Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni “Bi ọmọdé bá tó ni ọkọ́, à fún lọ́kọ́”. Ọkọ́ jẹ irinṣẹ́ pàtàki fún Àgbẹ̀. Iṣẹ́-àgbẹ̀ ni ó wọ́pọ̀ ni ayé àtijọ́. Nitori eyi, bi bàbá ti nkọ́ ọmọ rẹ ọkùnrin ni iṣẹ-àgbẹ̀, ni ìyá nkọ́ ọmọ obinrin rẹ ni ìtọ́jú-ile lati kọ fún ilé-ọkọ. Iṣẹ́ la fi nmọ ọmọ ọkùnrin, nitori eyi, bi ọkùnrin bá dàgbà, bàbá rẹ á fun ni ọkọ́ nitori ki ó lè dá dúró lati lè ṣe iṣẹ́ ti yio fi bọ́ ẹbi rẹ ni ọjọ́ iwájú.
Bi ọkùnrin bá ni iṣẹ́, ó ku kó gbéyàwó ti yio jẹ “Olorì” ni ilé rẹ. Ìyàwó fi fẹ́ bu iyi kún ọkùnrin, nitori, ó fi hàn pé ó ni igbẹ́kẹ̀lé. Àṣà Yorùbá gbà fún ọkùnrin lati fẹ́ iye ìyàwó ti agbára rẹ bá gbé lati tọ́jú. Nitori eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọba, Baálẹ̀, Ìjòyè àti àwọn enia pàtàki láwùjọ ma nfẹ ìyàwó púpọ̀. Ìṣòro ni ki wọn fi ọkùnrin ti kò ni ìyàwó jẹ Ọba. Kò wọ́pọ̀ ki Ọba ni ìyàwó kan ṣoṣo.
Ohun ti a ṣe akiyesi ni ayé òde òni, ni Ọba ti ó fẹ ìyàwó kan ṣoṣo nitori ẹ̀sìn, pàtàki ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n ti ó ni àlè rẹpẹtẹ. Ọba ayé òde òni ndá nikan lọ si òde lai mú Olorì dáni. Gẹgẹbi ọ̀rọ̀ Yorùbá, “Àpọ́nlé kò si fún Ọba ti kò ni Olorì”, nitori eyi, kò bu iyi kún Ọba, ki ó lọ àwùjó tàbi rin irin àjò pàtàki lai mú Olorì dáni. Ohun ti ó yẹ Ọba ni ki a ri Ọba àti Olorì rẹ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ.
ENGLISH TRANSLATION
Originally posted 2014-11-11 19:13:42. Republished by Blog Post Promoter