Ni ayé àtijọ́, wọn ma ńfi obinrin fún ọkọ ni, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, obinrin á mú̀ àfẹ́sọ́nà lati fi hàn òbi, nitori Yorùbá gba ọmọ obinrin ni àyè lati lọ si ilé-iwé, tàbi kọ́ iṣẹ́-ọwọ́, àti lati ṣe òwò. Èyi jẹ ki obinrin kúrò lọ́dọ̀ obi wọn. Bi obinrin bá ti dàgbà tó bi ọdún meji-din-logun, ti ó tó wọ ilé-ọkọ, àwọn òbi yio ma ran léti pé, ó ti tó mú ọkọ wálé.
Ẹni ti obinrin mọ̀ pé òhun kò lè fẹ́, bi àfojúdi ni lati fi irú ọkùnrin bẹ̃ han òbi. Bi obinrin ti ó ti dàgbà tó lati wọ ilé ọkọ bá mú àfẹ́sọ́nà wá han òbi, wọn yio fi òwe Yorùbá ti ó ni “A ki mọ́ ọkọ ọmọ, ki a tún mọ àlè rẹ” ṣe iwadi pé, ṣe ó da lójú pé òhun yio fẹ ọkùnrin ti ó mú wá? Òwe yi tún wúlò lati fi ṣe ikilọ nigbà igbéyàwó ibilẹ̀ fún obinrin pé kò lè mú ọkùnrin miràn wá lẹhin igbéyàwó.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading
Originally posted 2014-07-08 23:02:45. Republished by Blog Post Promoter