọ Bàbá bàjẹ́. Eyi ya gbogbo àwọn ti ó pé jọ lẹ́nu pàtàki ọmọ Bàbá nitori ó rò pé Bàbá kò fẹ́ràn ohun. Lẹhin ìbànújẹ́ yi, ó gbáradi, ó tọ àwọn àgbà lọ fún ìmọ̀ràn.

Ẹbí pé jọ lati pín Ogún – Family gathered to share inheritance

Ẹbí pé jọ lati pín Ogún – Family gathered to share inheritance

Ni ọjọ́ keje, ẹbí àti ará tún péjọ lati pari ọ̀rọ̀ ogún pin-pin, wọn pe ọmọ Bàbá jade pé ki ó wá mú ohun kan ṣoṣo ti ó fẹ́ ninú ẹrù Baba rẹ.  Ó dide, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ti ó joko, ó yan Olóri Ẹrú  gẹgẹ bi àwọn àgbà ti gba a ni ìyànjú.  Inú Ẹrú bàjẹ́, ṣùgbọ́n o ni ki Ẹrú má bẹ̀rù, Ẹrú na a ṣe ìlérí lati fi tọkàn-tọkàn tọ́jú ohun ti Bàbá fi silẹ̀.  Idi niyi ti Yorùbá ṣe ma npa a lowe pe “Ẹni tó ni Ẹrú ló ni Ẹrù.”

Lára ẹ̀kọ́ itàn yi ni pé, ó dára lati lo ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n nitori “Ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n ni ki i jẹ ki á pe àgbà ni wèrè”. Ẹ̀kọ́ keji ni pé, ogún ti ó ṣe pàtàki jù ni ki á kọ ọmọ ni ẹ̀kọ́ lati ilé àti lati bójú tó ẹ̀kọ́ ilé-iwé.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-10-30 08:30:22. Republished by Blog Post Promoter