Ni ayé àtijọ́, kò si itẹdi à lò sọnù bi ti ayé òde òni. Bẹni wọn kò lo ìgò oúnjẹ lati fún ọmọ tuntun ni oúnjẹ.
Ọwọ́ ọlọ́mọ tuntun ki kúrò ni omi nitori omi ni wọn fi nto àgbo ti wọn nrọ ọmọ fún ìtọ́jú ọmọ tuntun. Aṣọ àlòkù Bàbá, Ìyá àti ẹbi ni wọn nya si wẹ́wẹ́ lati ṣe itẹdi ọmọ nitori kò si itẹdi à lò sọnú bi ti ayé òde òni.
Ọmọ tuntun a ma ya ìgbẹ́ àti ìtọ̀ tó igbà mẹwa tàbi jù bẹ́ ẹ̀ lọ ni ojúmọ́. Ọmọ ki i sùn ni ọ̀tọ̀, ẹ̀gbẹ́ ìyá ọmọ ni wọn ntẹ́ ọmọ si. Lẹhin ọsẹ̀ mẹ́fà tàbi ogoji ọjọ́ tàbi ó lé kan ti wọn ti bi ọmọ, ìyá àti ọmọ lè lọ òde, ìyá á pọn ọmọ lati jáde.
Nitori aṣọ ni itẹdi kò gba omi dúró, bi ọmọ bá tọ̀ tàbi ya ìgbẹ́, á yi aṣọ ìyá tàbi ẹni ti ó gbé ọmọ. Kò si ẹ̀rọ ifọṣọ igbàlódé nitori na a, ó di dandan ki wọ́n fọ aṣọ ọmọ àti ẹni ti ó gbé ọmọ ni igbà gbogbo ni ilé ọlọ́mọ tuntun. Eyi ni ó jẹ́ ki Yorùbá ma ki ẹni ti ó bá ntọ ọmọ lọ́wọ́ pé “Ẹ kú ọwọ lómi” nitori ọwọ́ ki kúrò ni omi aṣọ fí fọ̀.
ENGLISH TRANSLATION
In the old days, there were no disposable diaper as common as it has become in recent times. Also, babies were not bottle fed. Continue reading
Originally posted 2016-03-04 23:03:05. Republished by Blog Post Promoter