A bi Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú ni ọjọ́ karundinlọ́gbọ̀n, oṣù kọkanla, ọdún Ẹ̀dẹ́ẹ́gbãlemẹ̃dógún, ó ṣe igbéyàwó pẹ̀lú Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ àgbà Òṣèlú ni ọjọ́ kẹrindinlọ́gbọ̀n, oṣù kejila, Ẹ̀dẹ́ẹ́gbãlemẹ̃tadinlọ́gbọ̀n, o jade láyé nigbati ó kú bi oṣú meji ó lé di ẹ ki ó pé ọgọrun ọdún.
“Lẹhin ọkùnrin tàbi obinrin (ni ayé òde òni) ti ó bá ṣe ori-ire, obinrin tàbi ọkunrin rere wa lẹhin tabi ẹ̀gbẹ rẹ”. Òwe yi ni a lè fi ṣe àpẹrẹ iṣẹ́ ribiribi ti Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú ṣe fún Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, ògúná gbongbo Òṣèlú ni ilẹ̀ Yorùbá àti fún orilẹ̀ èdè Nigeria. Nigbati Bàbá mba iṣẹ́ oselu kiri gbogbo àgbáyé, Iyá ló di ilé mú, ti ọkàn Olóògbé Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ fi balẹ̀ lati le fi ipò Olóri Òsèlú ṣe iṣẹ́ ribiribi ti ó ṣe. Titi di ọjọ́ ikú ọkọ rẹ ni ọdún mejidinlọ́gbọ̀n sẹhin, lẹhin igbéyàwó àádọ́ta ọdún, ó ṣe àti lẹhin fún ọkọ rẹ titi di ọjọ́ alẹ́, eyi jẹ àpẹrẹ rere fún gbogbo obinrin.
Ẹbi àti ará ti bẹ̀rẹ̀ si palẹ̀mọ́ fún ọjọ́ ibi ọgọrun fún Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú nigbati iròyin ikú rẹ jade pé iyá sùn ni ọjọ kọkàndinlógún, oṣú kẹsan ọdún Ẹgbàálemẹ̃dógún. Ipalẹ̀mọ́ ìsìnku bẹ̀rẹ lati ṣe àṣeyẹ ikẹhin fún olóògbé dipò ayẹyẹ ọjọ́ ọgọrun ibi.
Olóri Òṣèlú Nigeria Muhammadu Buhari pẹ̀lú àwọn àgbà Òsèlú, àwọn Ọba àti Ìjòyè, ọmọdé àti àgbà ilú dara pọ̀ pẹ̀lú ẹbi àti àwọn ọmọ Olóògbé lati ṣe ẹ̀yẹ ikẹhin fún Olóògbé, Olóyè Hannah Ìdòwú Dideolú Awólọ́wọ̀ ni ọjọ́ karùndinlọ́gbọ̀n, oṣù kọkanla ọdún Ẹgbàálemẹ̃dógún.
Sùn re o, ó digbà, o di gbóṣe.
ENGLISH TRANSLATION Continue reading