Tag Archives: i Nigeria Election 2015

“Òṣì ló njẹ tani mọ̀ ẹ́ ri, owó ló njẹ mo bá ẹ tan” – “Poverty is lonesome while success has many siblings”

Ni ayé igbà kan, bi èniyàn bá jẹ́ alágbára, ti ó tẹpá-mọ́ṣẹ́, ti ó si tún ni iwà ọmọlúwàbí, iyi wà fun bi kò ti ẹ ni owó, ju olówó rẹpẹtẹ ti kò si ẹni ti ó mọ idi owó rẹ ni áwùjọ tàbi ti kò hùwà ọmọlúwàbí.  Ni ayé òde òni, ọ̀wọ̀ wà fún olówó lai mọ idi ọrọ̀, eyi ló njẹ ki irú àwọn bẹ́ ẹ̀ dé ipò Òsèlú, Olóri Ìjọ tàbi gba oyè ti kò tọ́ si wọn.

Ìbẹ̀rù òṣì lè jẹ́ ki èniyàn tẹpá-mọ́ṣẹ́, bẹ ló tún lè jẹ́ ki ọ̀pọ̀ fi ipá wá owó.  Ìfẹ́ owó tó gba òde kan láyé òde òni njẹ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ jalè tàbi wá ipò agbára ti ó lè mú ki wọn ni owó ni ọ̀nà ti kò tọ́.  Òṣèlú ki fẹ́ gbé ipò silẹ̀ nitori ìbẹ̀rù pé bi agbára bá ti bọ́, ìṣẹ́ dé.  Àpẹrẹ tani mọ̀ ẹ́ ri pọ̀ lára àwọn Òsèlú ti agbára bọ́ lọ́wọ́ rẹ, Ọ̀gá Òṣìṣẹ́ Ìjọba ti ipò rẹ bọ́, Olóri Ìjọ ti ó kó ọrọ̀ jọ ni orúkọ Ọlọrun ló nri idá mẹwa gbà ju Olóri Ìjọ ti kò ni owó.

Òwe Yorùbá ti ó sọ wi pé “Òṣì ló njẹ tani mọ̀ ẹ́ ri, owó ló njẹ mo bá ẹ tan” fi hàn pé owó dára lati ni, ṣùgbọ́n kò dára lati fi ipá wá ni ọ̀nà ẹ̀bùrú.  Kò yẹ ki èniyàn fi ojú pa ẹni ti kò ni rẹ́ tàbi sá fún ẹbi ti kò ni, nitori igbà layé, igb̀a kan nlọ, igbà kan mbọ̀, ẹni ti ó ni owó loni lè di òtòṣì ni ọ̀la, ẹni ti kò ni loni lè ni a ni ṣẹ́ kù bi ó di ọ̀la.  Nitori eyi, iwà ló yẹ ká bọ̀wọ̀ fún ki i ṣe owó tàbi ipò.

ENGLISH TRANSLATION

In time past, if a person is strong, hard working with good moral character, such person is honoured even though he/she may not be rich rather than a very rich person whose source of Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-05-19 15:23:07. Republished by Blog Post Promoter

“Ìbẹ̀rẹ̀ kọ́ ló niṣẹ́” – Ẹ jade lọ dibò fún Gómìnà àti Aṣòfin Ipinlẹ̀ Orilẹ̀ Edè Nigeria: “The race is not to the swift” – Go out to vote to elect Governors and State Legislators in Nigeria

Ipinlẹ̀ Orilẹ̀ Edè Nigeria - States in Nigeria

Ipinlẹ̀ Orilẹ̀ Edè Nigeria – States in Nigeria

À ṣe kágbá Idibò ni orilẹ̀ èdè Nigeria yio wáyé ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kọkọ̀nlá, oṣù kẹrin ọdún Ẹgbãlémẹ̃dógún, lati yan Gómìnà àti àwọn Aṣòfin Ipinlẹ̀ mẹrindinlọ́gbọ̀n.

A dúpẹ́ pé ilú jade lati dibò yan Olóri Òṣèlú àti àwọn Aṣòfin-àgbà lai mú ijà dáni bi gbogbo ilú ti bẹ̀rù pé yio ri oṣù tó kọjá.  Yorùbá sọ wi pé “Ìbẹ̀rẹ̀ kọ́ ló niṣẹ́” a fi ọ̀rọ̀ yi rọ ará ilú pé ki wọn tu jade lati dibò nitori Ìjọba àpapọ̀ kò súnmọ́ ará ilú bi ti Gómìnà àti Aṣòfin Ipinlẹ̀, ki wọn lè jẹ èrè Ìjọba Alágbádá.

 

ENGLISH TRANSLATION

In Nigeria, the final day of election is coming up on Saturday, eleventh day of April, Two thousand and fifteen, to elect Governors and State Legislators in thirty-six States.

Nigerians are grateful that people trooped out last month to cast their votes to elect the President, Senators and Federal Legislators without serious violence as people feared it would be.   Federal Government is not as close to the grass root like the Governors and the State Legislators hence, one of the Yoruba adage meaning “The race is not for the swift” is being used to encourage people to come out massively to cast their votes so that the people can enjoy the benefits of Democracy.

Share Button

Originally posted 2015-04-10 11:47:34. Republished by Blog Post Promoter