Ibò ni gbogbo orilẹ̀ èdè Nigeria lati yan Olóri Òṣèlú àti Gómìnà fún agbègbè yio wáyé ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrinla, oṣù keji odun Ẹgbãlemẹ̃dogun.
Ki i ṣe ẹgbẹ́ Òṣèlú meji ló wà ṣùgbọ́n ninú ẹgbẹ́ bi mejidinlọgbọn, ẹgbẹ́ Alágboòrùn àti Onigbalẹ ló mókè jù ninú ẹgbẹ́ yoku. Laarin ẹgbẹ́ meji yi, ibò lati yan Gómìnà fún àwọn ìpínlẹ̀ Yorùbá wọnyi yio wáyé ni: Èkó laarin Akinwunmi Ambọde àti Jimi Agbájé, Ògùn Gómìnà Ibikunle Amósùn àti Ọmọba Gbóyèga Nasir Isiaka, Ọ̀yọ́ laarin Gómìnà Aṣòfin-àgbà Abiọ́lá Ajimọbi àti Aṣòfin-àgbà Teslim Kọlawọle Isiaka. Kò si ibò ni ìpínlẹ̀ Ọ̀sun nitori Gómìnà Rauf Arẹ́gbẹ́sọlá gba ipò padà ni ọjọ́ kẹsan oṣù kẹjọ ọdún Ẹgbãlemẹrinla, nigbati Ekiti gba ipò lọ́wọ́ Gómìnà Olóye Káyọ̀dé Fayẹmi fún Gómìnà Ayọdele Fayoṣe ni oṣù kẹfa, ọjọ́ kọkànlélogún ọdún Ẹgbãlemẹrinla. Àsikò Gómìnà Olóye Olúṣẹ́gun Mimiko ti Ondo kò ni pari titi di ọdún Ẹgbãlemẹrindilogun. Continue reading
Originally posted 2015-01-27 22:11:09. Republished by Blog Post Promoter