Ni ìlú Ayégbẹgẹ́, ìyàn mú gidigidi, eleyi mu Ọba ìlú bẹ̀rẹ̀ si sá pamọ́ fún àwọn ará ìlú nitori kò mọ ohun ti ohun lè ṣe. Òjò kò rọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, oorun gbóná janjan, nitorina, kò si ohun ọ̀gbìn ti ó lè hù. Ìrònú àti jẹ àti mun bá gbogbo ará ìlú – Ọba, Olóyè, Ọmọdé àti àgbà.
Yorùbá ni “Àgbà kii wà lọ́jà ki orí ọmọ tuntun wọ”, nitori èyí, Ọba sáré pe gbogbo àgbà ìlú àti “Àwòrò-Ifá” lati ṣe iwadi ohun ti ìlú lè ṣe ki òjò lè rọ̀. Àwòrò-Ifá dá Ifá, ó ṣe àlàyé ẹbọ ti Ifá ni ki ìlú rú. Ifá ni “ki ìlú mu Erin lati fi rúbọ ni gbàgede ọjà”.
Gẹ́gẹ́bi Ọba-orin Sunny Ade ti kọ́ “Ìtàkùn ti ó ni ki erin ma wọ odò, t’ohun t’erin lo nlọ”. Ògb́ojú Ọdẹ ló npa Erin ṣùgbọ́n Olórí-Ọdẹ ti Ọba yan iṣẹ́ ẹ mi mú Erin wọ ìlú fún, sọ pé ko ṣẽ ṣe nitori “Ọdẹ aperin ni àwọn, ki ṣe Ọdẹ a mu erin”. Ọba paṣẹ fún Akéde ki ó polongo fún gbogbo ara ilu pe “Ọba yio da ẹnikẹni ti ó bá lè mú Erin wọ ìlú fun ìrúbọ yi lọ́lá”. Ọ̀pọ̀ gbìyànjú, pàtàki nitori ìlérí ti Ọba ṣe fún ẹni ti ó bá lè mu Erin wọ̀lú, wọn sọ ẹmi nu nínú igbó, ọ̀pọ̀ fi ara pa lai ri Erin mú.
Laipẹ, Ìjàpá lọ bà Ọba àti Olóyè pé “ohun yio mú Erin wálé fún ẹbo rírú yi”. Olú-Ọdẹ rẹrin nigbati o ri Ìjàpá, ó wá pa òwe pé “À nsọ̀rọ̀ ẹran ti ó ni ìwo, ìgbín yọjú”. Olú-Ọdẹ fi ojú di Àjàpá, ṣùgbọ́n Ìjàpá kò wo bẹ̀, ó fi ọgbọn ṣe àlàyé fún Ọba. Ọbá gbà lati fún Ìjàpá láyè lati gbìyànjú.
Ìjàpá lọ si inú igbó lati ṣe akiyesi Erin lati mọ ohun ti ó fẹ́ràn ti ohun fi lè mu. Ìjàpá ṣe akiyesi pé Erin fẹ́ràn oúnjẹ dídùn àti ẹ̀tàn. Nigbati Ìjàpá padá, o ṣe “Àkàrà-olóyin” dání, o ju fún Erin ki ó tó bẹ̀rẹ̀ si sọ ohun ti ó báwá pé “àwọn ará ìlú fẹ ki Erin wá jẹ Ọba ìlú wọn nitori Ọba wọn ti wọ Àjà”. Àjàpá pọ́n Erin lé, inú ẹ̀ dùn, ohun naa rò wi pé, pẹ̀lú ọ̀la ohun nínú igbó o yẹ ki ohun le jẹ ọba. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọba àti ará ìlú, wọn ṣe gbogbo ohun ti Ìjàpá ni ki wọ́n ṣe. Ìjàpá àti ará ìlú mu Erin wọ ìlú pẹ̀lú ọpọlọpọ àkàrà-olóyin, ìlù, ijó àti orin yi:
Erin ká relé kó wá jọba)
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀ ) lẹ meji
Ìwò yí ọ̀la rẹ̃,
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀,
Agbada á má ṣe wéré,
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀
Ààrò á máa ṣe wàrà,
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀
Erin ká relé kó wá jọba)
Erin yẹ́yẹ́ ò, erin yẹ̀yẹ̀ ) lẹ mejiYou can also download a recital by right clicking this link: Erin ká relé kó wá jọba
Inú Erin dùn lati tẹ̀ lé ará ìlú, lai mọ̀ pé jàpá ti gba wọn ni ìmọ̀ràn lati gbẹ́ kòtò nlá ti wọ́n da aṣọ bò bi ìtẹ Ọba. Erin ti wọ ìlú tán, ó rí àga Ọba níwájú, Ìjàpá àti ará ìlú yi orin padà ni gẹ́rẹ́ ti ó fẹ́ lọ gun àga Ọba:
A o merin jọba
Ẹ̀wẹ̀kún, ẹwẹlẹ ……You can also download a recital by right clicking this link: A o merin jọba
Originally posted 2015-02-27 09:10:22. Republished by Blog Post Promoter