Ni àṣà Yorùbá, ni ayé àtijọ́, ọjọ́ keje ni wọn ńsọmọ obinrin ni orúkọ, ọjọ́ kẹsan ni ti ọmọ ọkùnrin, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ọjọ kẹjọ ni wọn sọ gbogbo ọmọ lórú̀kọ. Yorùbá ki sọmọ lórúkọ ni ọjọ́ ti wọn bi,ṣùgbọ́n Yorùbá ti ó bá bimọ si òkè-òkun lè fún ilé-igbẹbi lórúkọ ọmọ gẹgẹ bi àṣà òkè-òkun ki wọn tó sọmọ lórúkọ.
Òwe Yorùbá ni “Ilé làńwò, ki a tó sọmọ lórúkọ” nitori eyi, Bàbá àti Ìyá yio ronú orúkọ ti ó dara ti wọn yio sọ ọmọ ni ọjọ́ ikómọ. Orúkọ Yorùbá lé ni ẹgbẹ-gbẹrun, àwọn orúkọ yi yio jade ni ipasẹ̀ akiyesi iṣẹ̀lẹ̀ ti o ṣẹlẹ̀ ni àsikò ti ọmọ wa ni ninú oyún; ọjọ́ ibi ọmọ; orúkọ ti ó bá idilé tabi ẹsin àtijọ́ àti ẹsin igbàlódé mu.
A o ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ igbalode àti àwọn orúkọ ibilẹ ti ó ti fẹ ma parẹ. A o bẹrẹ pẹlu orukọ ti o wọpọ ni idile “Ọlá”, “Ọba”, “Olóyè” àti “Akinkanjú ni àwùjọ ni ayé òde òni. “Ọlá” ninú orúkọ Yorùbá ki ṣe owó àti ohun ini nikan, Yorùbá ka “ilera” si “Ọlà”. Continue reading
Originally posted 2014-07-01 20:03:09. Republished by Blog Post Promoter