Tag Archives: House hunting

“Ìṣòro ti Agbalésanwó n ri ni Ilú Nlá lati ri Ibùgbé”– “Prospective Tenants’ troubles of finding Accommodation in the Big Cities”

Abúlé – A Village.  Courtesy: @theyorubablog

Abúlé – A Village. Courtesy: @theyorubablog

Ni ayé àtijọ́, kò si ohun ti ó njẹ́ Agbalésanwó nitori kò si ẹni ti kò ni ẹbi ti wọn lè bá gbé ni ọ̀fẹ́.  Kò wọ́pọ̀ ki èniyàn kúrò ni ilé lati lọ gbé ilú miran.  Iṣẹ́ meji ti ó wọ́pò ni ayé àtijọ́ ni iṣẹ́ àgbẹ̀ àti òwò nipa ti ta irè oko ni ọjọ́ Ọjà Oko lati Abúlé kan si ekeji.  Kò si ohun irinna bi ayé òde òni, nitorina ẹsẹ̀ ni wọn fi nlọ lati ilú kan si ekeji.  Yorùbá fẹ́ràn àlejò, nitori eyi, bi Oniṣòwò bá lọ si Ọjà Oko ni ilú miran, ti kò lè délé ni ọjọ́ ti ó gbéra, yio ri ilé sùn ni abúlé ti ó bá dé ti ilẹ̀ fi ṣú lai sanwó.  Olóko ni o ma npèsè ibùgbé fún Alágbàṣe ti wọn bá gbà fún iṣẹ́ oko, nitori eyi, kò si pé àlejò gba ilé lati sanwó.

Ìsọ̀ Ọjà oko – Village Market Stall

Ìsọ̀ Ọjà oko – Village Market Stall. Courtesy: @theyorubablog

Ni igbà ti ó yá, èrò bẹ̀rẹ̀ si kúrò lati ilú kan si ekeji, pàtàki nitori ọ̀gbẹlẹ̀, iyàn, ogun tàbi ẹni ti wọn lé kúrò ni ilú nitori iwà burúkú.  Eleyi fã ki ilú kan fẹ̀ ju òmíràn lọ, pàtàki ni ilú ti ó bá sún mọ́ odò nla bi ti ilù Èkó nitori iṣẹ́ ma npọ̀.

Ni ayé òde òni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ má a nkúrò ni ilé lati wá iṣẹ́ lọ si ilú miran.  Ó rọrùn fún ẹni ti ó kàwé àti oníṣẹ́ ọwọ́ lati ri iṣẹ́ nitori oriṣiriṣi iṣẹ́ pọ ni ilú nlá, ju ilú kékeré lọ.  Eleyi jẹ́ ki ilú nlá bẹ̀rẹ̀ si fẹ si. Gẹ́gẹ́ bi òwe Yorùbá “Ọ̀kọ́lé kò lè mu ràjò”, bẹni kò si bi ẹni ti ó kúrò ni ilé ti lè gbé ilé dáni lọ si ilú nlá. Àlejò bẹ̀rẹ̀ si pọ̀ si ni ilú nlá ṣùgbọ́n ilé gbigbé kò kári.

Àṣà ti ó wọ́pọ̀ ni ki Onilé gba owó ọdún kan tàbi meji.  Elòmìràn ngba ọdún mẹta fún owó à san silẹ̀.  Ilé wá di ohun à mu ṣowó.  Oriṣiriṣi àwọn oniṣẹ́ “Abániwálé” wá pọ̀ si.  ọ̀pọ̀ Onilé àti Abániwále bẹ̀rẹ̀ si lu jìbìtì nipa gbi gba owó lọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ Agbalésanwó lóri ilé kan ṣoṣo, òmíràn ngba owó lóri ilé ti ki ṣe ti wọn. Yorùbá ni “Alágbàtà tó nsọ ọjà di ọ̀wọn”, bi ilé bá ti wọn tó ni owó ti Abániwále má a ri gbà ti pọ̀ tó.  Eyi jẹ́ ki wọn sọ ilé di ọ̀wọ́n, nitori owó ti wọn má a ri gbà lọ́wọ́ Onilé àti Agbalésanwó lai ro inira Agbalésanwó.

ENGLISH TRANSLATION Continue reading

Share Button

Originally posted 2015-09-04 07:30:37. Republished by Blog Post Promoter